Jagun Jagun (Fíìmù Nàìjíŕà)

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jagun Jagun (Fíìmù Nàìjíŕà)
Fáìlì:Jagun Jagun.jpg
AdaríTope Adebayo Àdàkọ:Plain list Adebayo Salami
Olùgbékalẹ̀Femi Adebayo
Àwọn òṣèréFemi Adebayo Àdàkọ:Plain list Lateef Adedimeji Àdàkọ:Plain list Faithia Balogun Àdàkọ:Plain list Bukunmi Oluwasina

Àdàkọ:Plain list Ibrahim Yekini

Àdàkọ:Plain list Bimbo Ademoye
Ilé-iṣẹ́ fíìmùEuphoria360Media
OlùpínNetflix
Déètì àgbéjáde10 August 2023
Orílẹ̀-èdèNigeria
ÈdèYoruba

Jagun Jagun jẹ́ fíìmù àgbéléwò tí Netflix gbé jáde ní ọdún 2023. Ó jẹ́ fíìmù àgbéléwò ajẹmọ́-ìtàn-akọni, èyí tí Fẹ́mi Adébáyọ̀ àti Euphoria360 Media ṣàgbéjáde.[1] Adebayo Tijani àti Tope Adebayo Salami ni olùdarí eré náà.[2] Lára àwọn akópa eré náà ni Femi Adebayo, Lateef Adédiméjì, Bimbo Ademoye, Faithia Balogun, Mr Macaroni, Bukunmi Oluwashina, Ibrahim Yekini àti Muyiwa Ademola. Ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹjọ ọdún 2023 ni Netflix gbé eré náà jáde, fún wíwò.[1]

Àhunpọ̀ ìtàn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Fíìmù Jagun Jagun dá lórí ìtàn jagunjagun kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ògúndìjì. Jagunjagun yìí lágbára, ó jẹ́ olókìkí, tó sì máa ń mú ìbẹ̀rùbojo bá àwọn ìlú tó wà ní agbègbè rẹ̀, àmọ́ agbára ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gbọ́tìjà tó wá kọ́ṣẹ́ ogun kó ba lè gbẹ̀san ìkú bàbá rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sì ní bà á lẹ́rù.[3] Láti ilẹ̀ ní Ògúndìjì ti jẹ́ amúnisìn tó sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣeyọrí nínú gbígba ìlú onílùú láti fi fún àwọn adarí tí kò tọ́. Ṣàdédé ni dídé Gbọ́tìjà já sí ẹ̀rù fun, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní wá oríṣiríṣi ọ̀nà láti mu kúrò lójú ọ̀nà.[4][5]

Àwọn akópa[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìṣàgbéjáde[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Apá Ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà ní wọ́n ti ṣe fíìmù Jagun Jagun, ó sì gbà wọ́n ju oṣù kan lọ láti gbé e jáde.[1] Òṣèrébìnrin tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bukunmi Oluwashina sọ ọ́ di mímọ̀ pé Femi Adebayo ti yan òun fún ẹ̀dá-ìtàn tí òun ṣe lọ́dún kan sẹ́yìn, kí iṣé tó bẹ̀rẹ̀ lórí fíìmù náà.[7]

Femi Adebayo tó ṣàgbéjáde fíìmù King of Thieves, fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé èròńgbà òun ni láti kí àṣeyọrí fíìmù Jagun Jagun jú ti àwọn èyí tí òun tí ṣe sẹ́yìn lọ, kó sì tún ju ti King of Thieves.[8]

Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹjọ (10 August), ọdún 2023, wọ́n ṣàgbéjáde fíìmù Jagun Jagun sí orí Netflix. Láàárín wákàtí méjìdínláàádọ́ta (48) tí wọ́n gbé e jáde, ó bẹ̀rẹ̀ sì tàn kálẹ̀ ní United Kingdom àti orílẹ̀-èdè mẹ́tàdínlógún mìíràn.[9] Láàárín ọjọ́ mẹ́ta tí ó jáde, àwọn ènìyàn tó wo fíìmù náà tó 2,100,000, ìgbà tó dẹ̀ máa fi di ọjọ́ 20, oṣù kẹjọ, ọdún 2023, àwọn tó ti wo fíìmù náà ti wọ 3,700,000. Èyí sì mu kó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn fíìmù mẹ́wàá àkọ́kọ́ tí àwọn ènìyàn ń wò jù.[10]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 1.2 Oloruntoyin, Faith (2023-07-21). "Here is your first look at Netflix's 'Jagun Jagun'". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-07-22. 
  2. "Netflix Unveils 'Jagun Jagun (The Warrior)': An Epic Yoruba Tale of Power, Love, and Honor! » YNaija". YNaija (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2023-07-22. Retrieved 2023-07-22. 
  3. "Yoruba film 'Jagun Jagun' set to premiere on Netflix". P.M. News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-08-12. 
  4. Oadotun, Shola-Adido (2023-08-12). "MOVIE REVIEW: Jagun Jagun raises bar for Nigerian epic films". Premium Times (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-08-12. 
  5. Mosadioluwa, Adam (2023-08-10). "Femi Adebayo's Netflix epic 'Jagun Jagun' earns fans' applause". Tribune Online (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-08-12. 
  6. NNN (2023-08-11). "Jagun Jagun: A Masterpiece of Nigerian Cinema". NNN (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-08-12. 
  7. Oluwayemi, Oluwapelumi. "Actress Bukunmi Oluwasina unveils daring role in "Jagun Jagun" - P.M. News" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-07-22. 
  8. Acho, Affa (2023-08-10). "Nigerians Hail Actor Femi Adebayo's Netflix Epic Jagun Jagun". Leadership (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-08-12. 
  9. Afigbo, Chinasa (2023-08-12). ""Record-breaking": Femi Adebayo's new film hits top 10 in 18 countries in 48 hrs". Legit.ng - Nigeria news. (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-08-12. 
  10. Netflix. "Weekly Top 10 lists of the most-watched TV and films" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-08-17.