Jump to content

Wole Oladiyun

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Wole Oladiyun tí ọjọ́ ìbí Jẹ́ ọjọ́ Kejì oṣù kẹrin ọdún 1959, jẹ́ àlùfáà kàn ní orílé èdè Nàìjíríà, Òǹkọ̀wẹ̀, onísòwò, ìmọ Ẹ̀rọ (engineer) àti Olùdarí/Olùdásílẹ̀ ilé ìjósìn tí orúko rè ń jẹ́ Christ of Living Spring Apostolic Ministry (CLAM).[1][2]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìgbé ayé àti Ètò Ẹ̀kọ́

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àlùfáà Oladiyun jẹ́ ọmọ bíbí Ilé Olúji ní ìpínlè Òndó ní orílé èdè Nàìjíríà tí ojú ibí rẹ̀ sí jẹ́ ọjọ keji oṣù kẹrin, ọdún 1959. Àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì jọ àlùfáà ilé ìjósìn, nígbà tí bàbá rẹ̀ jẹ́ Alàgbà, tí ìyá rẹ̀ sí jẹ́ Díkínẹ́sì ní ilé ìjósìn Àpọsítélì tí Kírísítì (Christ Apostolic Church). Ó kẹ́kọ̀ọ́ gbọyè ní ìmọ Ẹ̀rọ ní Fásitì tí ó wà ní Ilé Ìfẹ. Ó tẹ́sìwajú láti kẹ́kọ̀ọ́ gbọyè MBA ní Netherlands Business School ní Holland.[3]

Lẹ́yìn ayẹyẹ ìparí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Fásiti Ọbáfẹmi Awólọ́wọ̀ ní ilé ifè, Àlùfáà Oladiyun bẹ̀rẹ̀ iṣẹ títà Páàti Ọkọ̀, àwọn kẹ́míkà àti Igi èyí tí kò wá ní ìbámu tàbí lọnà òun tí ó pinnu láti ṣe tí ó wà lọkàn rẹ tíi ṣe Ìṣe Ọlọ́pàá.[4]

Iṣẹ́ Ìráńsẹ́

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àlùfáà Oladiyun lọsí Latter Rain Bible School tí ó wà ní ìpínlè Èkó. Ó kàwé náà ní Deeper Life Bible Church. Bákan náà, ó fi ará rẹ̀ silẹ láti di ìgbà Kejì Rev. (Dr). D.K Abóderìn tíì ṣe Àlùfáà àgbà ní Faith Family Bible Church, ti ó wà ní òjòdú ní Ìlú Èkó. Ó mú Àlùfáà Matthew Aṣímolówò gẹ́gẹ́ bí olùtọ̀nà nínú isé ìránṣẹ́.[5]

Àlùfáà Ọládiyùn ṣe ìgbéyàwó ní ọdún 1990 pẹ̀lú Búkọlá Ọládiyùn tí òun náà jẹ́ Àlùfáà nínú iṣẹ́ Ìráńsẹ́ Àlùfáà Ọládiyùn. Wn sí jọ bí ọmọ mẹ́rin pápọ tí wọ́n sì ní àwọn ọmọ-ọmọ mẹ́ta.[6]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Ajaja, Tunde (28 November 2021). "Nigeria’s obsolete curriculum limiting innovation, tech development – Cleric". Punch. https://punchng.com/nigerias-obsolete-curriculum-limiting-innovation-tech-development-cleric/. 
  2. Akaniyene, Idara (6 December 2021). "Our educational system is obsolete, we need hands-on graduates, says cleric". The Guardian. Archived from the original on 16 March 2022. https://web.archive.org/web/20220316051506/https://guardian.ng/news/our-educational-system-is-obsolete-we-need-hands-on-graduates-says-cleric/. 
  3. Oyewale, Femi (11 October 2014). "Inside CLAM’s N5 billion ministry". Encomium. https://encomium.ng/inside-clams-n5-billion-ministry/. 
  4. Ake, Ayodeji (5 April 2019). "Pastor Wole Oladiyun: ‘I Sold Spare Parts, Wood Before My Calling’". This Day Live. https://www.thisdaylive.com/index.php/2019/04/05/pastor-wole-oladiyun-i-sold-spare-parts-wood-before-my-calling/. 
  5. Ake, Ayodeji (5 April 2019). "Pastor Wole Oladiyun: ‘I Sold Spare Parts, Wood Before My Calling’". This Day Live. https://www.thisdaylive.com/index.php/2019/04/05/pastor-wole-oladiyun-i-sold-spare-parts-wood-before-my-calling/. 
  6. Ebhomele, Eromosele (19 April 2013). "The Flashy Wives Of Nigerian Pastors". PM News. https://pmnewsnigeria.com/2013/04/19/the-flashy-wives-of-nigerian-pastors/.