Ààre Kúrunmí Ìjàyè

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Ààre Kúrunmí Ìjàyè jé jagun jagun, alágbára, akínkanjú àti òkan lára àwon akoni ìgbà ìwásè tí ó ní agbára, ogbón àti oògùn púpò. Ó jé omo bíbí àti asíwájú tàbí adarí ìlú Ìjàyè lásìkò tirè ní ìpílè Òyó ní àsìkò 1831-1862

Ìgbésí ayé rè[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ààre Kúrunmí ni ó jé oníyàwó púpò tí ó sì lo òpò ìgbésí ayé rè lójú ogun, níbi tí ó ti ma n jà fitafita tí ó sì n kó òpò erù àti erú. Kúrunmí bá òpòlopò ìlú jagun tí ó sì ségun won.[1]

Ìtàpórógan rè pèlú Ìbàdàn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ònà méjì ni ìtàn tí ó rò mó Ààre Kúrunmí Ìjàyè tí ó sokùn fa ikú rè. Àkókó ni wípé gégé bí ìtàn se so, Ààre Kúrunmí ko ìréje ìdí nìyí tí òun àti Aláàfin Ọ̀yọ́ìgbà náà oba Àláàfin Àdélú tí ó jé omo bíbí Aláàfin Àtìbà tí ó gbésè fi gbéná wojú ara won látàrí wípé Ààre Kúrunmí kò láti San ìsákólè odoodun fún Òyó. Ààre Kúrunmí fé láti GBA òmìnira fún ìlú re (Ìjàyè) kúrò lábé àse àti ìmúni sìn ìlú [Ọ̀yọ́]]sùgbón, òrò náà kèkí púpò. Nígbà tí Aláàfin Àdélú rí wípé Kúrunmí ti tàpá sí àse àti òfin ìlú Òyó, ó gbé onísé oba dìde wípé kí wón lo fun ní àrokò méjì kan kí ó mú èyí tí ó wùú. Àrokò àkókó ni àrokò àlááfíà, èkejì ni àrokò ogun. Àmó, Ààre Kúrunmí mú àrokò ogun. Nípa ìdí èyí, àwon ìlú tí ó yi ká bí: Ede,Ìbàdàn,àti Ègbá bèé, wón ròó kí ó mú àrokò àláfíà kí ó má se bá Òyó jagun, Kúrunmí gégé bí ológun ti tafà ogun ná ó sì n retí ìjà Òyó.[2]

Bákan náà ni abala kejì ìtàn yìí ní àìgbóra eni yé ni ó fa ìjà láàrín àwon omo ìyá méta ilú Ìjàyè,ìlú ìbàdàn àti Òyó Àtìbà tí wón sì jo dìgbò-lùjà látàrí ìlú wo ni yóò jé adarí ilè Yorùbá láàrín Ìjàyè, Ìbàdàn, àti Òyó túntún (Òyó Àtìbà) léyìn tí Òyó àkókó yi subú nínú ogun Òyó àti Fulani lábé Aláàfin Látoósà láti lè gbé àse ilè Yorùbá ró ní odún 1855. Ààre Kúrunmí àti ìlú Ìbàdàn ni wón jó dámi ìjà kaná, tí ìtàn sì tún fìdí rè múlè wípé olùpolongo èsin Kírísítì olùsó àgùntàn Bowen tí ó dá ìjo Baptist sílè náà be Ààre Kúrunmí láti má se jagun, kàkà kí ó gbà n se ló wolé lo gbé Bíbélì àti ètù ìbon jádé tí ó sì n sofún okùsó náà wípé ogun ni òun yóò mú nítorí jagun jagun ni àwon baba nlá òun báyìí ni Bowen sofún Kúrunmí wípé ìhìn rere ni òun wá polowo re kìí sogun, léyìn èyí ni a gbó pé olùsó náà kúrò ní Ìjàyè tí ó sì lo dá ìjo rè sílè ní ìlú Abeokuta. Èmí sonú púpò nínú ogun abélé Ìbàdàn àti Ìjàyè yìí tí Ààre Kúrunmí sì ségun Ìbàdàn fún ìgbà àkókó tí ó sì mú Basòrun Ògúnmólá tí ó jé olórí ológun ìlè Ìbàdàn lásìkò náà lérú, ó soó mólè nídìí òkan nínú àwon òrìsà Ògún rè, tí ó sì n fun ní eerú (ashes) jé dípò ónjé gidi. Ìtàn sopé òkan lára àwon ìyàwó Ààre Kúrunmí ni tí ó jé agbèyìn bebo jé ni ó yó kélé lo tú Basòrun Ògunmólá sílè láàrín òru. Kété tí Ògúnmólá padà dé Ìbàdàn ni ó lo wà àwon omo ogun kúnra pèlú ìrànlówó ogórùún àti mókànlélógójì ìlú (141), láti fi bá Ààre Kúrunmí jà. Nínú ogun eléèkejì yí ni àwon omo Kúrunmí márùún kú sí, pèlú bí àwon omo ogun Ìbàdàn ti pa àwon omo re márúún tí wón sì gbé orí òkan nínú won ránsé sí bàbá won (Kúrunmí). Ikú àwon omo yìí dùún gidigidi.[3]

Ikú rè[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Orísirísi atótónu ló wáyé lórí ikú Ààre Kúrunmí. Òpò ní n se ni ojú tìí nígbà tí ó pàdánù ogun náà sówó Ìbàdàn tí ó sì fi bínú bé sínú odò Òsé, àwon kan ní n se ló pokùn so, bákan náà ni ìtàn kan tún so pe wón paá lójú ogun tí wón sì gbé òkú rè wálé láti siín, sùgbón won kò rí orípa ibojì rè títí di òní, àwon kan tún so pé Ààre Kúrunmí kú sínú ilé rè ni tí wón sì sín sí ègbé odò Òsé. Wón tún fi kun wípé sájú kí wón tó sin Ààre Kúrunmí, wón kókó sin àwon erú méta sáájú kí wón tó sin Ààre Kúrunmí níbàámu pèlú ìsèse.

Àwon ìtóka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. adekunle (2018-01-10). "Kurunmi: Self sacrifice, obduracy in defence of tradition". Vanguard News Nigeria. Retrieved 2018-11-08. 
  2. Omipidan, Teslim Opemipo (2016-03-22). "The Ibadan-Ijaye War (1861-1862) - OldNaija". OldNaija. Retrieved 2018-11-08. 
  3. "Kurunmi of Ijaye, 1831-1862 : a biography of a militant Yoruba ruler in SearchWorks catalog". SearchWorks catalog. 2018-10-20. Retrieved 2018-11-08.