Wunmi Toriola
Ìrísí
(Àtúnjúwe láti Wùnmí Toríọlá)
Wunmi Toriola tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kọkànlá oṣù keje ọdún 1988 jẹ́ òṣèrébìnrin àti Oǹkọ̀tàn sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ògùn lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[1] [2]
Ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ àti sinimá-àgbéléwò rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wùnmí Toríọlá kàwé gboyè nínú ìmọ̀ Ìpèdè (Linguistic) ní Ifáfitì ìjọba Àpapọ̀ tí ó wà ní ìlú Ìlọrin (University of Ìlorin). Bákan náà ó kàwé gboyè Dípólómà ní Ọdúnfá Caucus, ilé ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tíátà tí àgbájọpọ̀ àwọn gbajúmọ̀ òṣèré sinimá àgbéléwò Yínká Quadri, Taiwo Hassan (Ogogo), Sunny Àlí, Abbey Láńre àti Razaq Àjàó dá sílẹ̀. Ọdún 2009 ni Toríọlá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ sinimá àgbéléwò, lọ́dún 2013 ló gbé sinimá àgbéléwò tirẹ̀ gangan jáde ti o pe àkọ́lé rẹ̀ ní "Ẹ̀tọ́". Lẹ́yìn náà, ó ti kọ sinimá àgbéléwò bí i mẹ́tàlá fúnrarẹ̀, ó sì ti kópa nínú sinimá àgbéléwò tí ó ti ju ọgọ́rùn-ún lọ. [3] [4]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Wunmi Toriola Profile, Career & Biography". NigerianWiki. 2019-08-22. Archived from the original on 2020-09-22. Retrieved 2020-01-10.
- ↑ "Actress Wunmi Toriola Biography: Age & Pictures". 360dopes. 2018-05-15. Retrieved 2020-01-10.
- ↑ "How I met my husband through Facebook - Actress Wunmi Toriola reveals, talks about her relationship with Toyin Abraham". Within Nigeria. 2018-08-20. Retrieved 2020-01-10.
- ↑ Ologbonyo, Kemisola (2018-06-25). "6 Facts You Probably Didn’t Know About Beautiful Nollywood Actress, Wumi Toriola". blueink.ng. Retrieved 2020-01-10.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]