Orlando Owoh

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Orlando Owoh
Owoh.jpg
Background information
Orúkọ àbísọStephen Oládipúpò Olaore Owomoyela
Irú orinKennery Highlife
juju
Occupation(s)Olorin
Onigita

Orlando Owoh (oruko abiso: Stephen Oládipúpò Olaore Owomoyela[1], February 14, 1932 - November 4, 2008[2]) jé olorin omo ile Naijiria. Omo ìlú Ifón lébàá òwò ní Ìpínlẹ̀ Òndó ni.

Ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó lo sí ilé ìwé alákòóbèrè ti Ìjo Elétò ni ìlú Osogbo ní odún 1951 (Decca 1969).

Akínmúwàgún (2001:1-3) sàlàyé pé Orlando jáde ní ilé ìwé alákòóbèrè ó sì ń fi ojú sí eré àsíkò àti gbénàgbénà ti bàbá rè ń se. Ó darapò mó egbé omo ogun Nàìjíríà ní odún 1960, sùgbón kò lò ju odún kan péré tó fi kúro tó sì darapò mó egbé orí ìtàgé kan tí a mò sí Ògúnmólá National Concert Party’. Kò pé púpò ti òun pàápàá fi dá eré tirè sílè tí ó sì pé è ni Orlando Owoh And His Omimah Band’.

Odún 1969 ni Orlando gbé ìyàwó. Léyìn ìgbeyàwó àkókó, ó ti fé ìyàwó mérin mìíràn. Orúko àwon ìyàwó rè láti orí ìyàwó àkókó ni Múìbátù Orímipé, Folásadé Àkísan, Mopélólá Ìsòlá, Deborah Akérédolú ati ìyábò Ańjoórìn. Lára awon omo rè ni Káyòdé, Abósèdé, Ségún, Dàpò àti Sèsan. (Akinmuwagun 2001:1-3). Ìwádìí fi hàn pé ó tilè bi òkan nínú àwon omo rè tí ń je Tòkunbò si ìlú Oba, a gbó wí pé isé èsé kíkàn ni òdómokùnrin òhún ń se.

Nínú àlàyé Tádé Mákindé (2004:30) ó hàn gbangba pé Tòkunbò omo Orlando jogún èsè kíkàn ni. Ó sàlàyé pé Orlando féràn èsé kíkàn àti pé odidi odún meta ni ó fi je baálè àwon elésèé kíkàn nígbà èwe rè. Ó ní òré ni àbúrò òun àti gbajúgbajà olorin tí ń jé Sunny Ade.

Alákíkanjú ni Orlando, nípa akitiyan rè ni a dá Egbé Ìtèsíwájú Ìlú Ifón sílè (Ifón Progressive Union) ní odún 1970. Léyìn to seré ní ìlú Òwò ní odún 1973 ni wón se ètò ífilólè láti kó gbòngàn (Town Hall). (Àkínmúwàgún 2001:1-3).

Nínú ìfòròwánilénuwò tí Tádé Mákindé se, àwon òtító kan jeyo: Ekíní ni pé àìsàn rolápá-rolésè bá a jà, Olórun ló yo ó. Owó òtún re kò sì se é gbé gìtá dáradára mó. Bí ó tilè jé pé ó lè fi owò òtún òhún bo èníyàn lówó tàbí fi gbé omodé, kò se é mú síbí ìjeun dáradára. Gégé bi àlàyé Orlando:

Se ni yó máa gbon rìrì tí ó bá ti kù díè kí ó dé enu Àìsàn yìí kò mu ohùn re lo rárá èyí ni kò sì jé kí akùdé ba eré olósoosù tí ó máa ń se ni ilé ìtura Màjéńtà to wà ní Idimu Egbédá ní Èkó.

Nínú ìfòròwánilénuwò yìí, Orlando ní òún ti di omoléyìn kírísítì, ó sì fi gbogbo ògo fún Olórun. Ó ní: Èmi kì yóò kú bí kò se yíyè láti so nípa dídára Olúwa O mò pé mo sí ni nnkan se ní ilé ayé.

Nígbà tí wón bi í nípa ohun tí àwon olólùfe re ń so kirì pé bí gbajúgbajà olórin àgbàyé – Michael Jackson ba kojú Orlando Owoh nínú eré síse ni Òwò yàtò si ìlú bí i Eko, Abuja tabi Port Harcourt, Orlando ni yóò borí, èsì rè ni pé, Nítorí èka èdè Òwò enu mi àti síse kòkáárí àsà Òwò ni” (Makinde 2001:30).

Kí ló tún kù o? Orlando fara mó Òwò ati àsà òwò títí ti àwon ènìyàn kan fi yí owó inú Owóméyèlá rè sí Òwò, ó ko ó lórin pé déédéé ara òun ni orúko méjééjì se. Wón fi oyè amúlùúdún dá Orlando lólá ni ìlú Ifón. Nígbà tí ó lo sere ní ìlú Tokyo tó wà ni Ilè Japan ní odún 1986, ìjoba fi Oyè gbédègbéyò (Commander of Language) dá a lólá.

Pàtàkì ìsoro tó dojúko yàtò fún ti àìsàn tó ko lú ú ni èwòn tó lo ni odún 1985 látàrí pé ó ń se agbódegbà fún igbó títà.

Ní báyìí Orlando ti pé odún mókànlélógóta ó lé díè, ó sì ti se rékóòdù márùn-dín-lógójì.

Ìwádìí fi hàn pé Orlando fé ni ibùjókòó ní Ilú òyìnbó àti láti dá Ilé-èkósé eré sílè bí Olórun bá yònda (Akínmúwàgún 2001:1-3). Ó sàlàyé pé òun fé kí àwon orin tí óun ti ko di kíká sórí fóńrán fídíò. Ó ní òun ti parí ètò pèlú Ilé ise `Gazola Nig. Ltd’ láti sètò títa àwon Isé òun sí orí CD pèlú títà rè (Makinde 2004:30).

Ní gbogbo ònà, ó hàn gbangba pé Orlando ti di àgbà òjè nínú olórin, kì í se ní àdúgbò ìlú Òwò tàbí ile Yorùbá nikan bí kò se ni gbogbo Nàìjíríà (Uzo 2004:14).

Nínú orin tí ó pe àkolé rè ní `Ifón Omimah’, ó sàlàyé pé omo ilu Òwò ni ìyá òun. Nínú orin tí ó ko fún Gbenga Adébóyè, ó jé kí á mò pé òun sì ni ìyá láye nítorí pé ó ni òun ti bá Gbénga Adébóyè sòrò pé yóò bá òun sin ìyá oun lójó tí ó bá relé ogbó.


Àwọn ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Orlando Owoh - Igbesiaye ati igba re ninu iwe iroyin Guardian ti Naijiria 15/4/2006
  2. Orlando Owoh je alaisi ni ojo-ori odun 76 ninu iwe iroyin The Nation 6/11/2008

Ijapo lode[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]