West African Examinations Council

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
West African Examinations Council
AbbreviationWAEC
Official languagesEnglish
Websitewaecdirect.org
waecnigeria.org
WAEC Headquarter, Abuja
WAEC office, Ogba, Lagos
WAEC office, Ogba, Lagos

Àjọ West African Examinations Council (WAEC) jẹ́ ìgbìmọ̀ àjọ aṣèdánwò tí a dá sílẹ̀ lábẹ́ òfin lápá iwọ̀-oòrùn Áfíríkà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń lo èdè Gẹ̀ẹ́sì gẹ́gẹ́ bí èdè ìkọ́ni, pẹ̀lú ìwé-ẹ̀rí tó lè fagagbága pẹ̀lú àwọn ìwé-ẹ̀rí àwọn orílẹ̀-èdè ńláńlá lágbàáyé.[1] Wọ́n dá ìgbìmọ̀ aṣèdánwò yìí sílẹ̀ lọ́dún 1952, láti àkókò náà, ipa tí ìgbìmọ̀ àjọ yìí tí kó nínú ètò ẹ̀kọ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè Áfíríkà afòyìnbó-sọ̀rọ̀ bíi,Ghana, Nigeria, Sierra Leone, Liberia, àti the Gambia, kò kéré rárá, pàápàá jù lọ, àwọn ètò ìdánwò àti ìwé-ẹ̀rí tí wọ́n ti fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn aṣẹ̀dánwò. Bẹ́ẹ̀ náà wọ́n ṣètò ìkówójọ láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó bá ku díẹ̀ káàtó fún ní Áfíríkà.

Ọ̀gá àgbà kan ni àjọ yìí, Ọ̀mọ̀wé Adeyegbe, ṣàlàyé nígbà kan pé "àjọ náà tí ṣe ìgbéǹde àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ elétò ẹ̀kọ́, tí wọ́n ní ìtara láti ṣètò ìdánwò tó gbámúṣé, tí ó sìn wúlò fún ìdàgbàsókè àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà nínú ìgbìmọ̀ àjọ yìí".[2] Láàárín ọdún kan, ó máa ń tó mílíọ̀nù mẹ́ta àwọn ènìyàn tí wọ́n máa ń forúkọ sílẹ̀ láti ṣe ìdánwò yìí.[3] Bákan náà, àjọ yìí máa ń ṣe ìrànlọ̀wọ̀ fún àwọn àjọ ìdánwò mìíràn, yálà lórílẹ̀ wa Nigeria tàbí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "FAQ". www.waecnigeria.org. Archived from the original on 2013-07-25.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. Dr. Adeyegbe, S. (2004). Retrieved April 12, 2006, from http://www.waecnigeria.org/home.htm Archived 2006-04-08 at the Wayback Machine.
  3. Achievemhow can i check my west african examination council bwith my phone number ent of WAEC. (2004). Retrieved April 12, 2006, from http://www.ghanawaec.org/about3.htm Archived 2006-09-04 at the Wayback Machine.