Esther Ajayi

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Esther Ajayi
Ọjọ́ìbíOṣù Kẹrin 2, 1963 (1963-04-02) (ọmọ ọdún 61)
Nàìjíríà
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Iṣẹ́Wòólì-bìnrin,Olùdásílẹ̀ ìjọ, onínúure-tí-ń-ta-o-ọ̀pọ̀-ènìyàn-lọ́rẹ
Olólùfẹ́Ẹni-ọ̀wọ̀ (Dr.) Ademuyiwa Amuwaoluwa Ajayi
Àwọn ọmọmẹ́rin

Esther Ajayi tí a tún mọ̀ sí Ìyá Àdúrà, orúkọ rẹ̀ ní kíkún ni Esther Abimbola Ajayi( wọ́n bi ní ọjọ́ kejì oṣù kẹrin, ọdún 1963). Esther jẹ́ wòólì-bìnrin tilẹ̀ Nàìjíríà, onínúúre-tí-ń-ta-ọ̀pọ̀-ènìyàn-lọ́ọrẹ, olùsọ́àgùtàn, eni ọ̀wọ̀, olùdásílẹ̀ àti olùdarí gbogbogbò ìjọ Cathedral of Love of Christ Generation Church C&S.

Esther Abimbola Ajayi jẹ́ olùsọàgùntàn àti wòólì ìjọ aláṣọ funfun. Òun náà ni ó paalà tó wà láàárin ìjọ aláṣọ funfun ńlá méjì tí ó wà ní orílèdè Nàìjíríà, ìyẹn Cherubim and Seraphim(C&S), àti Celestial church of Christ(CCC).[1]

Ìbẹ̀rẹ̀ Ayé Esther Ajayi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

ilé onígbàgbọ́ ni wọ́n bí Esther sí, ọmọ Èkó-Nàìjíríà, ni ó jẹ́. Ó se ni láàánú pé ìyá rẹ̀ ti ṣe aláìsí, bàbá rẹ̀ jẹ́ òṣìsẹ́ ìjọba tí ó ti fẹ̀yìn tì ní ìsìyín, tí ò sì tún ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àjọ tó ń mójútó ìṣe òkèrè.[2]

Esther Ajayi ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwò, ìyẹn òwò lóríṣiríṣi, tí ó sì jẹ́ wí pé ó tayọ nípa òwò ṣíse, tí o fi jẹ́ pé àwọn ohun tó ti ń dùn, ò wá dùn mọ́. Ni ó fi fura wí pé ìpè Olúwa tí ó ti ń kan ilẹ̀kùn rẹ̀, ti padà wọlé.[3]

Ìrìnàjò Esther sí Ìpè Olúwa[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Kí ó tó di pé Esther di wòólì tàbí ìránṣẹ́ Ọlọ́run rárá ni ó tí rí àwọn ìran, Olúwa ta á lọ́rẹ àlá àti ìran rírí. Níṣe ni ó má ríran bí i ń pé ojú ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán ni ó tí ń ri. Ó máa ń ri pé òun ma ní bíbélì ńlá àti agogo, àti pé òun máa ń tú àwọn èyàn nínú ìdè àwọn ọ̀tá.

Òmíràn lárá àwọn ohun mìíràn tí ó fi gbọ́ ìpè Olúwa ni pé, àwọn adigunjalè wá sí ilé rẹ̀, wọ́n kó wọn lẹ́rù, wọ́n sì yìn ìbọn kiri, tí ó jẹ́ pé ó wọ yàrá àwọn ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n nǹkan kan ò ṣe àwọn omọ náà, tí àwọn olè náà aì dá gbogbo ohun tí wọ́n kó lọ padà.

Àwon adigunjalè tún wá ní ọjọ́ òmíràn, tí wọ́n pa aṣọ́lé rẹ̀, tí ó sì ku díẹ̀ tí wọ́n ma fi pa ọko rẹ̀. Èyí bà á lẹ́rù gidi gan tí ó wò pé tí kò bá gbọ́ ìpè yìí, ohun tó burú ṣì ma ṣẹlè sí òun àti mọ̀lẹ́bí rẹ̀. Ni ó wá bẹ̀rẹ̀ ìwàásù ọ̀rọ̀ Olúwa kiri gbogbo àdúgbò látì ìgbà náà.

Ọdún 1993, ni Esther fi ayé rẹ̀ fún Jésù ní Faith Bible College-Sango Otta, Ìpínlẹ̀ Ògùn.

Ní ọdún 2007, Ajayi dá ìjọ àkọ́kọ́ rè sílẹ̀, Love of Christ Generation Church C&S, ní Lọndọnu, ní 2015, ó tún kó lọ sí agbègbè tó sunwọ̀ ju ibi àkọ́kọ́ lọ-Clapham, Lọndọnu. Ní oṣù kẹsán-án ọdún 2021, ó tún ṣí òmíràn sí Victoria Island, Lagos, Nàìjíríà.[4]

Àwọn Bàbá Inú Olúwa Esther[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Olùṣọ́àgùntàn Enoch Adejare Adeboye àti aya rẹ̀ Foluke Adeboye, ti ìjọ Redeemed Christian Church of God, àti àlùfáà àgbà David Oyedepo, ti ìjọ Living Faith Church Worldwide, ni bàbá Esther Ajayi nínú Olúwa.[5][6]

Àwọn Ìtọkasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Naija, TheFamous (2021-09-20). "Esther Ajayi Biography, Husband, Children, Net Worth, House Cars, Jet". TheFamousNaija. Retrieved 2022-05-24. 
  2. Naija, TheFamous (2021-09-20). "Esther Ajayi Biography, Husband, Children, Net Worth, House Cars, Jet". TheFamousNaija. Retrieved 2022-05-24. 
  3. Naija, TheFamous (2021-09-20). "Esther Ajayi Biography, Husband, Children, Net Worth, House Cars, Jet". TheFamousNaija. Retrieved 2022-05-24. 
  4. Naija, TheFamous (2021-09-20). "Esther Ajayi Biography, Husband, Children, Net Worth, House Cars, Jet". TheFamousNaija. Retrieved 2022-05-24. 
  5. Naija, TheFamous (2021-09-20). "Esther Ajayi Biography, Husband, Children, Net Worth, House Cars, Jet". TheFamousNaija. Retrieved 2022-05-24. 
  6. "esther ajayi - Search". Bing. 2020-08-03. Retrieved 2022-05-24.