Ukwa

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ukwa jẹ́ oúnjẹ orílè-èdè Nàìjíríà, àwọn Igbo ni ó ma ń jẹ ẹ́, ni ìhà Gúsù Ìlà Òòrùn Nàìjíríà. A lè jẹ ẹ́ bẹ̀ tàbí kí a sè é bíi àsaró.[1]

Ìsọníṣókí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ukwa, tí a mọ̀ sí breadfruit, a sábà ma ń sè é pẹ̀lú potash, ewùro, ẹja gbígbẹ, ata, àti èròjà aládùn. Ẹ lè sè é kí ẹ tún fi White Puna yam àti àgbàdo kun kí ó lè dùn. Orúkọ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì rẹ̀ ni Treculia africana, tí ó sì jẹ́ ti ohun tí à ń pè ni Moraceae. Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ láti se ukwa ni kí a fọ̀ ọ́ dáadáa. Sè é títí irúgbìn rẹ̀ yóò fi rọ̀, sì fi epo, ewùro, potash, ẹja yíyan tàbí ẹja tútù àti ata si.[2]

Jẹ́ kí ó hó fún ìṣẹ́jú márùn-ún, lẹ́yìn rẹ̀ pín breadfruit porridge pẹ̀lú ohun mímu bíi ohun mímu aládùn. A lè jẹ Ukwa tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ sè pẹ̀lú ẹmu tàbí àgbon.[3]

Oúnjẹ tó dà bí rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ukwa fẹ́ rí gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀wà nípasẹ̀ sísè àti oúnjẹ aládùn tó jẹ́, àwọn oúnjẹ 'breadfruit' yòókù ni mulberries, figs, breadnut, àti jackfruit.[3]

Tún wo[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Trecullia africana
  • Staple food
  • Niuean cuisine

Àwọn Ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "How To Make Homemade Ukwa Dish". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-09-28. Retrieved 2022-06-20. 
  2. omotolani (2021-06-04). "Ukwa: How to make African breadfruit porridge". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-06-20. 
  3. 3.0 3.1 "How To Make Homemade Ukwa Dish". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-09-28. Retrieved 2022-06-20.