Jump to content

Umaru bin Ali

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Umaru bin Ali (1824–1891) jẹ Sultan Sokoto láti 1881 sí 1891. O rọpò Sultan Mu'azu lẹyin iku rẹ ní Oṣù Kẹsán 1881. Ali jẹ ọmọ ọmọ tí Uthman dan Fodio, ọmọ ọmọ Muhammed Bello àti ọmọ Aliyu Babba .

Ali jẹ ọmọ-ọmọ Usman dan Fodio . [1] Ṣáájú kí o tó di Sultan, Ali jẹ oyè Sarkin Sudan o si gbe ni ribat ni ilu Shinaka. Nígbà ìjọba rẹ̀, ó rìn àwọn ìrìn àjò méta. Ìrìn-àjò akọkọ ní atẹle ìpolongo Mu'azu lódì si Sabon Birni nígbà tí èkejì lódì sí Madarunfa . [2] Ìrìn àjò kẹta lódì si Argungu, lẹ́hin ìgbèrò àlàfíà tí Argungu kọ̀; olórí ẹgbẹ́ arìnrìn-àjò náà ni Sarkin Lifidi Lefau. Bí ó tí wù ó ri, àwọn Kebbawa wá ní ìmurasíè, wọn sì kojú ogún náà ni gbángba, àwọn ọmọ-ogun Sokoto sì ṣẹ́gun. wọn pa Lefau. [3]

  1. Mark R. Lipschutz; R. Kent Rasmussen (1989). "UMARU ('Umar Ibn 'Ali), c.1824-91". Dictionary of African Historical Biography. University of California Press. p. 241. ISBN 978-0-520-06611-3. 
  2. Last, Murray. (1967). The Sokoto Caliphate. New York: Humanities Press. p. 124
  3. Johnston (1967). The Fulani Empire of Sokoto. Oxford University Press.