Zain Asher

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Zain Asher
Ọjọ́ìbíZain Ejiofor Asher
27 Oṣù Kẹjọ 1983 (1983-08-27) (ọmọ ọdún 40)
Balham, London Borough of Wandsworth, England
IbùgbéNew York City, New York, U.S.
Orílẹ̀-èdèBritish, Nigerian
Ẹ̀kọ́Keble College, Oxford University (BA)
Columbia University (MS)
Iṣẹ́Anchor, Journalist
Ìgbà iṣẹ́2006–present
Àwọn olùbátanChiwetel Ejiofor
(brother)

Zain Ejiofor Asher (bíi ni ọjọ́ kẹtàdínlógbon oṣù kẹjọ ọdún 1983) jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti Britain, ó jẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ fún CNN International ni ilẹ̀ New York City. Ó darapọ̀ mọ́ ilé iṣẹ́ CNN ni odun 2013.[1] Ó tún má ṣise fún Money Magazine.[2]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọn bíi ni Balham, London Borough of Wandsworth, England, àwọn òbí rẹ jẹ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Asher jẹ́ àbúrò sì Òṣeré Chiwetel Ejiofor.[3][4] Ó sì jẹ ọmọ ìlú Ezeagu ni ìpínlè Enugu ni ilẹ̀ Nàìjíríà. Ni ọdún 2005 Ashley lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga Keble College ni Oxford University níbi tí ó ti kọ èdè Spanish àti French.[5] Ní ọdún tí ó tẹ̀le, ó parí ẹ̀kọ́ rẹ ni ilé ẹ̀kọ́ gíga Columbia University ni ibi tí ó ti kọ nípa ìmò ìròyìn.[6]

Iṣẹ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

O darapọ̀ mọ́ ilé iṣẹ́ CNN ni oṣù kejì ọdún 2013. Kí ó tó darapọ̀ mọ́ CNN, ó ń sisé fún Money Magazine ni ibi tí ó ti kọ nípa ọrọ̀ owó fún wọn. Ó ti ṣíṣe fún New 12 Brooklyn gẹgẹ bí alaroye lórí telefiisionu.[7]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]