Jump to content

Zakariya Maimalari

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Zakariya Maimalari jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ológun ilẹ̀ Nàìjíríà tí ó dé ipò brigadier-general, tí wọ́n sì ṣekú pa á nínú ìdìtẹ̀gbàjọba ọdún 1966. Òun ni adárí pátá pátá fún ikọ̀ ológun 2nd Brigade, ti ìlú Àpápá, ní Ìpínlẹ̀ Èkó ní ọdún 1966.

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Maimalari ní Ìpínlẹ̀ Yobe, ó lọ síilé-ẹ̀kọ Barewa College, ní ìlú Zaria. Òun àti ọ̀rẹ́ ìgbà èwe rẹ̀, Lawan Umar dara pọ̀ mọ́ Royal West Africa Frontier Force ní ọdún 1950.[1] Látàrí kíkó ọ̀pọ̀ ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà sínú ipò ọ̀gá lẹ́nu iṣẹ́ ológu ilẹ̀ Nàìjíríà, ó lọ sílé ẹ̀kọ́ Regular Officers Training School, tí ó wà ní Teshie Ghana àti the Royal Military Academy, Sandhurst. Òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ Lawan ni wọ́n jọ lọ sí Sandhusrt, ṣùgbọ́n wọ́n lé Lawan ní tirẹ̀ kúrò lẹ́nu iṣẹ́ ológun. Láwan tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ológun tí wọ́n kọ́kọ́ fi sípò officer Corps of the Nigerian army. Ó tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ ní ibùdó ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ológun àti adarí ikọ̀ ọmọ ogun ilẹ̀ Nàìjíríà. [2]

Àwọn Ìtọ́ka sí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Poloma, Haruna (2014). "Who Was Brigadier Zakariya Maimalari? | Sahara Reporters". Sahara Reporters. 
  2. Siollun, Max (2009). Oil, politics and violence : Nigeria's military coup culture (1966-1976) ([Online-Ausg.]. ed.). New York: Algora Pub.. p. 22. ISBN 9780875867083.