Jump to content

Àdéhùn Àbùrí

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Wọ́n ṣe Àdéhùn Àbùrí lọ́dún 1967 níbi ìpàdé kan tí ó wáyé láàárín àwọn aṣojú olórí ìṣèjọba ológun ti ìjọba Àpapọ̀ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti àwọn aṣojú olórí àwọn ènìyàn ní apá ìlà-oòrùn Nàìjíríà tí Ajagun Colonel Odumegwu Ojukwu darí. Wọ́n pe ìpàdé yìí láti wá ọ̀nà àbáyọ ìkẹyìn kí ogun abẹ́lé, Biafra máà bẹ́ sílẹ̀ nígbà náà.[1] Ìpàdé yìí wáyé lọ́jọ́ kẹrin àti karùn-ún oṣù kìíní ọdún 1967.

Ibi ìpàdé Àbúrì

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àbúrì jẹ́ ìlú kan lápá ìlà oòrùn lórílẹ̀-èdè Ghana, wọ́n yan ìlú yìí fún ìpàdé àlàáfíà náà nítorí àbò olórí àwọn aṣojú ìlà oòrùn Nàìjíríà, Odimegwu Ojukwu, tí ó jẹ́ Gómìnà nibẹ nígbà náà kò dájú láwọn ẹkùn àríwá àti ìwọ oòrùn Nàìjíríà nígbà rògbòdìyàn náà[2]

Àwọn kókó ìpàdé Àbúrí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn wọ̀nyí ni aṣojú kọ̀ọ̀kan níbi ìpàdé Àbúrí:

Àwọn yòókù ni:

  • N. Akpan, Akọ̀wé Gómìnà ìjọba ológun ẹkùn ìlà Òòrùn Nàìjíríà
  • Alhaji Ali Akilu Akọ̀wé Gómìnà ìjọba ológun ẹkùn àríwá Nàìjíríà
  • D. Lawani Under, Akọ̀wé Gómìnà ìjọba ológun ẹkùn ààrin ìwọ oòrùn Nàìjíríà
  • P. Odumosu, Akọ̀wé Gómìnà ìjọba ológun ẹkùn ìwọ Òòrùn Nàìjíríà
  • S. Akenzua (ẹni tí ó wá jọba ní ìlú Benin, Erediauwa I[4]Àdàkọ:Circular reference)

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. / Biafra Story, Frederick Forsyth ,Leo Cooper, 2001 ISBN 0-85052-854-2
  2. Ethnic politics in Kenya and Nigeria By Godfrey Mwakikagile, Nova Publishers, 2001.ISBN 1-56072-967-8
  3. http://www.dawodu.com/aburi1.htm
  4. Erediauwa I