Gulder Ultimate Search

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Gulder Ultimate Search
GenreReality
Presented byChidi Mokeme, Bob-Manuel Udokwu, Toke Makinwa
Country of originNigeria
Original language(s)English
Production
Executive producer(s)Oluseyi Siwoku. Nigerian Breweries Plc
Producer(s)Olakunle Oyeneye
Running time56 minutes
Production company(s)Jungle Fireworks
Release
Original networkDSTV, GOTV
Original release2004 (2004) – 2021 (2021)

Gulder Ultimate Search (tí wọ́n tún máa ń pè ní GUS)[1] jẹ́ ètò orí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán kan tí wọ́n máa ń ṣàfihàn ní oeílẹ̀-èdè Nàìjíríà, èyí tí ilé-iṣẹ́ Nigerian Breweries Plc ṣ ìdásílẹ̀ rẹ̀, tí wọ́n sì tún ṣagbátẹrù rẹ̀, láti ṣe ìgbélárugẹ Gulder Lager Beer.[2] Ètò àkọ́kọ́ náà wáyé ní ọdún 2004.[3] Ètò GUS yìí jẹ́ ètò àkọ́kọ́ ti orílẹ̀-èdẹ̀ Nàìjíríà tó dá lórí ìtirakà àwọn olùdíje tó tó bí i mẹ́wàá sí ọgbọ̀n láti yè. Ìtiraka yìí máa ń jẹ́ èyító le gan-an, níbi tíwọ́n á ti ní kí wọ́n ṣàwárí ìṣura àfimapọ́ kan, tí ẹni tó bá gbẹ̀yìn nínú ìdíje náà á gba ẹ̀bùn. Olùborí ìdíje ti ọdún 2014 gba 10 million naira àti ọkọ̀ SUV.[4]

Lẹ́yìn ọdún mehe tí wọn ò ṣe ètò náà lórí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán, Gulder Ultimate Search bẹ̀rẹ̀ ètò náà padà ní ọdún 2021.[5]

Àwọn àṣesẹ́yìn, ibùdó ètò, ìtàn tó rọ̀ mọn àti àwọn agbégbá-orókè[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Aṣagbátẹrù ètò yìí jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olakunle Oyeneye, aṣàgbéjáde náà sì jẹ́ Oluseyi Siwoku, ti Jungle Filmworks.[6]

GUS 1[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n ṣe GUS 1 ní Snake Island, ní Ìpínlẹ̀ Èkó. Àkọ́lé náà jẹ́ 'The Legend of Captain Kush', arákùnrin Ezeugo Egwuagwu sì ni agbégbá-orókè àọ́kọ́ ètò náà, tó gba ẹ̀bùn 3 Million Naira.

GUS 2[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Obudu Hills, ní Calabar, ní Ìpínlẹ̀ Cross River ni ìbùdó tí wọ́n ti ṣe apá kejì ètò yìí. Àkọ́lé rẹ̀ ni 'The Lost Helmet of General Maxmllian', arákùnrin Lucan Chambliss sì ni agbégba-orókè, tó gba ẹ̀bùn 5 Million Naira.

GUS 3[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

NIFOR, ní ìlú Benin ní Ipinle Edo ni agbègbè tí wọ́n ti ṣe apá kẹta ètò yìí. Àkọ́lé náà sì jẹ́ 'The Brew Master's Secret', arákùnrin Hector Joberteh ló gbégbá orókè, tó sìgba ẹ̀bùn 5 Million Naira àti ọkọ̀ Ford Explorer SUV. Arákùnrin yìí padà di òṣèré, àmọ́ wọ́n yìnbọn pa á ní ibùgbé rẹ̀, ní ìpínlẹ̀ Èkó ní ọjọ́ 3 September 2017.[7]

GUS 4[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

The Shere Hills ní ìlú Jos ni agbègbè tí wọ́n ti ṣe apá kẹrin ètò yìí, tí àkọ́lé náà sì jẹ́ 'The Search for the Golden Age'. Arákùnrin Dominic Mudabai sì ló tayọ̀ jù láàárín àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀, òun sì ló gba ẹ̀bùn ọdún náà.

Ikú olùdíje kan[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Olùdíje kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Anthony Ogadje, kú sínú odò ní ìlú Jos, ní Ìpínlẹ̀ Plateau lásìkò apá kẹrin ìdíje náà.[8]

GUS 5[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Láàárín òkè tó kún fún ìjì ní MmakuAwgu, ní Ipinle Enugu ni wọ́n ti ṣe apá karun-ún ètò yìí. Arákùnrin Michael Nwachukwu ló ṣàwárí ohun ìṣura náà, tó sì fi gba 5 million naira àti ọkọ̀ SUV tuntun.

GUS 6[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n gbé ètò GUS 6 lọ sí apá Ìwọ̀-oòrun ilẹ̀ Nàìjíríà, ìyẹn ní igbó Omodo ti Aagba ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, àkọ́lé ti ọdún náà sì jẹ́ 'The Horn of Valour'. Arákùnrin Uche Nwaezeapu ló gbégbá orókè.

Ètò náà fún àwọn gbajúmọ̀ òṣèré[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìpètò náà fún àwọn gbajúmọ̀ òṣèré wáyé ní ọdún 2010, La Campaigne Tropicana ní Epe, ní Ìpínlẹ̀ Èkó ni agbègbè tí wọ́n lò. Àkọ́lé ètò náà ni 'The Golden Goblet', òṣèrékùnrin Emeka Ike sì ni agbégbá-orókè ti ọdún náà, tó sì lọ ilé pẹ̀lú seven million naira.

GUS 7[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọdún kan náà tí wọ́n ṣe ìpètò fún àọn gbajúmọl òṣèré, wọ́n gbé ètò náà lọ sí igbó Omo ní Ìpínlẹ̀ Ògùn. Èyí sì ni apá keje ètò náà, agbégbá-orókè náà jẹ́ arákùnrin Oyekunle Oluwaremi.

GUS 8[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Kukuruku Hills, tó wà ní Egbetua Quarters ní Ososo, ní agbègbè Akoko-Edo, ní Ipinle Edo ni wọ́n ti ṣe apá kẹjọ ètò náà. Àkọ́lé ìdíje ọdún náà jẹ́ 'The Contest of Champions', níbi tí awọn agbégbá-orókè pẹ́jọ pọ̀ láti díje pọ̀. Arákùnrin Chris Okagbue ló sì gbégbá orókè.

GUS 9[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọdún 2012 ni ọdún tí ètò yìí lọ sí Usaka, Obot Akara, ní ipinle Akwa Ibom. Àkọ́lé ti ọdún náà jẹ́ 'The Gatekeeper's Fortune', arákùnrin Paschal Eronmose Ojezele sì ni agbégbá- orókè. Laszlo Bene tó jẹ́ olùdarí àti aṣagbátẹrù fìímù ni olùdarí ètò yìí fún ọdún náà. Olùdarí yìí jẹ́ ọmọ ilẹ̀ America, àmọ́ South Africa ló ń gbé lọ́wọ́lọ́wọ́.

GUS 10[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nínú igbó Usaka ní Akwa Ibom, ni arákùnrin Dennis Okike ṣàwárí ìṣùrà náà, tó sì fi gba 10 million naira àti ọkọ̀ Mitsubishi Pajero tuntun. Laszlo Bene ló jẹ́ olùdarí ètò yìí fún ọdún náà. Ìlú South Africa ló ń gbé lọ́wọ́lọ́wọ́.

GUS 11[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ètò GUS 11 wáyé nínú igbó Aguleri ní Ipinle Anambra, níbi ti arákùnrin Chinedu Ubachukwu ṣàwárí akoto ọ̀gágun. Ó gba ẹ̀bùn 10 million naira àti ọkọ Ford Explorer tuntun.

Apá ìdíje tuntun[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

GUS 12: The Age of Craftmanship[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Gulder Ultimate search padà wá sí orí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán lẹ́yìn ọdún méje, láti ìgbà tí wọ́n ti ṣe é ní ọdún 2014.[9] Apá ìdíje tuntun náà bẹ̀rẹ̀ ní October 16, 2021, títí wọ December 19, 2021. Wọ́n máa ń ṣàfihàn rẹ̀ ní ọjọ́ Àbámẹ́ta (Saturday) àti ọjọ́ Àìkú (Sunday) láti ago mẹ́jọ alẹ́ (8pm) wọ ago mẹ́sàn-án alẹ́ (9pm).[10]

Wọ́n ṣe àfihàn olùdíje méjìdínlógún (18) fún apá kejìlá ètò náà. Lára àwọn olùdíje náà ni Damola Johnson, tó jẹ́ ọmọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26 year-old) tó sì jẹ́ olùdarí eré, lá ti ìpínlẹ̀ Èkó, Mfon Mikel Esin, tó jẹ́ ọmọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27year-old) tó jẹ́ òǹkọ̀wé láti Akwa Ibom, Samuel Ishmael, tó jẹ́ ọmọdún márùndínlógójì (35 year old) tó jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ onímọ̀-ẹ̀rọ láti ìpínlẹ̀ Ògùn, Emmanuel Nnebe, tó jẹ́ ọmọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29 year old) láti Anambra, Damilola Odedina, tó jẹ́ ọmọdún márùndíndínlọ́gbọ̀n (25 year old) tó jé ayafọ́nrán, Solomon Yankari, Olayinka Omoya, Godswill Oboh, Omokhafe Bello, Chidimma Okeibe, Jennifer Okorie, Tobechukwu Okoye, Gerald Odeka, Tosin Michael Emiola, Iniabasi Umoren.[11]

Odudu Otu ni ó gbégbá-orókè, lẹ́yìn tí ó ṣàwárí àpótí Akolo ní ọjọ́ àṣekágbá, lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìfìgagbága pẹ̀lú àwọn olùdíje yòókù. Wọ́n fún ní àwọn ẹ̀bùn tó tó bí i N50 million pẹ̀lú kọ́kọ́rọ́ sí ọkọ̀ SUV láti ọwọ́ Innoson Motors àti ìwé láti lọ rín ìrìn-àjò lọ sí Dubai.[12][13][14][15]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Gulder Ultimate Search". www.gulderultimatesearch.ng. Retrieved 2022-12-21. 
  2. Okeke, Ifeoma (2021-09-27). "Air Peace becomes sponsor of 12th Gulder Ultimate Search". Businessday NG (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-12-21. 
  3. Augoye, Jayne (2021-09-02). "Gulder Ultimate Search returns after seven-year-hiatus". Premium Times Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-12-21. 
  4. Abimboye, Micheal (2014-10-31). "Chinedu Ubachukwu Wins Gulder Ultimate Search Season 11". Premium Times Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-12-21. 
  5. Nwafor (2021-10-16). "As BBNaija ends, Gulder Ultimate Search returns to DStv". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-12-21. 
  6. ".:: Welcome to Jungle Film Works official Website ::". Archived from the original on 11 June 2013. Retrieved 4 June 2013.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  7. "How Gulder Ultimate Search winner, Hector Joberteh was killed in cold blood". 4 September 2017. http://thenet.ng/2017/09/how-gulder-ultimate-search-winner-hector-joberteh-was-killed-cold-blood/. 
  8. "Nigerian died 'in TV challenge'". News.bbc.co.uk. 9 August 2007. Retrieved 30 November 2021. 
  9. "Gulder Ultimate Search, other reality shows return after long breaks". Punch Newspapers. 26 September 2021. Retrieved 30 November 2021. 
  10. "Gulder Ultimate search partners MultiChoice for Season 12". Vanguardngr.com. 28 September 2021. Retrieved 30 November 2021. 
  11. "Gulder Ultimate Search unveils 18 contestants as show begins October 16". Vanguardngr.com. 4 October 2021. Retrieved 30 November 2021. 
  12. "GUS 12… Toast the Ultimate Craftsman". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-01-29. Retrieved 2023-05-01. 
  13. "Odudu Otu Is The Winner Of Gulder Ultimate Season 12". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-12-26. Retrieved 2023-05-01. 
  14. www.premiumtimesng.com https://www.premiumtimesng.com/entertainment/naija-fashion/502692-odudu-otu-wins-gulder-ultimate-search-season-12.html. Retrieved 2023-05-01.  Missing or empty |title= (help)
  15. "Odudu Wins Gulder Ultimate Search Season 12 – THISDAYLIVE". www.thisdaylive.com. Retrieved 2023-05-01.