Jump to content

Ààfin

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ààfin ni ibùgbé àwọn ọba Gẹ́gẹ́ bí orikì tí ìwé atúmọ̀ èdè fún ààfin.[1]. Ipò ọba kì í ṣe ipò yẹpẹrẹ rárá fún ìdí èyí ibugbe wọn máa ń yàtọ̀ sí ti àwọn ará ìlú. Àárín ìlú ni ààfin máa ń sábà wà.

Ààfin ìlú Benin.

Ààfin ọba Benin jẹ́ ọkan lára àwọn ààfin ilẹ̀ Yorùbá. inú ààfin yìí ni ọba àti àwọn ebí rẹ̀ má ń gbé[2][3]. Ọba Ewedo ni ó kọ́ ààfin yìí ní ọdún (1255AD – 1280AD). Àárin ìlú Benin ni ó kọ́ ààfin yìí sí. Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní ilé ọba tójó, ẹwà ló bù si. Ní ọdún (1914-1932) ní Ọba Eweka II tún ààfin Benin kọ́ lẹ́yìn tí wọ́n bà á jẹ́ nínú ogun tó ṣẹlẹ̀ láàárín wọ́n àti àwọn òyìnbó ní ọdún1897 war with the British. Ní ọdún 1999 ni ààfin náà wà lára àwọn nǹkan ọ̀ní tí ó wà ní abẹ́ UNESCO Listed Heritage Site

Ààfin ọba Èkó.

Ààfin ọba Èkó náà ni a mọ̀ sí Ìgà Ìdúngánràn. Láti sẹ́ntúrì márùndínlógún (15th) ní ìgà Ìdúgánràn ti jẹ́ ilé fún ọba tóbá jẹ ní Èkó tí wọ́n ń pè ní Elékòó. Àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ gbé ní erékùsù Èkó ni wọ́n ní ìgà yìí. ìtumọ̀ Ìgà Ìdúngánràn ní Ààfin tí wọ́n kọ́ sí oko ata. [4]

Ọdún 1670 ní wọ́n kọ́ ààfin yìí fún ọba Gabaro. Tafawa Balewa tó jẹ́ mínísítà Nàìjíríà fún gbà kan rí tún ààfin náà ṣe ní ọdún 1960 ọjọ́ kìnní, oṣù Ọ̀wàwà.


Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Definition of PALACE". Merriam-Webster. 2022-04-22. Retrieved 2022-05-08. 
  2. Nathaniel, Soonest. "CORONATION: EXPOSED! 9 things you must never do in Oba of Benin palace (Photos)" (in en-US). Naij.com - Nigeria news.. https://www.naij.com/1015633-coronation-exposed-9-things-you-must-never-do-in-oba-of-benin-palace-photos.html. 
  3. "The Royal Palace of the Oba of Benin". ZODML. Archived from the original on 2016-12-17. https://web.archive.org/web/20161217160019/http://zodml.org/content/royal-palace-oba-benin. 
  4. "Oba of Lagos Palace – Iga Idaguran – Isale Eko". Isale Eko – Descendants Union. 1960-10-01. Archived from the original on 2022-07-01. Retrieved 2022-05-17.