Wolfgang Amadeus Mozart

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lọ sí: atọ́ka, àwárí
Wolfgang Amadeus Mozart

Wón bí Mozart ní 1756. Ó kú ní 1791. Ó jé òkan nínú tí ó máa n ‘Compose’ orin. Gbajúgbajà ni nínú isé yìí. Láti nnkan bí omo odún méta ni ó ti ní etí inú fún orin. Láìpé sí ìgbà yìí ni ó ti bèrè sí níí lo òpòlopò irin isé tí wón fi n korin. Salzburg ní Austria ni wón ti bíi. Ìlú yìí ni bàbá rè ti n sisé orin kíko ní ààfin Archbishop ti Salzburg.

Omo odún méfà ni Mozart nígbà tí ó bèrè isé orin gan-an. Ó bá bàbá rè àti àntí rè se ìrìnàjò lo sí ìlú Òyìnbó. Àntí rè yìí náà mo orin-ín ko gan-an ni. Gbogbo ènìyàn ló n gbé won gègé ní gbogbo ibi ti wón lo. Ìgbà yìí ni Mozart ti bèrè síí ko orin fún ara rè.

Kò sí irú orin tí Mozart kò lè ko. Ó n ko opera, choral music, orchestral music àti chamber music. Ara àwon opera tí ó ko ni ‘The Marrcege of figaro’ ‘Dio Giovanni’ àti The Magic Flute’. Nínú won, the Magic Flute ni ó gbajúmò jù.

Lára àwon symphonies bí ogójì tí ó ko ‘Jupiter’ tàbí ‘Symphony C major’. ‘Symphony ni G minor’ àti ‘the Symphony in E flat major’ ni òpò so pé ó dára jù lára isé rè. Àwon isé rè mìíràn tí ó lápere ni ‘Eine Kleine Nachtmusik’ ti ó jé ‘serenade’ àti ‘Sinfonia Concertante’ tí ó jé ‘concerto’ fún violin àti viola.

Lékèé gbogbo isé tí ó se yìí, kò lówó. Omo odún márùndínlógájì péré ni nígbà tí ó kú wón sì sin ín sí ibi tí wón máa n sin àwon òtòsì sí ní Vienna.