Yejide Kilanko
Yejide Kilanko(tí a bí ní ọdún 1975) jẹ́ ọ̀ǹkọ̀wé ìwé Ìtàn àrọ̀sọ àti òṣìṣẹ́ àwùjọ ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti orílẹ̀ èdè Kánádà. Ó jé gbajúmọ̀ fún sísọ ìwà-ipá sí àwọn obìnrin nínú iṣẹ́ rẹ̀. Ìtàn àkọ́kọ́ tí ó tẹ̀ jáde, Àwọn ọmọbìnrin tí ó Rin ọ̀nà yìí, Ìtàn Àrọ̀sọ orílẹ̀ èdè Canada jẹ́ olutàjà tí ó dára jù lọ ní ọdún 2012.
Ìgbésí ayé ìbẹ̀rẹ̀ àti ẹ̀kọ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]A bí Kilanko ní ọdún 1975 ní Ìlú Ìbàdàn Nàìjíríà, ní ibi tí bàbá rẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́bí olùkọ́ ilé-ẹ̀kọ́ gíga. Ó bẹ̀rẹ̀ Ẹ̀wì kíkọ láti kékeré.[1][2][3] Ó kẹ́kọ̀ọ́ sáyẹ́ǹsì ìṣèlú ní Yunifásítì ìlú Ìbàdàn.[4]
Gbé lọ sí Ìlú Kánádà àti iṣẹ́ àwùjọ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọdún 2000, Kilanko kúrò ní Nàìjíríà, ó fẹ́ ọmọ Amẹ́ríkà kan ó sì kó lọ sí Laurel, Maryland, ní Amẹ́ríkà. Ní ọdún 2004, ó kó lọ sí orílẹ̀ èdè Kánádà, ní ibi tí ó ń gbé ní Chatham_Kent, Ontario.[5][6][7]
Maryland, ni AmẹrikaÓ tún kó lọ sí u Kana ,í ọdún 2004,ní ibi tó ń gbé báyìínií i Chatham-Kent, Ontario .
Ní Ìlú Kánádà, ó kọ́ ẹ̀kọ́ nípa Iṣẹ́ Àwùjọ ní University of Victoria ati University of Windsor.[8] Ó ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí Oníwòsàn ní Ìlera Ọpọlọ àwọn ọmọdé.[9]
Ìwé kíkọ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Kilanko kọ́kọ́ gbá ojú mọ́ Ewì, ìgbà tí ó yá ó yí padà sí ìtàn àròsọ̀. Ó pinnu láti kọ ìwé ìtàn àkọ́kọ́ lẹ́yìn ìpènijà pẹ̀lú hílàhílo tí ó gbọ́ nípa ìrírí àwọn ọmọdé tí ó bá ṣíṣe pọ̀ gẹ́gẹ́ bí Olùgbani_nímọ̀ràn nípa ìlera ọpọlọ.[10]
Ìwé àkọ́kọ́ rẹ̀ , Àwọn Ọmọbìnrin tí ó Rin Ọnà yìí (Daughters Who Walk This Path) tí a tẹ̀ jáde ní ọdún 2012.[11][12][13] Ṣètò ní ìlú abínibí rẹ̀, Ìbàdàn, ó dá lórí ìfípábanilòpọ̀ àti ìwà-ipá si àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé ní Nàìjíríà, a sọ ọ́ nípasẹ̀ ojú ọmọdé tó ń sọ ìtàn. Àwọn tó ń ṣe Àgbéyẹ̀wọ̀ ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí fífọ́ ààlà lórí èèwọ̀ ti ìjíròrò ìfípábanilòpọ̀, pàápàá jù lọ lórí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[14][15]
Àwọn Ọmọbìnrin tí ó Rin Ọnà yìí (Daughters Who Walk This Path) jẹ́ Canada National Fiction ìwé tí ó tà jù lọ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọsẹ̀.[16][17][18] Wọ́n gbe jáde lórí àtòjọ Globe and Mail ti Ọgọ́rùn-ún (100)ìwé tí ó dára jù lọ ní ọdún 2012.[19] Ní Ọdún 2014 ọ̀ǹkọ̀wé ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà Chimamanda Ngozi Adichie dámọ̀ràn ìwé náà fún ìwé tí wọ́n ń kà nígbà Ẹ̀ẹ̀rù (Summer Reading) nínú The Guardian.[20]
Wọ́n yan ìwé ìtàn náà fún Nigeria Prize for Literature ní 2016, lẹ́yìn tí àtẹ̀wẹ́ ọmọ Nigeria kan gbe jáde ní bẹ̀.[21][22] Ẹ̀bùn náà lọ sí ọwọ́ Abubakar Adam Ibraheem fún ìwé rẹ̀, ìyẹn Season of Crimson Blossom.[23]
Iṣẹ́ lemọ́-lemọ́ rẹ̀ lórí Ìtàn-Àrọ̀sọ, The novella Chasing Butterflies, ni a tẹ̀ jáde ní 2015 gẹ́gẹ́ bíi Àjọ tó ń kó owó jọ fún Wordreader.[24][25] It also discusses violence against women, focusing on domestic violence Ó tún jíròrò lórí ìwà-ipá sí àwọn obìnrin, tí ó sì ṣe àfojúsùn lórí ìwà-ipá ti abẹ́-ilé.[26][27]
Ní ọdun 2018, ó ṣe àtẹ́jáde ìwé àwọn ọmọdé kan, Erin wà nínú Aṣọ Mí (There ìs án Elephant ín My Wardrobe), èyí tí ó pinnu láti ṣe ìrànwọ́lọ́ fún àwọn ọmọdé pẹlu aibalẹ.[28] [29]
Látàrí ìwé ìtàn Ìwé àfọwọ́kọ rẹ̀(Manuscript) "èyí tí ó jẹ́ ìtàn tòótọ́ tí ó tún ṣe àfikún nípa àwọn ọmọbinrin nọ́ọ́sì ọmọ Nàìjíríà tó ń gbé ní Amẹ́ríkà tí àwọn ọkọ tí ó jù wọn lọ ṣekúpa " jẹ́ ìwé tí wọ́n kó sínú àkọsílẹ̀ fún Ẹ̀bùn Guernica ti ìlú Kánádà fún Literary Fiction ni Ọdún 2019 lábẹ́ àkọlé ìṣẹ́ Moldable Women.[30][31] Wọ́n tẹ̀ jáde ní ọdún 2021 gẹ́gẹ́ bíi Orúkọ Rere (Good Name).[32][33]
Ikú rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Kilanko pe ara rẹ̀ ní Alátìlẹyìn ìn tó ń jà fẹ́tọ̀ọ́ obìnrin àti ṣíṣe àpèjúwe iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi àtìlẹyìn fẹ́tọ̀ọ́ ọmọbìnrin. Ó ní àwọn Òǹkọ̀wé Obìnrin tí ilẹ̀ Áfíríkà àti ti ilẹ̀ Áfíríkà Amẹ́ríkà bíi Buchi Emecheta, Chika Unigwe, Toni Morrison àti Alice Walker ni Ipa púpọ̀ lórí òun gidigidi.[34]
Àṣàyàn àwọn iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Daughters Who Walk This Path (2012)
- Chasing Butterflies (2015)
- There Is an Elephant in My Wardrobe (2018)
- A Good Name (2021)
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Newcomer Stories: Yejide Kilanko". Chatham-Kent (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-06-18. Retrieved 2020-11-14.
- ↑ Mbaye, Ndeye Sene (2013-04-22). "Daughters who walk the path by Yejide Kilanko". Afrobooks (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-11-14.
- ↑ "Yejide Kilanko". Penguin Random House (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-11-14.
- ↑ "Yejide Kilanko". Ottawa International Writers Festival. 2012. Retrieved 2020-11-14.
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs named:03
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs named:32
- ↑ Carlucci, Paul (2012-09-10). "Africa: Review - Daughters Who Walk This Path". AllAfrica (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-11-14.
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs named:12
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs named:33
- ↑ Mordi, Melissa (2019-06-03). "Yejide Kilanko: Shattering The Shackles Of Silence Through Writing". The Guardian Life. Retrieved 2020-11-14.
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs named:05
- ↑ Ullery, Sarah (2018-05-17). "10 Books by Nigerian Authors with Feminist Themes". Book Riot (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-11-14.
- ↑ Kelly, Joanne (2012-04-28). "Setting helps tell dark story" (in en-CA). Winnipeg Free Press. https://www.winnipegfreepress.com/opinion/fyi/setting-helps-tell-dark-story-149344425.html.
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs named:42
- ↑ Martin, Diana (2012-05-03). "This is for all the silent daughters; NOVEL: Newly published work encourages the abused to seek help". Chatham Daily News.
- ↑ "Yejide Kilanko signs contract for new book". The Daily Trust. 2019-10-26.
- ↑ "BESTSELLERS". The Globe and Mail. 2012-05-05.
- ↑ "BESTSELLERS". The Globe and Mail. 2012-06-23.
- ↑ "The Globe 100". The Globe and Mail. 2012-11-24.
- ↑ "Best holiday reads 2014 - top authors recommend their favourites" (in en-GB). The Guardian. 2014-07-12. ISSN 0261-3077. https://www.theguardian.com/books/2014/jul/12/best-holiday-reads-2014-writers-critics-recommendations.
- ↑ "11 Authors Shortlisted for the Nigerian Prize for Literature 2016". AllAfrica. 2016-07-17. https://allafrica.com/stories/201607170238.html.
- ↑ Lasisi, Akeem (2016-07-15). "Women writers dominate shortlist of $100,000 literature prize". The Punch Newspaper (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-11-14.
- ↑ Sam-Duru, Prisca (2016-10-13). "2016 Winner of $100,000 Nigeria prize for Literature emerges". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-11-14.
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs named:53
- ↑ Ibrahim, Abubakar Adam (2016-01-30). "'Being a Writer Is a Huge Part of My Identity'". AllAfrica. https://allafrica.com/stories/201601310040.html.
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs named:43
- ↑ "BN Prose – Book Excerpt: Chasing Butterflies by Yejide Kilanko". BellaNaija (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-05-01. Retrieved 2020-11-14.
- ↑ "Yejide Kilanko signs contract for new book". 2019-10-26.
- ↑ "Author tackles issue of child anxiety; Guest book reading part of Black History Month programming". Chatham Daily News. 2010-02-25.
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs named:54
- ↑ "Nigerian makes Guernica Prize 2019 shortlist". The Daily Trust. 2019-09-14.
- ↑ "Yejide Kilanko On the Making of "A Good Name"". BellaNaija (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-04-25. Retrieved 2022-07-20.
- ↑ "65 Canadian works of fiction to watch for in fall 2021". CBC. 2021-08-12. https://www.cbc.ca/books/65-canadian-works-of-fiction-to-watch-for-in-fall-2021-1.6114977.
- ↑ Ibrahim, Abubakar Adam (2016-01-30). "'Being a Writer Is a Huge Part of My Identity'". https://allafrica.com/stories/201601310040.html.