Yewande Adekoya

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Yéwándé Adékọ̀yà a bíi ní (Ogúnjọ́ oṣù Kìn-ín-ní 1984) ó jẹ́ òsèré orí ìtàgé Nàìjíríà, akọ̀tàn, adarí eré àti olùgbéré jáde ni Ìpínlẹ̀ Èkó ni wọ́n bíi sí àmọ́ ó jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Òsósà-Ìjẹ̀bú ní ìpínlẹ̀ Ògùn gúúsù-ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà. Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti Bright star Nursery and Primary School, kí ó tó tẹ̀ síwájú fún ẹ̀kọ́ gíga sẹ́kọ́ńdírì ní Bright Star Comprehensive High School. Ó gba àmì ẹ̀yẹ Báṣélọ̀ Áàtì (Bí Eè) dìgíríì nínú ìmọ̀ ìbánisọ̀rọ̀ gbogbogbòò ní Ifáfitì Babcock.[1] Yéwándé Adékọ̀yà bẹ̀rẹ̀ eré ṣíṣe ní ọdún 2002 pẹ̀lú ẹgbẹ́ Alphabash Music and Theatre. Eré rẹ̀ àkọ́kọ́ tí ó kọ tí ó sì gbé jáde ní ọdún 2006 tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ 'Àsírí Ayé' (Life secret). Ó ti gbéré jáde, darí àti kópa nínú onírúnrú eré àgbéléwò Nàíjíríà bí àpẹẹrẹ 'Ọmọ Ẹlẹ́mọ̀shọ́' eré ọdún 2012 tí ó ní àwọn akópa bíi Bím̀bọ́ Ọṣìn, Múyìwá Adémọ́lá àti Yọ̀mí Fash-lanso nínú. Eré tí wọ́n yan orúkọ rẹ̀ fún àmì ẹ̀yẹ márùn-ún nínú àmì ẹ̀yẹ African Movie Academy ẹlẹ́ẹ̀kẹwàá irú ẹ̀.[2] Wọ́n tún yàn-án fún àmì ẹ̀yẹ 'sẹ̀sẹ̀ dé tí ó dára jùlọ' ní aagbọn Yorùbá fún àmì ẹ̀yẹ ti "City People Entertainment" ní ọdún 2014. Ní ọdún yìí kan náà, ipa rẹ̀ nínú eré 'Kúdí Klepto' jẹ́ kí wọ́n yan orúkọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré tí ó dára jùlọ nínú akópa pàtàkì ti àmì ẹ̀yẹ 'Best Nollywood ọdún 2014'. Ní oṣù Kejìlá ọdún 2014, ó gba àmì ẹ̀yẹ òsèré 'Most promising actress' ní ibi àmì ẹ̀yẹ Yorùbá Movie Academy. Eré rẹ̀ 'Kùrukùru' fún-un ní àmì ẹ̀yẹ 'òsèré tí ó dára jùlọ' ti ACIA Awards ọdún 2016. Ní ọdún 2017 eré rẹ̀ 'ìyàwó Adédigba' jẹ́ kí ó gba àmì ẹ̀yẹ 'Eré tí ó dára jùlọ lọ́dún' ti 'City People Movie Awards' ọdún 2017.[3]

Àwọn ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Actress Yewande Adekoya shares new photos of her daughter - Kemi Filani News". Kemi Filani News. 2018-07-26. Retrieved 2018-11-26. 
  2. Nigeria, Information (2018-04-14). "9 Things You Probably Don’t Know About Actress-Producer, Yewande Adekoya". INFORMATION NIGERIA. Retrieved 2018-11-26. 
  3. "I Have Fallen More In Love With My Husband --Actress, Yewande Adekoya". Nollywood/ Nigeria No.1 movies/ films resources online. Retrieved 2018-11-26.