Jump to content

Àjẹsára ibà pọ́njú-pọ́ntọ̀

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àjẹsára ibà pọ́njú-pọ́ntọ̀ jẹ́ àjẹsára tí ń dáàbò bo ni lọ́wọ́ ibà pọ́njú-pọ́ntọ̀.[1] Ibà pọ́njú-pọ́ntọ̀ jẹ́ àkóràn àrùn kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn tó má a ń sábà wáyé ní Afrika àti Gúsù Amẹ́ríkà. Iye àwọn ènìyàn tó tó 99% ni ó má a ń ní agbára àti kojú àrùn náà láàárín oṣù kan lẹ́yìn tí wọ́n bá ti gba àjẹsára náà, èyí sì dàbí ẹni pé yóò wà títí ayé wọn. A le lo àjẹsára náà láti ṣàkóso ìtànkiri àrùn náà. À ń fún ni gẹ́gẹ́ bí abẹ́rẹ́ tí a gún sínú ẹran ara ẹni tàbí tí a gún sábẹ́ awọ ara ẹni.[1]

Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) gba ni nímọ̀ràn láti má a gba àjẹsára lóòrèkóòrè ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí àrùn náà ti wọ́pọ̀. Èyí gbọ́dọ̀ wáyé láàárín àkókò tí ènìyàn jẹ́ ọmọ oṣù mẹ́ẹ̀sán sí mẹ́ẹ̀wá. Àwọn ènìyàn tó ń rin ìrìn-àjò lọ sí àwọn agbègbè ibití àrùn náà ti ń wáyé ní a tún gbọdọ̀ fún ní àjẹsára náà.[1] A kìí sábà nílò àfikún ìwọ̀n àjẹsára náà lẹ́yìn èyítí a bá ti kọ́kọ́ fún ni.[2]

Àjẹsára ibà pọ́njú-pọ́ntọ̀ jẹ́ èyítí kò léwu rárá. Èyí rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn tó ní àkóràn àrùn HIV ṣùgbọ́n tí wọn kò ní àmì àrùn náà pàápàá. Àtúnbọ̀tán wọ́ọ́rọ́wọ́ tó lè wáyé ni orí-fífọ́, ìrora nínú ẹran ara, ìrora lójú ibi abẹ́rẹ́, ibà, àti ara-sísú. Gbígbòdì egbògi lára ẹni a má a wáyé ní mẹ́ẹ̀jọ nínú mílíọ̀nù ìwọ̀n egbògi náà, ìṣòro tó lágbára tó níí ṣe pẹ̀lú  iṣan ara náà a má a wáyé ní mẹ́ẹ̀rin nínú mílíọ̀nù ìwọ̀n egbògi náà, bẹ́ẹ̀ sì ni ìkùnà àwọn ẹ̀yà tí nṣiṣẹ́ oríṣiríṣi nínú ara náà a má a wáyé ní mẹ́ẹ̀ta nínú mílíọ̀nù ìwọ̀n egbògi náà. Ó ṣeé ṣe kí ó máṣe léwu láti lòó nígbàtí ènìyàn bá ní oyun, nítorí náà, a dámọ̀ràn lílò rẹ̀ láàárín àwọn ènìyàn tó lè wà ní sàkání ibití àrùn náà ti ń ran ni.[1] A kò gbọdọ̀ lòó fún àwọn tí agbára kíkojú àrùn wọn kò bá múnádóko.[3]

A bẹ̀rẹ̀ ìmúlò àjẹsára ibà pọ́njú-pọ́ntọ̀ ní ọdún 1938.[4] Ó wà lórí Àkójọ Àwọn Egbògi Kòṣeémáàní ti Àjọ Ìlera Àgbáyé, àwọn òògùn tó ṣe pàtàkì jùlọ tí a nílò fún ètò ìlera ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ yòówù.[5] Iye owó rẹ̀ lójú pálí jẹ́ 4.30 sí 21.30 USD fún ìwọ̀n egbògi náà kanṣoṣo ní ọdún 2014.[6] Ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà iye owó rẹ̀ jẹ́ 50 sí 100 USD.[7] A ṣe àgbéjáde àjẹsára náà pẹ̀lú àwọn kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn ibà pọ́njú-pọ́ntọ̀, àwọn èyítí a ti sọ di aláìlágbára.[1]

  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 "Vaccines and vaccination against yellow fever.
  2. Staples, JE; Bocchini JA, Jr; Rubin, L; Fischer, M; Centers for Disease Control and Prevention, (CDC) (19 June 2015).
  3. "Yellow Fever Vaccine".
  4. Norrby E (November 2007).
  5. "WHO Model List of EssentialMedicines" (PDF).
  6. "Vaccine, Yellow Fever"[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́].
  7. Hamilton, Richart (2015).