Àdìtú Olódùmarè

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Àdìtú Olódùmarè je oruko iwe ti D.O. Fagunwa ko.

Ọ̀rọ Akọsọ

Iwe yi wa fun tọmọde tagba lọkunrin lobinrin ti nwọn mọ ede Yoruba ka dada. O wa fun lilo pẹlu awọn iwe mi miran ti awọn ọmọ ile iwẹ nka nínú ile ìwe wọn, iwe bi “Ogboju Ọdẹ”. “Ireke Onibudo” ati bẹ bẹ lọ. Bi awọn ọmọ ba ka eyikeyi ninu awọn iwe wọnyi bi o ti yẹ, dandan ni ki nwọn lo meji pọ ni ọdun kan, ki nwọn pari ọkan ni oṣu mẹfa iṣaju, ki nwọn pari ekeji ni oṣu mẹfa ti o tẹle e.

Mo ni ọrọ pataki lati sọ nipa iwe yi fun awọn ti nwọn nkọ Yoruba pataki fún idanwo ṣiṣe. Idanwo bi iru eyiti àwọn olukọ nṣe ni ile ẹkọ giga ti a ti nkọ wọn (Grades II and III Teachers Examination) tabi fun idanwo àbájáde ile ẹkọ Girama (West African School Certificate Examination). Yio jẹ iranlọwọ ni nwọn ba ka iwe yi dada tobẹ ti awọn gbolohun ọrọ nínú rẹ̀ yio kó wọ wọn nínú agbari lọ, iwọnyi ni nwọn le lo ti yio ran wọn lọwọ nigbati nwọn ba ndahun ibere ni igba idanwo.

  • D.O. Fágúnwà (2005) Àdììtú Olódùmarè Ibadan; Evans Brothers (Nigeria publishers) Limited, ISBN 978-126-239-7. Ojú-iwé 148.