Jump to content

White House

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
White House
South façade of the White House
Building
Town1600 Pennsylvania Avenue NW
Washington, D.C. 20500
CountryUnited States
Construction
StartedOctober 13, 1792
Design team
ArchitectJames Hoban

White House jẹ́ orúkọ tí wọ́n ń pè Olú-ilé-iṣẹ́ ìṣèjọba orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà tí Ààrẹ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ti ń ṣèjọba. Ó fìkàlẹ̀ sí Washington DC. [1] [2] [3]

Ọmọ ìlú Ireland, James Hoban ni ó ya àwòrán bí wọn yóò ṣe kọ́ ilé náà . [4] Hoban ṣe àpẹrẹ ilé náà lórí ilé LeinsterDublin, níbi tiOireachtas tó jẹ́ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Ireland. Ìkólé wáyé láàárin ọdún 1792 àti 1800, pẹ̀lú ìta Aquia Creek sandstone tí wọ́n kùn ní ọ̀dà funfun. Nígbà tí Thomas Jefferson kó sínú ilé yìí ní ọdún 1801, òun àti Benjamin Henry Latrobe fi colonnades kún àwọn apá ibi kọ̀ọ̀kan láti gbé ilé ẹṣin tó wà níbẹ̀ pamọ́. [5] Ní ọdún 1814, lákòkóò Ogun ti 1812, àwọn ọmọ ogun Ilu Gẹẹsi dáná sun ilé ńlá ni Washington, gbogbo inú ilé náà ló jóná nigbà tí ìta ilé jó díẹ̀. Láì pẹ́ ẹ̀ ni àtúnkọ́ bẹ̀rẹ̀ tí Alákoóso James Monroe sì kó lọ sí àkọ́kù ilé Ibugbe Alase ní Oṣù Kẹwàá Ọdún 1817. Iṣẹ́ tẹ̀síwájú pẹ̀lú àfikún ní ìta ilé náà tí a pè ní South Portico ní ọdún 1824 àti North Portico ní ọdún 1829.

Nítorí àpéjọpọ̀ láàárin ilé ńlá aláṣe fúnrararẹ̀, Alákoóso Theodore Roosevelt ni kí gbogbo àwọn ọ́fììsì padà sí West Wing tuntun tí a ṣe ní ọdún 1901. Ọdún mẹ́jọ lẹ́hìn náà, ní ọdún 1909, ni Alákòóso William Howard Taft fẹ East Wing ó sì ṣẹ̀dá Oval Office àkọ́kọ́, èyítí a padà gbé kúrò tí a sì fẹ̀ ẹ́ si. Nínú Ìbùgbé Aláṣẹ, òkè àjà kẹta ti yípadà sí ibi gbígbé ní ọdún 1927 nípasẹ̀ ṣị́ṣẹ àfikún sí òrùlé àwọn ìbùgbé tí ó gùn. East Wing tuntun tí a ṣe ni a lò bí agbègbè fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ; Yàrá Jefferson já pọ̀ mọ́ àwọn yàrá titun yìí. Àwọn ìyípadà East Wing ti parí ní ọdún 1946, ṣíṣẹ̀dá ààyè ọ́fììsì àfíkún. Ní ọdún 1948, a ṣàkíyèsí àwọn odi ilé náà pé wọn kò dára mọ́. Lábẹ́ Harry S. Truman, gbogbo àwọn yàrá inú ilé ni a túká pátápátá tí a sì lo irin tó kúnjúòṣùwọ̀n. Ní ìta, a ṣe àfikún Truman Balcony. Ní kété tí iṣẹ́ ìgbékalẹ̀ náà ti parí, àwọn yàrá inú di àtúnṣe.

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "The White House". The White House. Retrieved 2020-01-04. 
  2. Stevenson, Chris; Stevenson, Chris; Stevenson, Chris; Stevenson, Chris; Gray, Lucy Anna; Michallon, Clémence (2020-01-04). "White House". The Independent. Retrieved 2020-01-04. 
  3. "White House - History, Location, & Facts". Encyclopedia Britannica. 2019-12-05. Retrieved 2020-01-04. 
  4. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named TSGjH
  5. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named bwDpG