Esther Oyema

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Esther Oyema
Òrọ̀ ẹni
Ọmọorílẹ̀-èdèNigerian
Ọjọ́ìbí20 Oṣù Kẹrin 1982 (1982-04-20) (ọmọ ọdún 42)
Weight48 kg (106 lb)
Sport
Erẹ́ìdárayáPowerlifting
Updated on 20 January 2023.

Esther Oyema (tí wọ́n bí ní 20 April 1982) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti eléré-ìdárayá tó máá ń gbé nǹkan tó wúwo.[1]

Oyema parí ìdíje ti ayẹyẹ 61 kg fún àọn obìnrin ní 2014 Commonwealth Games,[2] ibẹ̀ sì ni wọ́n ti fún ní àmì-ẹ̀yẹ oníwúrà fún títayọ rẹ̀ nínú eré-ìdárayá náà fún gbígbé ohun tó tó ìwọ̀n 122.4 kg.[3] Ní ọdún 2015, ó gba àmì-ẹ̀yẹ oníwúrà ní All-Africa Games, nípa gbígbé ohun tó tó ìwọ̀n 133 kg, èyí tó ju àṣẹyọrí rẹ̀ nígbà kan rí tó gbé 126 kg.[4] Ní ọdún kan náà, ó rin ìrìn-àjò lọ sí ìlú Almaty, Kazakhstan níbi tó ti gba àmì-ẹ̀yẹ oníwúrà mìíràn ní IPC Powerlifting Asian Open Championships fún gbígbé ìwọ̀n tó tó 79 kg.[5] Lásìkò 2016 Summer Paralympics, ó gba àmì-ẹ̀yẹ onífàdá́kà nígbà tó díje dupò pẹ̀lú Amalia Perez ní women's 55 kg, tó sì borí.[6] Ó gba àmì-ẹ̀yẹ oníwúrà, ó sì fi àkọsílẹ̀ tuntun lélẹ̀ nígbà tó gbé 131 kg ní ayẹyẹ women's lightweight event ní 2018 Commonwealth games.[7]

Ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù karùn-ún, ọdún 2020, International Paralympic Committee (IPC) dá a dúró fún kíkópa nínú ìdíje fún ọdún márùn-ún lẹ́yìn tó fìdí rẹmi nínú ìdánwò kan. Ó parí ìdíje ti ọdún 2019 International Paralympic tí ó wáyé ní Oriental Hotel, ní Victoria IslandEko, níbi tí ó ti gba àmì-ẹ̀yẹ oníwúrà mìíràn, àmọ́ wọ́n gbadà gbà á. Wọ́n gba ìtọ̀ rẹ̀ láti fi ṣe àyẹ̀wò, wọ́n sì ri pé ó ní àrùn19-norandrosterone.[8]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Glasgow 2014 profile". Retrieved 10 October 2014. 
  2. "Preview: Glasgow 2014 Commonwealth Games powerlifting competition". www.paralympic.org. 20 July 2014. https://www.paralympic.org/news/preview-glasgow-2014-commonwealth-games-powerlifting-competition. Retrieved 29 March 2018. 
  3. "Team Nigeria Para-power lifters set new world records at Commonwealth Games". Vanguard. 2 August 2014. http://www.vanguardngr.com/2014/08/team-nigeria-para-power-lifters-set-new-world-records-commonwealth-games/. Retrieved 29 March 2018. 
  4. "Another Nigerian powerlifter, Esther Onyema breaks world record". Vanguagrd. 16 September 2015. https://www.vanguardngr.com/2015/09/another-nigerian-powerlifter-esther-onyema-breaks-world-record/. Retrieved 29 March 2018. 
  5. Valentine Chinyem (31 July 2015). "Nigerian Weight Lifters Break World Record in Asia". News of Nigeria. Archived from the original on 30 March 2018. https://web.archive.org/web/20180330083437/http://newsofnigeria.com/nigerian-weight-lifters-break-world-record-in-asia/. Retrieved 29 March 2018. 
  6. Christopher Maduewesi (12 September 2016). "Esther Onyema wins Silver for Team Nigeria at Rio Paralympics". Making if Champs. https://www.makingofchamps.com/2016/09/10/esther-onyema-wins-silver-team-nigeria-rio-paralympics/. Retrieved 29 March 2018. 
  7. "Esther Oyema". results.gc2018.com. Retrieved 20 January 2023. 
  8. "Esther Oyema receives a four-year ban for anti-doping rule violation". International Paralympic Committee (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-06-28.