Wikipedia:Àyọkà ọṣẹ̀ 15 ọdún 2020

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Máápù Nàìjíríà
Máápù Nàìjíríà

Nàìjíríà tó jẹ́ mìmọ̀ fún isiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi 'Orílẹ̀-èdè Olómìnira Àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà' (Nigeria ni èdè Gẹ̀ẹ́sì) jẹ́ orílẹ̀-èdè ìjọba àpapọ̀ olómìnira pẹ̀lú iwe ìlànà-ìbágbépọ̀, to je pinpin si ìpínlẹ̀ mẹ́rindínlógójì àti Agbègbè Olúìlú Ìjọba Àpapọ̀. Ó bùdó sí apá ìwọ̀òrùn Afrika. Ilẹ̀ rẹ̀ ní bodè mọ́ Benin ní apá ìwọ̀òrùn, Nijẹr ní apá àríwá, Tshad àti Kamẹróòn ní apá ìlàòrùn àti Òkun Atlantiki ni apá gúúsù. Abuja ni olúìlú rẹ̀. Botilejepe ile Naijiria ni eya awon eniyan pupo, awon meta ni won tobijulo, ti won si pojulo. Awon wonyi ni Hausa, Ígbò ati Yorùbá.

Àwọn ará Nàìjíríà ní ìtàn fífẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ̀rí ìmọ̀-aíyejọ́un fihàn pé àwọn ìgbé ènìyàn ní agbègbè ibẹ̀ lọ sẹ́yìn dé kéré pátápátá ọdún 9000 kJ. Agbegbe Benue-Cross River je riro gege bi ile akoko awon Bantu arokere ti won fan ka kiri opo arin ati apaguusu Afrika bi iru omi ni arin egberundun akoko kJ ati egberundun keji.

Naijiria ni orile-ede to ni onibugbe pupojulo ni Afrika, ikejo ni agbaye, be si ni o je orile-ede to ni awon eniyan alawodudu julo laye. O je kikojo mo ara awon orile-ede ti a n pe "Next Eleven" ni to ri okowo won, o si tun je ikan ninu Ajoni awon Ibinibi. Okowo ile naijiria je ikan ninu eyi to n dagba kiakiajulo laye, pelu IMF to ngbero idagba 9% fun 2008 ati 8.3% fun 2009. Ni ibere awon odun 2000, ogunlogo awon onibugbe gbe pelu iye to din ju US$ 1.25 (PPP) lojumo. Naijiria ni okowo re tobijulo ni Afirika, ati alagbara ni agbegbe Iwoorun Afirika. '(ìyókù...)'