Àwòrán
Àwòrán jẹ́ ìfirọ́pò ohun tí a lè f'ojú rí. Ó lé wá ní ọ̀nà méjì tàbí mẹ́ta tàbí kí á wò ó nínú ohun tí a fi ń wo àwòrán tí ó fi lè fún wa ní ìtumọ̀ àwòrán náà gan an. Àwòrán lè jẹmọ́ ohun ìṣẹ̀mbáyé tí a yá kalẹ̀ pẹ̀lú.[1]
Kò di dandan kí àwòrán ó fi gbogbo ara hànde kàá tó mọ̀ wípé àwòrán ni, àpẹẹrẹ irúfẹ́ àwòrán bẹ́ẹ̀ ni èyí tí ó wà níbí tí ó fi apá kan hàn nínú àwọ̀ rẹ̀ tí èyí sì fi gbogbo èyí tókù hàn. Bí àwòrán bá ní àwọ̀ funfun ati dúdú, síbẹ̀ àwòrán yí yóò sì sọ ohun tí ó bá jẹ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé a kò rí gbogbo ara rẹ̀ pátá.
Ojúkan ni àwòrán ma ń wà, bákan náà àwòrán ti ń lọ bọ̀ láyé òde òní.
Àbùdá àwòrán
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwòrán lé jẹ́ onígun méjì tàbí mẹ́ta tàbí kí á wò ó nínú ohun tí a fi ń wo àwòrán tí ó fi lè fún wa ní ìtumọ̀ àwòrán náà gan an. Àwòrán lè ní ojú ìwò tàbí mẹ́ta, gẹ́gẹ́ bí àwòrán tí a fi kámẹ́rà yà, àwọn lé jẹ́ onígun mẹ́ta bíi ère tàbí hólógíráámù. Wọ́n lè fi àwọn irinṣẹ́ bí kámẹ́rà, dígí tàbí Iwo gbe tí wọ́n fi ń wo àwọn kòkòrò àìfojúrí tí ojú lásán kò lè rí.
Àwọn itọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Chakravorty, Pragnan (September 2018). "What is a Signal? [Lecture Notes]". IEEE Signal Processing Magazine 35 (5): 175–77. Bibcode 2018ISPM...35e.175C. doi:10.1109/MSP.2018.2832195.