Àjẹsára ọ̀fìnkì
Àjẹsára ọ̀fìnkì, tí a tún mọ̀ sí àbẹ́rẹ́ ọ̀fìnkì, jẹ́ àjẹsára tí ń dáàbò bo ni lọ́wọ́ ọ̀fìnkì.[1] A má a ń ṣe àgbéjáde ẹ̀yà àjẹsára náà titun lẹ́ẹ̀mejì lọ́dún nítorí tí kòkòrò àrùn àìlèfojúrí afàìsàn ọ̀fìnkì a má a paradà kíákíá.[1] Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn a má a pèsè ààbò tó mọ níwọ̀n àti èyí tó lágbára púpọ̀ fúnni lọ́wọ́ ọ̀fìnkì; ṣùgbọ́n, èyí a má a yàtọ̀ láti ọdún dé ọdún.[2][1] Ẹ̀rí iṣẹ́ rẹ̀ lára àgbàlagbà tí ọjọ́-orí rẹ̀ ti ju ọdún 65 lọ kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀.[3][4] Wọn a má a dín iye ọjọ́ tí àwọn ènìyàn kò fi níí lè lọ sí ibi-iṣẹ́ kù sí bíi ìdajì ọjọ́ bí a bá wòó lápapọ̀.[5] Fífún àwọn ọmọdé ní àjẹsára lè dáàbò bo àwọn ẹlòmíràn tó wà ní àyíká wọn.[1]
Àti Àjọ Ìlera Àgbáyé àti Ilé-iṣẹ́ Ìṣàkóso àti Ìdènà Àrùn ni ó gba ni níyànjú pé kí gbogbo ẹnití ọjọ́-orí rẹ̀ bá ti ju oṣù 6 lọ má a gba àjẹsára náà lọ́dọọdún.[1][6] Èyí ṣe pàtàkì púpọ̀ pàápàá jùlọ fún àwọn obìrin tó ní oyún, àwọn ọmọdé tí ọjọ́-orí wọn jẹ́ bí oṣù mẹ́fá sí ọdún máàrún, àwọn tó ní ìṣòrò yòówù nípa ìlera wọn, Àwọn Ọmọ Abínibí Amẹ́ríkà, àti àwọn òṣìṣẹ́ ìlera.[1][7]
Àwọn àjẹsára náà kò léwu láti lò. Ní àárín àwọn ọmọdé ibà a má a wáyé láàárín iye àwọn ọmọ tó tó ìwọ̀n 5 sí 10 nínú ọgọ́ọ̀rún, bẹ́ẹ̀ sì ni ìrora nínú ẹran-ara, àti àárẹ̀ náà lè wáyé. Ní àwọn ọdún mìíràn, láàárín àwọn àgbàlagbà, àjẹsára náà a má a fa àìsàn tí à n pè ní Guillain Barre syndrome ní ìwọ̀n egbògi náà kan nínú mílíọ̀nù kan. A kò gbọdọ̀ lòó fún àwọn tó ní ìfèsì ara ẹni lọ́nà tó burú púpọ̀ sí ẹyin tàbí sí oríṣi àjẹsára náà àtijọ́. Wọn a má a wá bíi oríṣi tí a fi kòkòrò afàìsàn àìlèfojúrí tí a ti pa ṣe, àti bíi oríṣi tí a fi kòkòrò afàìsàn náà ti a ti sọ di aláìlágbára ṣe. Oríṣi tí a fi kòkòrò afàìsàn tí a ti pa ṣe ni a gbọ́dọ̀ lò fún àwọn aboyún. Wọn a má a wá bíi oríṣi tí à ń gún bí abẹ́rẹ́ sínú ẹran-ara ẹni tàbí bíi oríṣi tí à ń fún sínú imú ẹni.[1]
Gbígba àjẹsára fún ààbò lọ́wọ́ ọ̀fìnkì bẹ̀rẹ̀ ní àwọn ọdún 1930, nígbàtí wíwà fún lílò gbogbogbò ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1945.[8][9] Ó wà lórí Àkójọ Àwọn Egbògi Kòṣeémáàní ti Àjọ Ìlera Àgbáyé, àwọn òògùn tó ṣe pàtàkì jùlọ tí a nílò fún ètò ìlera ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ yòówù.[10] Iye owó rẹ̀ lójú pálí jẹ́ bíi 5.25 USD fún ìwọ̀n egbògi náà kanṣoṣo ní ọdún 2014.[11] Ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà iye owó rẹ̀ kò tó 25 USD.[12]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Jump up to: 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 1.5 1.6 "Vaccines against influenza WHO position paper – November 2012."
- ↑ Manzoli L, Ioannidis JP, Flacco ME, De Vito C, Villari P (July 2012).
- ↑ Osterholm, MT; Kelley, NS; Sommer, A; Belongia, EA (Jan 2012).
- ↑ Jefferson, T; Di Pietrantonj, C; Al-Ansary, LA; Ferroni, E; Thorning, S; Thomas, RE (Feb 17, 2010).
- ↑ Jefferson, T; Di Pietrantonj, C; Rivetti, A; Bawazeer, GA; Al-Ansary, LA; Ferroni, E (13 March 2014).
- ↑ "Who Should Get Vaccinated Against Influenza".
- ↑ "Influenza Virus Vaccine Inactivated".
- ↑ Compans, Richard W. (2009).
- ↑ Vaccine Analysis: Strategies, Principles, and Control.
- ↑ "19th WHO Model List of Essential Medicines (April 2015)" (PDF).
- ↑ "Vaccine, influenza"[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́].
- ↑ Hamilton, Richart (2015).