Jump to content

Àjàkálẹ̀ àrùn Covid-19 ní Madagascar

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àjàkálẹ̀ àrùn Covid-19 ní Madagascar
ÀrùnCOVID-19
Irú kòkòrò èrànSARS-CoV-2
IbiMadagascar
Index caseAntananarivo
Arrival date13 March 2020
(4 years, 7 months and 4 days)
Gbogbo iye àwọn ẹ̀sùn6,849 (as of 18 July) [1][2]
Active cases3,455 (as of 18 July)
Iye àwọn tí ara wọn ti yá3,339 (as of 18 July)
Iye àwọn aláìsí
55 (as of 18 July)[3]

Wọ́n kéde pé Ajàkálẹ̀ àrùn COVID-19 bẹ́ sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè Madagascar lóṣù kẹta ọdún 2020.

Bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lọ́jọ́ Kejìlá oṣù kìíní ọdún 2020 ni àjọ elétò ìlera àgbáyé, World Health Organization (WHO) jẹ́rìí pé ẹ̀rànkòrónà, Covid-19, ni ó ń fa àìsàn èémí láàárín àwọn ènìyàn kan lágbègbè Wuhan,ní Ìpínlẹ̀ Hubei, lórílẹ̀-èdè China, èyí tí wọ́n jábọ̀ rẹ̀ fún àjọ WHO lọ́jọ́ kokànlélọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 2019.[4][5]

Iye ìjàm̀bá ikú àrùn Covid-19 kéré sí ti àrùn SARS, Severe acute respiratory syndrome tó bẹ́ sílẹ̀ lọ́dún 2003,[6][7] ṣùgbọ́n jíjàkálẹ̀ àrùn náà lágbára ju SARS lọ, pàápàá jù lọ iye àwọn ènìyàn tí àrùn náà ń pa lápapọ̀.[8][6]

Àjàkálẹ̀ àrùn náà láti ìgbà dé ìgbà

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Oṣù kẹta ọdún 2020

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní olú-ìlú orílẹ̀-èdè Madagascar, Antananarivo ní wọ́n ti kọ́kọ́ kéde àwọn ẹni àkọ́kọ́ mẹ́ta tí ó lùgbàdì àrùn Covid-19 lórílẹ̀ èdè náà lógúnjọ́ oṣù kẹta. Obìnrin ni gbogbo wọn.[9]

Lóṣù kẹta náà, odidi ènìyàn mẹ́tàdínlọ́gọ́ta ní wọ́ kéde pé wọ́n ní àrùn náà, gbogbo ló sìn wà nínú àìsàn náà títí oṣù náà fi parí.[10]

Oṣù kẹrin ọdún 2020

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Láàárin oṣù kẹrin, Madagascar tí ní odidi ènìyàn mọ̀kàndínlọ́gọ́fà, 121 tí wọ́n kéde pé wọ́n ní àrùn Covid-19, ṣùgbọ́n kò sí eni kankan tó kú.[11]

Àwọn ènìyàn ókànléláàádọ́rin (71) ni àpapọ̀ àwọn tuntun tí wọ́n kárùn náà ní oṣù kẹrin. Tí àpapọ̀ iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ní àrùn náà ni Madagascar láti ìgbà tí ó ti bẹ́ sílẹ̀ jẹ́ éjìdínlọ́gbọ̀lélọ́gọ́fà, 128. Àpapọ̀ iye àwọn tí àìsàn náà ṣì ń bá jà títí di ìparí oṣù kẹrin jẹ́ mẹ́rìndínlógojì, èyí tí ó jẹ́ ìdí kù ìdá mẹ́tàdínlógojì (37%) láti oṣù kẹta.[12]

Oṣù karùn-ún ọdún 2020

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lósù karùn-ún, Madagascar kéde àpapọ̀ ènìyàn tí iye wọn jẹ́ ókàndínlógóje (149) tí wọ́n ní àrùn Covid-19 ṣùgbọ́n kò sí ẹnikẹ́ni tó kú.[13] Eni àkọ́kọ́ tí àìsàn náà pa ni wọ́n kéde lọ́jọ́ kẹrìndínlógún oṣù karùn-ún. Òkú náà tí wọ́n kò dárúkọ rẹ̀ jẹ́ òṣìṣẹ́ ìlera ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta (57) tí ó ti ní àrùn ìtọ̀ ṣúgà àti ẹ̀jẹ̀ rúru.[14]

Nínú oṣù yìí, ènìyàn 643 ni èsì àyẹ̀wò tí fihàn pé wọ́n ní àrùn náà. Àpapọ̀ iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ti ní àrùn náà láti ìgbà tí ó bẹ́ sílẹ̀ ní Madagascar jẹ́ 771. Iye àwọn ènìyàn tí àìsàn náà ṣì ń bá jà títí di ìparí oṣù náà jẹ́ 597, ó jẹ́ ènìyàn 561 ti Wọ́n lé sí i láti oṣù kẹrin. Ènìyàn mẹ́fà ni àrùn náà sìn ti pa lóṣù karùn-ún.[15]

Oṣù kẹfà ọdún 2020

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lọ́jọ́ kejì oṣù kẹfà, àjọ European Centre for Disease Prevention and Control ti kéde ikú ènìyàn mẹ́fà tí àrùn Covid-19 pa ní Madagascar.[3]

Àjàkálẹ̀ àrùn náà ṣoro débi pé wọ́n gbà pé ó ṣòro ju ìjàm̀bá àsìkò iná lọ, débi pé àwọn ènìyàn tí wọ́n máa ń rí oúnjẹ ọòjọ́ láti ibi iṣẹ́ ìgbàfẹ́ níláti bẹ̀rẹ̀ sí ní wá oúnjẹ òòjọ́ lọ sínú igbó.[16]

Lóṣù náà, àwọn ènìyàn 1443 ni èsì àyẹ̀wò fihàn pé wọ́n kó àrùn Covid-19, èyí tí ó mú kí àpapọ̀ iye àwọn tí wọ́n ní àrùn náà di 2214 láti ìgbà tí ó ti bẹ́ sílẹ̀ lórílẹ̀ èdè náà. 1200 ni iye àwọn tí àrùn náà ṣì wà lára wọn títí di ìparí oṣù kẹfà, èyí ju ìlọ́po méjì lọ sí ti iye oṣù karùn-ún. Tí iye àwọn ènìyàn tí wọ́n kú lé sí i ní mẹ́rìnlá sí ogún.[17]

Oṣù keje ọdún 2020

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lọ́jọ́ Kejìlá oṣù keje, àpapọ̀ iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ti ní àrùn náà jẹ́ 4867, èyí ju ìlọ́po méjì àwọn tí wọ́n ní àrùn náà lọ ní ìparí oṣù kẹfà. Lọ́jọ́ keje oṣù keje, ìjọba wọn tún pàṣẹ ìsémọ́lé tipátipá ní àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè náà láti lè dẹ́kun àjàkálẹ̀ àrùn náà sí í.[18]

Àwọn ọ̀nà Ìdènà àrùn náà

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n kéde ìsémọ́lé tipátipá ni ìlú-ńlá méjì. [19] Ìjọba kéde lọ́jọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹta pé ìdádúró gbogbo ìrìnnà ọkọ̀ òfuurufú jákèjádò orílẹ̀-èdè náà yóò wáyé fún odidi oṣù kan gbáko, èyí tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní ogúnjọ́ oṣù kẹta ọdún 2020.[20]

Nítorí rògbòdìyàn yìí, àìsí àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ wá sí orílẹ̀ èdè náà fa ìfàsẹ́yìn fún ilé-iṣẹ́ ìjọba tí ó ń rí sí ìrìnnà ìgbafẹ́.[21] Ambatovy mine suspended operations.[19] Ní àsìkò yìí ilé ìfowópamọ̀ àgbà, Central Bank of Madagascar kó ẹgbẹlẹmùkú owó ilẹ̀ náà, ariary síta láti tu àwọn ará ìlú lára nítorí rògbòdìyàn àrùn Covid-19.[22]

Lógúnjọ́ oṣù kẹrin ọdún 2020,[23] Ààrẹ orílẹ̀-èdè Madagascar, Andry Rajoelina kéde egbògi tí wọ́n gbà pé ó ń wo àrùn Covid-19, tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Covid Organic, tí ilé iṣẹ́ ìwádìí ìjìnlẹ̀, Madagascar Institute of Applied Research (MIAR), ṣe. Wọ́n ṣe àgbo náà láti ara ègbogi ewé dóńgóyárò, tí wọ́n ń pè ní artemisia àti àwọn ewé mìíràn. Wọ́n da àwọn ológun sí ìgboro láti pín àgbo náà fún àwọn ará ìlú. Ọ̀gágun, Colonel Willy Ratovondrainy kéde lórí ẹ̀rọ tẹlifíṣàn pé àgbo náà máa ń fún àwọn èròjà ara ní okun sí i.[24] Bí ó tilẹ̀ wù kí ó rí, àjọ National Academy of Medicine of Madagascar (ANAMEM) fọhùn pé òun kò fara mọ́ ìgbésẹ̀ ìjọba lórí àgbo yìí, bẹ́ẹ̀ náà àjọ àgbáyé fún ìlera World Health Organization (WHO) kilọ̀ pé kò ì tí ì sí ìdánilójú ìwádìí ìjìnlẹ̀ tó fihàn pé àgbo, covid organic lè wo àrùn Covid-19 tí ìjọba orílẹ̀ èdè Madagascar kéde rẹ̀. Àjọ ilẹ̀ Adúláwò Áfíríkà, African Union bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú ìjọba orílẹ̀-èdè Madagascar láti ṣe àyẹ̀wò àgbo náà bóyá ó lè wo àrùn Covid-19 tàbí bóyá ó ní ìjàm̀bá kan tí ó lé fà lágọ̀ọ́ ara.[11][25]

Ní àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè náà pẹ̀lú Antananarivo, ìjọba kéde ìsémọ́lé láti ọjọ́ kẹfà sí ogúnjọ oṣù kefa ọdún 2020 láti dènà àjàkálẹ̀ àrùn náà lọ́nà tó peléke sí í látàrí àwọn ènìyàn tuntun tí wọ́n ń kó àrùn náà.[26]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Johns Hopkins CSSE. "Coronavirus COVID19 (2019-nCoV)" (ArcGIS). Coronavirus COVID-19 Global Cases. Retrieved 18 July 2020. 
  2. "Worldometer Madagascar". Retrieved 18 July 2020. 
  3. 3.0 3.1 "Download today’s data on the geographic distribution of COVID-19 cases worldwide". ECDC. Retrieved 2 June 2020. 
  4. Elsevier. "Novel Coronavirus Information Center". Elsevier Connect. Archived from the original on 30 January 2020. Retrieved 15 March 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  5. Reynolds, Matt (4 March 2020). "What is coronavirus and how close is it to becoming a pandemic?". Wired UK. ISSN 1357-0978. https://www.wired.co.uk/article/china-coronavirus. 
  6. 6.0 6.1 "Crunching the numbers for coronavirus". Imperial News. Archived from the original on 19 March 2020. Retrieved 15 March 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  7. "High consequence infectious diseases (HCID); Guidance and information about high consequence infectious diseases and their management in England". GOV.UK (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 3 March 2020. Retrieved 17 March 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  8. "World Federation Of Societies of Anaesthesiologists – Coronavirus". www.wfsahq.org. Archived from the original on 12 March 2020. Retrieved 15 March 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  9. "Officiel trois premiers cas de Coronavirus à Madagascar" (in fr). Orange Madagascar. 20 March 2020. https://actu.orange.mg/officiel-trois-premiers-cas-de-coronavirus-a-madagascar/. 
  10. "Afrique. Coronavirus : ces pays qui ont les meilleurs taux de guérison" (in Èdè Faransé). 2 April 2020. Retrieved 1 July 2020. 
  11. 11.0 11.1 "Coronavirus: Caution urged over Madagascar's 'herbal cure'". BBC News. 22 April 2020. Archived from the original on 30 April 2020. https://web.archive.org/web/20200430104857/https://www.bbc.com/news/world-africa-52374250. Retrieved 7 May 2020. 
  12. "Coronavirus disease 2019 (COVID-19) situation report 101" (PDF). World Health Organization. 30 April 2020. p. 8. Retrieved 1 July 2020. 
  13. Qazi, Shereena; Uras, Umut (5 May 2020). "UK coronavirus death toll rises above 30,000: Live updates". Al Jazeera. https://www.aljazeera.com/news/2020/05/world-coronavirus-death-toll-exceeds-250000-live-updates-200504231301555.html. Retrieved 5 May 2020. 
  14. "Madagascar records its first COVID-19 death -official". Reuters. 17 May 2020. Archived from the original on 4 June 2020. Retrieved 17 May 2020. 
  15. "Coronavirus disease (COVID-19) situation report 133" (PDF). World Health Organization. 1 June 2020. p. 7. Retrieved 1 July 2020. 
  16. "In Madagascar’s dry forests, COVID-19 sparks an intense, early fire season". Mongabay Environmental News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-06-25. Retrieved 2020-06-27. 
  17. "Epidémie - 76 nouveaux cas confirmés positifs au coronavirus sur 148 tests annoncés ce mardi". 2424 (in Èdè Faransé). 2020-06-30. Retrieved 2020-07-01. 
  18. "Madagascar reimposes lockdown in capital as coronavirus cases surge". www.msn.com. Retrieved 2020-07-12. 
  19. 19.0 19.1 "Sumitomo halts mines in Bolivia, Madagascar". MINING.COM. 26 March 2020. https://www.mining.com/sumitomo-halts-mines-in-bolivia-madagascar/. Retrieved 26 March 2020. 
  20. "Madagascar suspend toutes les liaisons aériennes régionales et internationales". mofcom.gov.cn (in Èdè Faransé). 2020-03-18. Archived from the original on 18 March 2020. Retrieved 2020-03-30.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  21. "Tourists' departure leaves Madagascar forlorn as coronavirus fears bite" (in en). Reuters. 20 March 2020. https://www.reuters.com/article/us-health-coronavirus-madagascar-tourism/tourists-departure-leaves-madagascar-forlorn-as-coronavirus-fears-bite-idUSKBN2171QM. Retrieved 26 March 2020. 
  22. "Madagascar's central bank injects cash to support economy due to virus" (in en). Reuters. 24 March 2020. https://www.reuters.com/article/health-coronavirus-madagascar-economy/madagascars-central-bank-injects-cash-to-support-economy-due-to-virus-idUSL8N2BH6J1. Retrieved 26 March 2020. 
  23. "Madagascar : Andry Rajoelina lance son remède contre le coronavirus" (in Èdè Faransé). jeuneafrique. 21 April 2020. Retrieved 7 July 2020. 
  24. "Madagascar hands out 'miracle' coronavirus cure as it lifts lockdown". The Straits Times. 23 April 2020. Archived from the original on 2 May 2020. https://web.archive.org/web/20200502065651/http://www.straitstimes.com/world/africa/madagascar-hands-out-miracle-coronavirus-cure-as-it-lifts-lockdown. Retrieved 7 May 2020. 
  25. "Coronavirus: What is Madagascar's 'herbal remedy' Covid-Organics?". Al Jazeera. 5 May 2020. https://www.aljazeera.com/news/2020/05/coronavirus-madagascar-herbal-remedy-covid-organics-200505131055598.html. Retrieved 5 May 2020. 
  26. "Madagascar reimposes lockdown in capital as coronavirus cases surge". CNN. 6 July 2020. Retrieved 7 July 2020.