Jump to content

Uwani Musa Abba Aji

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Uwani Musa Abba Aji (tí a bí ní ọjọ́ keje oṣù kọkànlá ọdun 1956) jẹ́ Adájọ ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Adájọ́ ilé-ẹjọ́ àgbà orílẹ̀-èdè ti orílẹ̀-èdè Nàíjíríà.[1][2][3]

Àárò ayé àti Èkó rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Aji ní ọjọ́ keje oṣù kọkànlá ọdun 1956, ní ìlú Gashua, ìpínlè Yobe. Ó tètè bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé-ìwé Central Primary School Gashua ní ọdun 1961, tí ó sì tẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀ síwájú ní Government Girls Secondary School, Maiduguri níbi tí ó ti gba ìwe-ẹ̀rí WAEC rẹ̀ ni ọdun 1972.[2] Ní ọdun 1976, ó gba àmì-ẹyẹ "Diploma in Law" ní Yunifásítì Àmọ́dù Béllò ti Zaria ní ọdun 1980, àti àmì-ẹyẹ L.L.B Hons ní ilé-ìwé kan náà. Aji bẹ̀rẹ̀ isẹ́ òfin ní ọdun 1981.[2]

Uwani fẹ́ Musa Abba-Aji, àwọn méjèèjì sì bí ọmọ mẹ́ta, Musa jẹ́ ọ̀gá àgbà Borno State Civil Service tẹ́lẹ̀ rí.[4] Uwani ní àwọn nnkan tí òun féràn láti ma se ni kí kàwé, kí kọ̀wé, kí òun máa rin ìrìn-àjò àti kí ó máa tọjú ọgbà.[2]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Ifeoma, Peters (23 January 2019). "Justice Uwani Musa Abba Aji: From Gashua to the Supreme Court". DNL Legal and Style. Archived from the original on 17 April 2020. https://web.archive.org/web/20200417111612/https://dnllegalandstyle.com/2019/justice-uwani-musa-abba-aji-from-gashua-to-the-supreme-court/. Retrieved 27 April 2020. 
  2. 2.0 2.1 2.2 2.3 "Supreme Court of Nigeria". supremecourt.gov.ng. Retrieved 27 April 2020. 
  3. "Justice Abba Aji Sworn In As Supreme Court Judge". Sahara Reporters. 9 January 2019. http://saharareporters.com/2019/01/09/justice-abba-aji-sworn-supreme-court-judge. Retrieved 27 April 2020. 
  4. "Presidential Tribunal Verdict: Over-Confident Yar'adua travels to China on Tuesday, Former Senator Abba-Aji to the Rescue". Sahara Reporters. 23 February 2008. http://saharareporters.com/2008/02/23/presidential-tribunal-verdict-over-confident-yaradua-travels-china-tuesday-former-senator. Retrieved 27 April 2020.