Yetunde Barnabas

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Yetunde Barnabas
Ọjọ́ìbíAbuja, Nigeria
Iṣẹ́
  • Actress
  • Model
  • Producer
Ìgbà iṣẹ́2012–present

Yetunde Barnabas jẹ́ òṣèré, mọ́dẹ́lì àti olùgbé jáde eré fíìmù àgbéléwò ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó gbajúmọ̀ fún igbá orókè tí ó gbé nínú ìdíje obìnrin tí ó rẹwà jùlọ ní ìpínlẹ̀ Abuja ní ọdún 2017[1] àti Miss Tourism ni ọdún 2019[2]. Ó kó ipa Miss Pepeiye nínú eré Papa Ajasco and Company.

Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Yetunde sì ìpínlè Abuja, àmọ́ ó jẹ́ ọmọ Ìpínlẹ̀ Kogí ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Kings of Kings Secondary School kí ó tó wá tẹ̀ síwájú sí ilé ẹ̀kọ́ gíga tí Séríkí Ọlọ́pọlọ Production and Royal Art Academy.[3]

Iṣẹ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ mọ́dẹ́lì nígbà ó lọ fún ìdíje Miss Olókun ní ọdún 2013, òun sì ni ó gbé igbá orókè. Ó ti kópa nínú orísìírísìí ìdíje fún àwọn arẹwà obìnrin bíi Miss Live Your Dream ní ọdún 2014 àti ìdíje tíì obìnrin tí ó rẹwà jùlọ ní ìpínlẹ̀ Abuja ní ọdún 2017. Igbá orókè tí ó kó nínú ìdíje tí Abuja yìí ní o jẹ́ kí ó gbajúmọ̀ gidi gan-an, èyí sì ló jẹ́ kí ilé iṣẹ́ Multichoice fi ṣe àmbásẹ́dọ̀ wọn.[4] Ó kó ipa Miss Pepeiye nínú eré Papa Ajasco, ó sì tì farahàn nínú àwọn eré bíi Erin Folami, Dagogo, Omo Iya Osun àti Elegbenla.[5]

Ẹ̀bùn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọdún 2019, wọ́n yàán kalẹ̀ fún àmì ẹ̀yẹ Most Promising Actress of the Year láti ọ̀dọ̀ Nigerian Achiver's Award[6], Model of the Year láti ọ̀dọ̀ Scream Awards àti Beauty Queen of the Year láti ọ̀dọ̀ Africa Choice Awards. Ní oṣù kẹjọ ọdún 2019, wọ́n yan òhun àti àwọn mọ́dẹ́lì míràn láti ilẹ̀ adúláwò láti ṣe asojú fún ètò Ewatomi èyí tí British Broadcasting Corporation gbé kalẹ̀.[7]

Àṣàyàn àwọn eré tí ó tí ṣe[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • 2017 - date - Papa Ajasco & Company
  • 2017 - Alaya Imarun
  • 2017 - Ede Meji
  • 2018 - Lisa
  • 2018 - Queen Mi
  • 2018 - Omo Iya Osun
  • 2019 - Oka ori ebe
  • 2019 - Imule Aje
  • 2019 - Lori Titi
  • 2019 - Olode
  • 2019 - Omije Afoju
  • 2019 - Knockout
  • 2019 - Dagogo
  • 2019 - Aiye
  • 2019 - Elegbenla
  • 2019 - Bayonle
  • 2019 - Erin Folami

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Acting Miss Pepeiye role, a dream come true –Yetunde Barnabas". The Punch Newspaper. October 14, 2018. Retrieved October 28, 2019. 
  2. Ononye (July 26, 2019). "I Spent Lots Of Fund On Grooming – Yetunde Barnabas". Daily Independent. Retrieved October 28, 2019. 
  3. Odukoya (December 1, 2018). "YETUNDE BARNABAS: I DON’T BECOME RUDE TO Men who try to ask me out". The New Telegraph Newspaper. Archived from the original on October 28, 2019. Retrieved October 28, 2019. 
  4. Odukoya (October 12, 2019). "From Nollywood Starlet To Beauty Queen – Yetunde Barnabas". Daily Independent Newspaper. Retrieved October 28, 2019. 
  5. Correspondents (October 21, 2019). "Yetunde Barnabas bags two new award nominations". The New Telegraph Newspaper. Archived from the original on October 24, 2019. Retrieved October 28, 2019. 
  6. Ebirim (October 18, 2019). "Yetunde Barnabas bags nomination for Promising Actress of the Year". Daily Independent Newspaper. Retrieved October 28, 2019. 
  7. Omotayo (October 18, 2019). "Miss Tourism 2019 Winner, Yetunde Barnabas Stuns In New BBC Campaign". Glamsquad Magazine. Retrieved October 28, 2019.