Jump to content

Wikipedia:Ayoka ose 13 2010

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ogagun Colin Powell

Ọ̀gágun Colin Luther Powell (ọjọ́ìbí 5 April, 1937) jẹ́ ẹni àyẹ́sí ọmọ ilẹ̀ Amerika àti Ọ̀gágun onirawo merin to ti feyinti kuro ni Ile-ise Ologun Jagunjagun ile Amerika. O tun je Alakoso Oro Okere ile Amerika lati 2001 - 2005 labe Aare George W. Bush. Ohun ni eni alawodudu akoko ti yio gun ori ipo yi. Nigbato wa ni enu ise ologun, Powell tun je Alábàágbìmọ̀pọ̀ Ọ̀rọ̀ Àbò Orílẹ́-èdè ile Amerika (National Security Advisor, 1987-1989); Apase, Ile-ise Alase awon Ologun Jagunjagun ile Amerika (U.S. Army Forces Command, 1989); ati Alaga Ijokopápo awon Oga Omo-ologun ile Amerika (Chairman, U.S. Joint Chiefs of Staff, 1989-1993), ori ipo yi lowa nigbati Ogun Ikùn Odò Persia sele. Ohun ni o je eni alawodudu akoko, ati soso titi doni, ti yio kopa ninu Ijokopapo awon Oga Omo-ologun ile Amerika (Joint Chiefs of Staff).

...lẹ́kùnrẹ́rẹ́