Colin Powell

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Ọ̀gágun

Colin Luther Powell
Colin Powell official Secretary of State photo.jpg
65th Alakoso Oro Okere ile Amerika
Lórí àga
January 20, 2001 – January 26, 2005
Ààrẹ George W. Bush
Deputy Richard Armitage
Asíwájú Madeleine Albright
Arọ́pò Condoleezza Rice
12th Alaga Ijokopápo awon Oga Omo-ologun ile Amerika
Lórí àga
October 1, 1989 – September 30, 1993
Ààrẹ George H. W. Bush
Bill Clinton
Deputy Robert T. Herres (1989)
David E. Jeremiah (1989-1993)
Asíwájú William J. Crowe
Arọ́pò David E. Jeremiah
16th Alábàágbìmọ̀pọ̀ Ọ̀rọ̀ Àbò Orílẹ́-èdè ilẹ̀ Amẹ́ríkà
Lórí àga
1987–1989
Ààrẹ Ronald Reagan
Deputy John Negroponte
Asíwájú Frank Carlucci
Arọ́pò Brent Scowcroft
Personal details
Ọjọ́ìbí Oṣù Kẹrin 5, 1937 (1937-04-05) (ọmọ ọdún 82)
New York City, New York, U.S.A.
Ẹgbẹ́ olóṣèlu Republican
Spouse(s) Alma Vivian Johnson Powell
Alma mater City College of New York
George Washington University
Profession Soldier
Statesman
Military service
Allegiance United States of America
Service/branch Army
Years of service 1958-1993
Rank General
Unit 3rd Armored Division
Americal Division
Commands Forces Command
Battles/wars Vietnam War
Invasion of Panama
Gulf War

Colin Luther Powell (ọjọ́ìbí 5 April, 1937) jẹ́ ẹni àyẹ́sí ọmọ ilẹ̀ Amerika àti Ọ̀gágun onirawo merin to ti feyinti kuro ni Ile-ise Ologun Jagunjagun ile Amerika. O tun je Alakoso Oro Okere ile Amerika lati 2001 - 2005 labe Aare George W. Bush. Ohun ni eni alawodudu akoko ti yio gun ori ipo yi.[1][2][3][4] Nigbato wa ni enu ise ologun, Powell tun je Alábàágbìmọ̀pọ̀ Ọ̀rọ̀ Àbò Orílẹ́-èdè ile Amerika (National Security Advisor, 1987-1989); Apase, Ile-ise Alase awon Ologun Jagunjagun ile Amerika (U.S. Army Forces Command, 1989); ati Alaga Ijokopápo awon Oga Omo-ologun ile Amerika (Chairman, U.S. Joint Chiefs of Staff, 1989-1993), ori ipo yi lowa nigbati Ogun Ikùn Odò Persia sele. Ohun ni o je eni alawodudu akoko, ati soso titi doni, ti yio kopa ninu Ijokopapo awon Oga Omo-ologun ile Amerika (Joint Chiefs of Staff).

Ìgbà èwe[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bi Colin Luther Powell ni ojo 5 osu kerin odun 1937 ni Harlem to je adugbo kan ni ilu New York fun Luther Theophilus Powell ati Maud Arial McKoy ti won ko wa sibe lati ile Jamaika. O si dagba ni South Bronx. Apa awon obi re kan tun wa lati ile Skotlandi ati Irelandi. Powell lo si ile eko Morris High School to fi igba kan je ti igboro ni Bronx, o pari nibe ni 1954.

Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ní Ilé-iṣẹ́ Ológun[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Powell darapo mo Reserve Officers' Training Corps ni ile eko City College ni New York o si salaye re leyin igba na gege bi iriri ti o mu inu re dunjulo laye re, pe ohun ti ri ohun ti ohun feran ti ohun si mọ̀ọ́ ṣe, lokan re pe "öhun ti wa ara ohun ri." Gege bi Kèdẹ́ẹ̀tì, Powell darapo mo egbe awon Ayìnbọn Pershing ni City College. Nigbato pari eko re ni City College ni 1958, o gba ipo gege bi igbaketa ajagun ni Ile-ise Ologun Jagunjagun ile Amerika (second lieutenant, United States Army).[5] Osise omo-ogun lo je fun odun 35, o di orisirisi ile-ise apase ati ipo alabasisepo mu titi to fi goke de ipo Ogagun ni 1989.[6]


Ọjọ́ọdún tó dé àwọn ipò rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

 • Igbákẹta Ajagun (Second Lieutenant): June 9, 1958
 • Igbákejì Ajagun (First Lieutenant}: December 30, 1959
 • Ajagun Ile-ise Ologun Jagunjagun ile Amerika (Captain, U.S Army): June 2, 1962
 • Àgbàogun (Major): May 24, 1966
 • Igbákejì Akógun (Lieutenant Colonel): July 9, 1970
 • Akógun (Colonel): February 1, 1976
 • Ọ̀gágun Ẹlẹ́ẹ̀ṣọ́ (Brigadier General): June 1, 1979
 • Ọ̀gágun Àgbàogun (Major General): August 1, 1983
 • Igbákejì Ọ̀gágun (Lieutenant General): March 26, 1986
 • Ọ̀gágun (General): April 4, 1989


Àwọn ìgbésókè
Okùn Ipò Ọjọ́ọdún
US-O10 insignia.svg ỌGG-GEN 1989
US-O9 insignia.svg IỌG-LTG 1986
US-O8 insignia.svg ỌA-MG 1983
US-O7 insignia.svg ỌẸ-BG 1979
US-O6 insignia.svg AKO-COL 1976
US-O5 insignia.svg IAK-LTC 1970
US-O4 insignia.svg AO-OMAJ 1966
US-O3 insignia.svg AJA-CPT 1962
US-O2 insignia.svg 2AJA-1LT 1959
US-O1 insignia.svg 3AJA-2LT 1958

Awon Ebun ati eye[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Awọn ìlẹ̀máyà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Alábàágbìmọ̀pọ̀ Ọ̀rọ̀ Àbò Orílẹ́-èdè[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nigbato di omo odun 49, Powell di Alábàágbìmọ̀pọ̀ Ọ̀rọ̀ Àbò Orílẹ́-èdè fun Aare Ronald Reagan lati 1987 titi di 1989 lai fi ipo re sile gege bi igbakeji ogagun (lieutenant general). Nigbato pari ise Igbimo Oro Abo ile Amerika, Powell gba igbesoke si ipo Ogagun labe Aare George H.W. Bush, o si sise nigba die gege bi Alase, Ile-ise Apase awon Ologun Jagunjagun ile Amerika, to un mojuto gbogbo Ologun Jagunjagun, Ologun Jagunjagun Alagbepamo, ati awon eyo Ile-ise Ologun Oluso ile Amerika (U.S. National Guard) fun orile Amerika, Alaska, Hawaii ati Puerto Rico.

Alaga Ijokopapo awon Oga Omo-ologun[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Afunse ise ologun to se gbeyin, lati October 1, 1989 titi di September 30, 1993 ni gege bi Alaga ikejila Ijokopapo awon Oga Omo-ologun, eyi ni ipo ologun togajulo ni Ile-ise Alakoso Oro-àbò ile Amerika (U.S. Dept. of Defense).


Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

 1. The first African American secretary of state, Colin Powell, The African American Registry
 2. Biographies - Colin Powell: United States Secretary of State, African American History Month, US Department of Defense
 3. Colin Powell, Britannica Online Encyclopedia
 4. Profile: Colin Powell, BBC News
 5. "Secretary of State Colin L. Powell (biography)". The White House. 2003-04-29. Retrieved 2007-02-03. 
 6. "Colin (Luther) Powell Biography (1937 - )". The Biography Channel. A&E Television Networks. Retrieved 2007-05-31. 


Iwe kika lekunrere[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Fidio[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Awon ijapo Interneti[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wikiquote logo
Nínú Wikiquote a ó rí ọ̀rọ̀ tójẹmọ́:
Wikisource-logo.svg
Wikisource has original text related to this article:
Wikinews-logo.svg
Wikinews ní ìròhìn lórí ọ̀rọ̀ yíì: