Òkè-Ìmẹ̀sí

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ìlú Òkè-Ìmẹ̀sí jẹ́ ìlú kan lára awọn ìlú tí ó korajọ pọ̀ di ìjọba ìbílẹ̀ Ìwọ Oòrùn Èkìtì LGAÌpínlẹ̀ Èkìtì.[1] [2][3][4] Wọ́n fi léde wípé iye àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ olùgbé ìlú náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n( 30,000).

Bí ó ṣe tó[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìlú Òké-Ìmẹ̀sí wa ní Ìpínlẹ̀ Èkìtì ní apá ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà. Òké-Ìmẹ̀sí tó 7.82° ìbú ní apá Gúsù nígbat tí ó tó 4.92° òró ní apá Àríwá tí ó sì tó 541 fífẹ́ ní iye. Coordinates: 7°49′0″N 4°55′0″E / 7.81667°N 4.91667°E / 7.81667; 4.91667 Ìkóró-Èkìtì àti Ìjerò-Èkìtì ni ó pààlà pẹ́lú Òké-Ìmẹ̀sí ní apá àríwá nígbàtí òun àti Ẹfọ̀n Alààyè pààlà ní apá ìwọ̀ Oòrùn, ní apá Gúsù ni Ìmẹ̀sí-Ilé wà sí Òké-Ìmẹ̀sí, tí ìlú Òké-Ìmẹ̀sí sì pààlà pẹ̀lú àwọn ìlú bíi: Ẹ̀sà-Òkè àti Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.[5] Bí ìlú náà ṣe ní òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ó jẹ́ kí ó dùn ún wò ati láti lọ síbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àyè ìgbafẹ́. Bákan náà ni ọyẹ́ tí ó ma ń mú níbẹ̀ ní àsìkò ọyẹ́ ma ń tutù mọ́ni fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ ni. Àwọn ilẹ̀ ibẹ̀ gbogbo ni ó jẹ́ ilẹ̀ ọlọ́ràá fún nkan ọ̀gbìn, bákan náà ni àwọn ohun alùmónì oríṣiríṣi sòódó síbẹ̀.


Ìtàn ìlú Òké-Ìmẹ̀sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ wípé gbogbo ọmọ káàrọ-oò-jíire ni wọ́n ṣẹ̀ wá láti Ilé-Ifẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orírun baba-ńla wọn, bá kan náà ni ti ìlú Òké-Ìmẹ̀sí rí. Mọ̀lẹ́bí àti ìbátan kan náà ni Ìlú Òkè-Ìmẹ̀sí, Ìmẹ̀sí-Ilé àti Ilé-Ifẹ̀. Ọba àti aláṣẹ pátápátá ti ìlú Òkèmẹ̀sí ni wọ́n ń pè ní Ọwá Oòyè ti ìlú 'Òké-Ìmẹ̀sí'. Orúkọ ọba tí ó wà ní orí àpèrè àṣẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ ni Ọba Gbádébọ̀ Adédèjì


Àwọn lààmì-laaka ènìyàn láti ìlú Òké-Ìmẹ̀sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Agan, Okemesi Ilu (2014-10-16). "Welcome to Okemesi!". okemesi Ilu Agan. Archived from the original on 2021-01-24. Retrieved 2020-12-21. 
  2. "Ekiti: A rocky state and its untapped potentials". Sun News. September 11, 2014. http://sunnewsonline.com/new/?p=81261. 
  3. "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2012-07-24. Retrieved 2020-12-21. 
  4. http://www.maplandia.com/niger/ekitiwest/oke-mesi/
  5. http://projectmaterials2015.blogspot.com.ng/2015/08/the-role-of-fabunmi-of-okemesi-ekiti-in.html

Àdàkọ:Ekiti-geo-stub