Bolaji Ogunmola

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Bolaji Ogunmola
Ọjọ́ìbíBolaji Ogunmola
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Ilorin
National Open University of Nigeria
Royal Arts Academy
Iṣẹ́Oṣere
Ìgbà iṣẹ́[ 2013]

Bọ́lájí Ògúnmọ́lá jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ògúnmọ́lá ní ètò ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní Philomena Nursery and Primary School, Èbúté Métta, ṣááju kí ó tó lọ sí ìlú Ìbàdàn fún ètò ẹ̀kọ́ mẹ́wàá rẹ̀. Ó kẹ́ẹ̀kọ́ Ìṣàkóso Ìṣòwò ní National Open University of Nigeria.[1] Ògúnmọ́lá tún jẹ́ àkẹ́ẹ̀kọ́-gboyè ní ilé-ẹ̀kọ́ Yunifásitì ti Ìlorin. Ó kọ́ ẹ̀kọ́ eré ìtàgé ṣíṣe gẹ́gẹ́ bi akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ní Royal Arts Academy.[2] Nígbà kan tí ó n sọ̀rọ̀ fún ilé-iṣẹ́ oníròyìn Vanguard lóri níní ẹni tí òun pẹ̀lu rẹ̀ dì jọ n ṣe wọléwọ̀de, Ògúnmọ́lá ṣàlàyé wípé, òun kò ní bẹ́ẹ̀ òun kò wá. Ó wípé ọ̀nà àti ṣiṣẹ́ owó ni òun gbájúmọ́. Ó tún ṣàlàyé pé owó jẹ́ èròjà pàtàkì nínu èyíkèyí wọléwọ̀de tó yanrí.[3] Nínu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan ti ọdún 2016, ó sọ di mímọ̀ wípé bótilẹ̀jẹ́pé òún ní ìfẹ́ sí àwọn ọkùnrin tí ó bá mọ́ láwọ̀, òun kò fọwọ́sí bíbóra.[4]

Iṣẹ́ ìṣe[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ògúnmọ́lá jẹ́ olùkópa níbi ètò ìfihàn Next Movie Star ti ọdún 2013.[5] Ipa rẹ̀ nínu eré Okon goes to School jẹ́ ìtọ́kasí gẹ́gẹ́ bi fíìmù àkọ́kọ́ tí ó ti hàn.

Fún ipa rẹ̀ nínu Sobi's Mystic, ó wọ àtòkọ Newsguru.com bi ọ̀kan nínu àwọn máàrún òṣèré Nollywood tí yóó gòkè àgbà lọ́jọwájú.[6] Nínu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú The Punch, ó ṣe àpèjúwe ipa méjì rẹ̀ tí ó kó nínu fíìmù náà gẹ́gẹ́ bi Aida/Mystic bi ìpèníjà tí ó ga jùlọ nínu iṣẹ́ rẹ̀. Ó tún ṣe ìkéde Bíọ́dún Stephen, Mo Ábúdù àti Oprah Winfrey gẹ́gẹ́bi àwọn àwòkọ́ṣe rẹ̀ nídi ṣíṣe fíìmù.[7]

Ó ní àwọn yíyàn méjì níbi ayẹyẹ City People Movie Awards ti ọdún 2018.[8]

Àṣàyàn eré rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]