Wikipẹ́díà l'édè Yorùbá
URL | http://yo.wikipedia.org/ |
---|---|
Commercial? | No |
Type of site | Internet encyclopedia project |
Registration | Optional |
Available language(s) | Yoruba |
Owner | Wikimedia Foundation |
Wikipẹ́díà l'édè Yorùbá ni àgbéjáde Wikipedia ní èdè Yorùbá. Ó bẹ̀rẹ̀ ní osù kẹwàá ọdún 2002,[1] lọ́wọ́lọ́wọ́ ó ní iye àyọkà 34652 àti àwọn oníṣe aforúkọsílẹ̀ 29,976, Wikipẹ́díà l'édè Yorùbá ní Wikipedia ẹ̀kẹta tótóbijùlọ nínú àwọn Wikipẹ́díà l'édè Áfríkà lẹ̀yìn èdè Lárúwábá àti èdè Swahili, òhun ni Wikipedia 105k tótóbijùlọ nínú àwọn èdè lágbàáyé. Wikipẹ́díà l'édè Yorùbá ti jẹ́ ìkan nínú àwọn Wikipedia aṣíwájú 3 tàbí 4 Wikipedia l'édè Áfríkà bóṣejẹ mọ́ iye àwọn àyọkà tó ní láti ọdún 2008.[2]
Ní ọdún 2012 ní ibi ìpàdé Wikimania 2012, Jimmy Wales fún ìkan nínú àwọn olóòtú Wikipẹ́díà l'édè Yorùbá ní ẹ̀yẹ ẹ̀bùn Wikipedian of the Year fún ìkópa àti iṣẹ́ rẹ̀ lórí Wikipẹ́díà l'édè Yorùbá.[1][2][3]
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |