Jump to content

Vladislav Lekomtsev

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Vladislav Alekseyevich Lekomtsev (tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kejìlá ọdún 1994) jẹ́ eléré-ìdárayá ti ilẹ̀ Russia.[1] Lásìkò Paralympics ti ọdún 2014, ó gba àmì-ẹ̀yẹ fún sísá eré 7.5 km, tí ó sì tún gba àmì-ẹ̀yẹ onídẹ fún 20 naa km fún ìkópa rẹ̀ nínú eré-ìdárayá ti ọdún náà. [2]

Ìgbésí ayé[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Vladislav Lekomtsev ní ọjọ́ kẹjọ oṣụ̀ kejìlá ọdún 1994 ní ìlú Romashkino, ní agbègbè Alnashsky, Udmurtia sí Tamara Yakovlevna Lekomtseva àti Aleksey Lekomtsev. Láti ìgbà tí òun àti àwọn àbúrò rẹ̀ mẹ́ta ti wà ní ilé-ìwé alákọọ́bẹ̀rẹ̀ ni ó ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ ní okò láti rí aṣọ àti àwọn ohun tí wọ́n máa lò ní ilé-ìwé. Ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹjọ ọdún 2007, apá rẹ̀ gé nígbà tí ó ṣe ijàm̀bá ọkọ agégi kan lóko níbi tí ó ti ń ran bàbá rẹ̀ lọ́wọ́. [3]

Ní ọdún 2009, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní kópa nínú erẹ́ bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá títí tí ìyá rẹ̀ fi bá a yan eré-ìdárayá skiing fun láti darapọ̀ mọ́. [4]

Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní Udmurt State University ní Izhevsk, níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀-ọkàn.[5]

Ó gba àmì-ẹ̀yẹ oníwúrà nínú ìdíje 2021 World Para Snow Sports Championship, tó wáyé ní Lillehammer, Norway. [6] [7] Ó tún gba àmì-ẹ̀yẹ oníwúrà nínú ìdíje àwọn ọkùnrin.[8] [9] Nínú ìdíje ẹ̀ẹ̀mejì lọ́dún, ọ́ gba àmì-ẹ̀yẹ oníwúrà bákan náà.[10] [11] Bákan náà ni ó gba àmì-ẹ̀yẹ oníwúrà nínú ìdíje àwọn ọkùnrin fún ìkópa nínú erẹ́-sísá ti 10km. [12] [13]

Ìgbésí ayé ara ẹni[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Orúkọ obìnrin tí ó fẹ́ fún ọ̀pọlọpọ̀ ọdún ni Varvara Reshetnikova.[14] Láti ilé-ìwẹ́ ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ọ̀rẹ́ wọn, kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí ní fẹ́ ara wọ́n ní oṣù kẹta ọdún 2013.[15] Ní ọjọ́ kejìlélógún oṣụ̀ kejì ọdún 2015, wọ́n bí ọmọkùnrin tó jẹ́ àkọ́bí wọn, tí ẃn sì sọ ní Timofey. [16]

Àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Order "For Merit to the Fatherland", 4th class (ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹta ọdún 2014) – fún ìlọ́wọ́sí rẹ̀ sí ìdàgbàsókè ọ̀rọ̀ àṣà àti eré-ìdárayá, àti fún ìtayọ rẹ̀ nínú eré-ìdárayá ti ọdún 2014 Paralympic Winter Games ní Sochi[17]
  • Merited Master of Sports of Russia (ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹta ọdún 2014)[18]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Russia breaks medal record at Sochi Paralympics with cross-country golds". The Moscow News. December 3, 2014. Archived from the original on December 20, 2014. https://web.archive.org/web/20141220042053/http://themoscownews.com/sports/20140312/192604201/Russia-breaks-medal-record-at-Sochi-Paralympics-with.html. 
  2. . 
  3. Stovbun, Svetlana (20 April 2015). "Две стороны несчастья: о чём мечтает чемпион Владислав Лекомцев?" (in ru). Argumenty i Fakty (16). http://www.udm.aif.ru/society/people/1493911. 
  4. Impolitova, Nadezhda (8 December 2014). "Паралимпиец из Удмуртии Владислав Лекомцев отмечает юбилей в Финляндии" (in ru). Komsomolskaya Pravda. http://www.izh.kp.ru/daily/26317.5/3196119/. 
  5. Semenova, Anna (9 April 2016). "Паралимпиец Владислав Лекомцев из Удмуртии: папа сделал мне отдельную комнату для медалей, но в ней уже тесновато" (in Èdè Rọ́ṣíà). Izhlife.ru. Retrieved 26 February 2017. 
  6. "Royals crown six new champions as hosts strike cross-country gold on first day". Paralympic.org. 13 January 2022. https://www.paralympic.org/news/royals-crown-six-new-champions-hosts-strike-cross-country-gold-first-day. 
  7. "Golubkov and Gretsch among first winners at World Para Snow Sports Championships". InsideTheGames.biz. 13 January 2022. https://www.insidethegames.biz/articles/1117750/world-para-snow-sports-champs-1. 
  8. "Masters wins first gold of World Para Snow Sports Championships". InsideTheGames.biz. 18 January 2022. https://www.insidethegames.biz/articles/1117950/world-para-snow-sports-champs-6. 
  9. "USA's Oksana Masters claims 10th world title days after recovering from COVID". Paralympic.org. 18 January 2022. https://www.paralympic.org/news/usa-s-oksana-masters-claims-10th-world-title-days-after-recovering-covid. 
  10. "Russians take biathlon golds at World Para Snow Sports Championships". InsideTheGames.biz. 15 January 2022. https://www.insidethegames.biz/articles/1117842/world-para-snow-sports-champs-3. 
  11. "Clean podium sweeps for RPC and Ukraine on Para biathlon's opening day". Paralympic.org. 15 January 2022. https://www.paralympic.org/news/clean-podium-sweeps-rpc-and-ukraine-para-biathlon-s-opening-day. 
  12. "Belarus' Yury Holub reigns supreme for second gold medal despite icy slip". Paralympic.org. 16 January 2022. https://www.paralympic.org/news/belarus-yury-holub-reigns-supreme-second-gold-medal-despite-icy-slip. 
  13. "Russian trio win again in biathlon at the World Para Snow Sports Championships". InsideTheGames.biz. 16 January 2022. https://www.insidethegames.biz/articles/1117882/world-para-snow-sports-champs-4. 
  14. Igosheva, Diana (5 May 2015). "У паралимпийца из Удмуртии Владислава Лекомцева родился сын" (in Èdè Rọ́ṣíà). Izhlife.ru. Retrieved 26 February 2017. 
  15. Semenova, Anna (9 April 2016). "Паралимпиец Владислав Лекомцев из Удмуртии: папа сделал мне отдельную комнату для медалей, но в ней уже тесновато" (in Èdè Rọ́ṣíà). Izhlife.ru. Retrieved 26 February 2017. 
  16. Empty citation (help) 
  17. "Указ Президента Российской Федерации от 17 марта 2014 года № 144 «О награждении государственными наградами Российской Федерации»" (in Èdè Rọ́ṣíà). kremlin.ru. Retrieved 26 February 2017. 
  18. "Приказ Министерства спорта Российской Федерации от 11 марта 2014 г. № 21-нг «О присвоении почётного спортивного звания "Заслуженный мастер спорта России"»" (in Èdè Rọ́ṣíà). Ministry of Sports of the Russian Federation. 11 March 2014. Retrieved 26 February 2017.