Yewande Omotoso

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Yewande Omotoso
Ọjọ́ìbí1980 (ọmọ ọdún 43–44)
Bridgetown, Barbados
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Cape Town
Iṣẹ́Novelist, architect and designer
Notable workBom Boy (2011)
The Woman Next Door (2016)
Àwọn olùbátanKole Omotoso (father); Akin Omotoso (brother)

Yewande Omotoso (tí wọ́n bí ní 1980) jẹ́ òǹkọ̀wé ìwé eré-onítàn tí ó jẹ́ olùgbé South African, ayàwòrán ilé àti a-ṣe-ọ̀ṣọ́, tí wọ́n bí ní Barbados, tí ó sì dàgbà ní Nàìjíríà .[1] Ó jẹ́ ọmọbìnrin òǹkọ̀wé Nàìjíríà Kole Omotoso, àti arábìnrin aṣàgbéjáde fíìmù Akin Omotoso.[2] Ó ń gbé ní Johannesburg.[3] Àwọn ìwé eré-onítàn rẹ̀ méjèèjì tí wọ́n ti tẹ̀ jáde ti fún ní ìdánimọ̀ tí ó tó, àti pẹ̀lú gbígba àmì-ẹ̀yẹ South African Literary Award fún òǹkọ̀wé tí wọ́n tẹ iṣẹ́ rẹ̀ jáde fún ìgbà àkọ́kọ́ ,[4] tí ó sì jẹ́ àṣàyàn fún South African Sunday Times Fiction Prize,,[5] M-Net Literary Awards 2012,[6] àti 2013 Etisalat Prize for Literature,[7] àti tí ó jẹ́ yíyàn fún 2017 Bailey's Women's Prize for Fiction.[8]

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Yewande Omotoso ní Bridgetown, Barbados;[9] àti láàárín ọdún kan tí wọ́n bí i ni òun àti ìyá rẹ̀ ọmọ Barbados lọ, bàbá rẹ̀ ọmọ Nàìjíríà àti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin méjì sí Nàìjíríà. Ó dàgbà ní Ilé-Ifẹ̀, Ìpínlẹ̀ Osun , títí di 1992, nígbà tí ìdílé náà kó lọ sí South Africa[10][11] lẹ́yìn tí bàbá rẹ̀ gba iṣẹ́ akadá pẹ̀lú University of the Western Cape.[12] Ó ti sọ, "Láìnífiṣe iye ọdún tí mo ti gbé ní South Africa, mo ṣì rí ara mi bí i àbájáde ìran mẹ́ta: Barbados, Nàìjíríà, àti South Africa. Nigeria jẹ́ ará tí ó ṣe pàtàkì nínú bí mo ṣe kéèéfín ara mi, ìdánimọ̀ mi",[10] àti nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò 2015 kan, ó ní : "Ìdánimọ̀ le. Mo fẹ́ràn jíjẹ́ ọmọ Nàìjíríà, Mo fẹ́ràn bí mo ṣe jẹ́ ara ìdánimọ̀ náà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé jíjẹ́ tí mo jẹ́ le, torí ìdánimọ̀ púpọ̀ tí mo ní àti ìrírí ayé gbígbé kiki."[13]

Ó kẹ́kọ̀ọ́ architecture ní University of Cape Town (UCT), àti lẹ́yìn tí ó ṣiṣẹ́ fún àwọn ọdún díẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i olùyàwòrán ilé ó lọ láti gba master's degree nínú in Creative Writing ní Yunifásítì kan náà.[11]

Iṣẹ́ ìwé kíkọ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìwé ìtàn àròsọ Omotoso's àkọ́kọ́, Bom Boy, ni wọ́n tẹ̀ jáde ní 2011 láti ọwọ́ Modjaji Books ní Cape Town. Ó gba South African Literary Award 2012 fún akọ̀wé ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n tẹ iṣẹ́ rẹ̀ jáde, wọ́n yàn án fún Sunday Times Fiction Prize ti South Africa, àti fún M-Net Literary Awards 2012.[14] Bom Boy tún gbé ipò kejì fún 2013 Etisalat Prize for Literature,[15] lẹ́yìn tí Omotoso bẹ̀rẹ̀ Etisalat Fellowship 2014 ní University of East Anglia[16] tí ẹni tí ó gba ẹ̀bùn 2013, NoViolet Bulawayo fi sílẹ̀ fún un.[17]

Omotoso jẹ́ 2013 Norman Mailer Fellow, ó sì gbá Miles Morland Scholarship ní 2014.[18][19][20]

Gẹ́gẹ́ bí i Bom Boy, ìwé ìtàn àròsọ rẹ̀ kejì, The Woman Next Door (Chatto and Windus, 2016)[21] gba àyẹ̀wò tí ó dára, pẹ̀lú Publishers Weekly tí wọ́n pè é ní "this charming, touching, occasionally radiant tale of two prickly octogenarians: two women, one black and one white, neighbours who discover after 20 years of exchanging digs and insults that they might help each other... Omotoso captures the changing racial relations since the 1950s, as well as the immigrant experience through personal detail and small psychological insights into mixed emotions, the artist’s eye, and the widow’s remorse. Hers is a fresh voice as adept at evoking the peace of walking up a kopje as the cruelty of South Africa’s past."[22] Irish Independent ṣe àpèjúweThe Woman Next Door gẹ́gẹ́ bí i "a finely observed account of female prejudice, redemption and that often elusive commodity - friendship."[23] Wọ́n yàn án fún Bailey's Women's Prize for Fiction ní 2017,[24][25] àti wọ́n yàn án fún International Dublin Literary Award ti 2018.[26]

Omotoso ti ṣe àfikún àwọn ìtàn àti ewì sí àtẹ̀jáde oríṣìíríṣìí, lára wọn Konch, Noir Nation, Speaking for the Generation: Contemporary Stories from Africa, Contemporary African Women’s Poetry,[27] Kalahari Review, The Moth Literary Journal, One World Two, the 2012 Caine Prize anthology,[28] and New Daughters of Africa (2019), tí Margaret Busby ṣe àtúntò rẹ̀.[29]

Ó jẹ́ olùkópa láti ìgbà dé ìgbà àwọn ọdún iṣẹ́ ọnà, lára wọn ni Aké Arts and Book Festival,[30] Edinburgh International Book Festival[31] àti PEN American World Voices Festival.[32]

Wọ́n ti mọ Omotoso ní àwọn àwùjọ kan fún ìlò àtinúdá rẹ̀ fún àwọn àwòrán afìmọ̀sílára hàn bí ìbòjú juju tí wọ́n sọ lórúkọ ní déédéé.

Ìwé ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Yewande Omotoso biography at African Books Collective.
  2. Shanaaz Prince, "Akin Omotoso: From actor to filmmaker", PressReader, 23 February 2017.
  3. "Your Favorite Writers are Mentoring! | Yewande Omotoso", Writivism, 30 January 2017.
  4. "Yewande Omotoso". www.penguin.co.uk. Retrieved 2020-05-30. 
  5. Vanguard, The Patriotic (2020-04-23). "Nigerian writer Yewande Omotoso". The Patriotic Vanguard (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-05-30. 
  6. "Yewande Omotoso", This is Africa.
  7. "Etisalat Prize for Literature: Again, Nigeria's young writers miss laurel". Guardian Nigeria. Retrieved 2020-05-30. 
  8. "Announcing the 2017 Longlist..." Archived 2019-05-11 at the Wayback Machine., Bailey's Women's Prize for Fiction.
  9. "A Q&A with Yewande Omotoso" Archived 2019-04-22 at the Wayback Machine., Baileys Women’s Prize for Fiction.
  10. 10.0 10.1 Evelyn Osagie, "‘I think of myself as a product of three nations’", The Nation (Nigeria), 19 March 2014.
  11. 11.0 11.1 "Yewande Omotoso (Nigeria/South Africa)", Time of the Writer, Centre for Creative Writing, University of Kwazulu-Natal, 2012.
  12. Africa Film Festival. "Akin Omotoso bio". New York. 
  13. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named Sabi
  14. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named TiA2
  15. "Random facts about Yewande Omotoso" Archived 2017-04-05 at the Wayback Machine., Etisalat Prize for Literature, 3 January 2017.
  16. "The Etisalat Prize brought recognition – Yewande Omotoso" Archived 2020-05-11 at the Wayback Machine., Sabi News, 16 August 2015.
  17. James Murua, "Noviolet Bulwayo gives up Etisalat fellowship to Yewande Omotoso" Archived 2021-02-26 at the Wayback Machine., James Murua's Literature Blog, 16 April 2014.
  18. "2014 Morland Scholarship Winners", Miles Morland Foundation.
  19. "Yewande Omotoso wins Morland Writing Scholarship", University of East Anglia, 27 November 2014.
  20. "Yewande Omotoso new novel sneak peaked" Archived 2019-05-20 at the Wayback Machine., James Murua's Literature Blog, 12 April 2016.
  21. "'Next Door' Neighbors Gradually Learn To Get Along In Post-Apartheid Cape Town". NPR. 12 February 2017. https://www.npr.org/2017/02/12/514495267/next-door-neighbors-gradually-learn-to-get-along-in-post-apartheid-cape-town. 
  22. "The Woman Next Door", Publishers Weekly, 12 May 2016.
  23. Deirdre Conroy, "Fiction: The Woman Next Door by Yewande Omotoso", Irish Independent, 27 June 2016.
  24. "Baileys prize 2017 longlist – in pictures". The Guardian. 8 March 2017. https://www.theguardian.com/books/gallery/2017/mar/08/baileys-prize-2017-longlist-in-pictures. 
  25. "A Q&A with Yewande Omotoso". Women's Prize for Fiction. Retrieved 1 December 2021. 
  26. "The 2018 shortlist is announced, 5th April" Archived 2019-05-21 at the Wayback Machine., International Dublin Literary Award.
  27. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named TOW2
  28. Jennifer Emelife, "My Writing Day (and other tips): Yewande Omotoso", Praxis Magazine, 10 February 2017.
  29. Michele Magwood, "'New Daughters of Africa' Is a Powerful Collection of Writing by Women from the Continent", Wanted, 5 July 2019.
  30. "Yewande Omotoso" at Ake Festival, 2016.
  31. 2016 Edinburgh International Book Festival Brochure.
  32. "Yewande Omotoso" Archived 2020-02-05 at the Wayback Machine., PEN American World Voices Festival.
  33. Bom Boy Archived 2019-05-19 at the Wayback Machine. at Modjaji Books.
  34. The Woman Next Door at Penguin Random House.