Yvonne Orji

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Yvonne Orji
Ọjọ́ìbíYvonne Anuli Orji
2 Oṣù Kejìlá 1983 (1983-12-02) (ọmọ ọdún 40)
Port Harcourt, Rivers State, Nigeria
Ẹ̀kọ́
Iṣẹ́
Ìgbà iṣẹ́2011–present

Yvonne Anuli Orji (bíi ni ọjọ́ kejì oṣù kejìlá ọdún 1983) jẹ́ òṣèré ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti Amẹ́ríkà. Ó gbajúmọ̀ fún ipá tí ó kó nínú eré Insecure ní ọdún 2016, èyí tí ó jé kí wọn yàán fún àmì ẹ̀yẹ tí Primetime Emmy Award àti NAACP Image Awards.

Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Orji ni ọjọ́ kejì oṣù kejìlá ọdún 1983 sì ìlú Port Harcourt ni Ìpínlẹ̀ Rivers ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ó sì dàgbà sì ìlú Lauren ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà.[1] Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Linden Hall. Ó tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga tí George Washington University níbi tí ó tí gboyè nínú ìmò Liberal Arts. Ní ọdún 2009, ó lọ sí ìlú New York City láti ṣe iṣẹ́ aláwàdà.[2] Ní ọdún 2015, ó kó ipa Molly nínú eré Insecure.[3] Ní ọdún 2008, ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Population Services International fún oṣù mẹ́fà lórílẹ̀ èdè Liberia. Ó jẹ́ àmbásẹ́dọ̀ fún Jumpstart àti JetBlue.[4] Ní ọdún 2020, wọ́n yàán fún àmì ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bí Outstanding Supporting Actress in a Comedy Series láti ọ̀dọ̀ Primetime Emmy Awards fún ipa tí ó kó nínú eré Insecure.

Àṣàyàn àwọn eré tí ó tí ṣe[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọdún Àkọ́lé eré Ipa tí ó kó Àfíkún
2011 Love That Girl! Njideka Episode: "Head Shrunk"
2013 Sex (Therapy) with the Jones Moshinda Short film
2016–present Insecure Molly Carter 34 episodes
2017 Jane the Virgin Stacy 2 episodes
2017 Flip the Script Ad Exec 1 Episode: "Mad Woman"
2018 Night School Maya
2019 A Black Lady Sketch Show Flight attendant Episode: "Why Are Her Pies Wet, Lord?"
2020 Momma, I Made It![5] Herself HBO comedy special
2020 Spontaneous Agent Carla Rosetti
TBA Vacation Friends Post-production

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]