Jump to content

Àjọ̀dún Irreechaa

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Irreecha
Irreecha
Irreecha Festival in 2019 at Addis Ababa
Official nameIrreecha
Observed by
TypeNational, cultural
SignificanceThanksgiving
DateIn October every year[1]
Celebrations
Related toThanksgiving day

Irreecha (èyí tí a tún mọ̀ sí Irreessa tàbí Dhibaayyuu), ó jẹ́ àjọ̀dún ìdúpẹ́ ní ẹkùn Oromia, Ethiopia.[2] Àjọ̀dún Irreecha jẹ́ àjọ̀dún ìbílẹ̀ èyí tí ó gbajúgbajà ní ilẹ̀ Africa. Àwọn ẹ̀yà Oromo máa ń ṣe Irreecha láti dúpẹ́ fún òrìṣà Waaqa fún àánú, ojú rere, àwọn ohun rere tí wọ́n ti rí ní ọdún tí ó ré kọjá. Àjọ̀dún Irreecha jẹ́ èyí tí wọ́n máa ń ṣe ní ọdọọdún ní ìbẹ̀rẹ̀ Birraa, àkókò tí ó máa ń tẹ̀lé ìgbà òjò. Àwọn ogunlọ́gọ̀ àwọn ènìyàn ni wọ́n máa ń lọ sí ibi àjọ̀dún yìí.[3] Àjọ̀dún ìdúpẹ́ yìí jẹ́ èyí tí wọ́n máa ń ṣe ní àwọn odò kan tí a yà kalẹ̀ káàkiri ẹkùn Oromia. Lára àwọn odò náà ni Hora Fihe, Hora Harsadi, Bishoftu, káàkiri gbogbo ẹkùn Oromia.[4]

Ní ọdún 2019, wọ́n ṣe àjọ̀dún yìí ní Addis Ababa, olú-ìlú Ethiopia àti àwọn Ìpínlẹ̀ tí wọ́n ń bẹ ní ẹkùn Oromia, lẹ́yìn náà ni Irreecha tó ń bẹ ní Bishoftu.[5] Àjọ̀dún Irreecha tí ọdún 2020 èyí tí wọ́n ṣe ní Addis Ababa jẹ́ èyí tí wọ́n ṣe pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ̀rún márùn-ún àwọn ènìyàn látàrí àrùn COVID-19 tí ó bẹ́ sílẹ̀ .[6] Wọ́n máa ń ṣe ọdún Irreecha káàkiri gbogbo àgbáyé níbi tí àwọn ẹ̀yà tí wọ́n Jẹ́ ti Oromo bá ń gbé, pàápàá jùlọ ní Àríwá orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti ní Europe.[7]

Irrecha festival (2014)

Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni wọ́n túmọ̀ àjọ̀dún ọdún Irreecha tí àwọn ẹ̀yà Oromo gẹ́gẹ́ bí àjọ̀dún ìgbà ìnira láàrin oṣù kẹfà sí oṣù kẹsàn-án. Ṣùgbọ́n ohun tí ó ṣe pàtàkì lórí ọdún yìí ni pé kìí ṣe bí àwọn ènìyàn ṣe máa ń fi ojú wò ó. Àjọ̀dún Irreecha jẹ́ àjọ̀dún láti fi kí àwọn èso àti irúgbìn tí wọ́n ti ń retí káàbọ̀, pẹ̀lú àlàáfíà. Àwọn ẹ̀yà Oromo náà ka ìgbà ójó tí ó ń bẹ láàárín oṣù kẹfà sí oṣù kẹsàn-án sí ìgbà ìnira nínú ètò ìbánisọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ̀, látàrí òjò alágbára tí ó máa ń fa kí odò ó kún, kí àgbàrá ó sì máa ya káàkiri, èyí tí ó sì le gbé àwọn ènìyàn, ẹran, erè oko, àti àwọn ilé. Bẹ́ẹ̀ ni ìdíwọ́ le wà nínú Ìbáṣepọ̀ láàrin àwọn ẹbí, torí wọn kò ní ní àǹfààní láti kàn sí ara wọn torí odò kíkún. Ní àfikún, àsìkò yìí le jẹ́ àkókò ebi àti àìrọ́wọ́ mú lọ sí ẹnu fún àwọn ènìyàn kan nítorí pé àwọn erè oko tí wọ́n rí nínú oṣù kìíní ọdún kò ní le tó wọ́n títí di àkókò ìkórè tó kàn. Nítorí ìdí èyí àwọn ẹbí kan a máa ní àìtó oúnjẹ ní àkókò náà. Ní àkókò Birraa, àìnító oúnjẹ yìí máa ń dínkù nítorí àwọn oúnjẹ kan bí àgbàdo á ti pọ́n, àwọn ẹbí á sì ní àǹfààní láti jẹ ayo. Àwọn irúgbìn mìíràn bíi ànàmọ́, barley, abbl á ti tó jẹ ní àkókò yìí. Àwọn àìsàn kan bíi àìsàn ibà máa ń bẹ́ sílẹ̀ ní àkókò òjò. Nítorí ìdí èyí àwọn Oromos ríi àkókò náà gẹ́gẹ́ bíi èyí tí ó le. Kìí ṣe wí pé wọn kò nífẹ̀ẹ́ sí àkókò òjò àti ọyẹ́ rárá. Kó dà bí kò bá sí òjò wọ́n máa ń gba àdúrà sí òrìṣà Waaqa fún òjò.

Àwọn ẹ̀yà Oromo a máa ṣe àjọ̀dún Irreecha kìí ṣe láti dúpẹ́ lọ́wọ́ òrìṣà Waaqa nìkan ṣùgbọ́n láti kí àkókò ìkórè káàbọ̀ lẹ́yìn àkókò òjò àti ọyẹ́. Ní àkókò ọdún Irreecha, àwọn ẹbí, ará, ọ̀rẹ́, àti ìbátan máa ń kóra jọ pọ̀ láti ṣe ọdún yìí pẹ̀lú ìdùnnú àti ayọ̀. Àjọ̀dún Irreecha máa ń kó àwọn ènìyàn papọ̀ sún mọ́ ara wọn kí ìrẹ́pọ̀ ó le wà.

Àwọn ẹ̀yà Oromo máa ń ṣe ọdún yìí láti fi ṣe àmì ìparí ìgbà òjò, èyí tí a mọ̀ sí Ganna, èyí tí àwọn babańlá àwọn Oromo dá sílẹ̀, ní àkókò Gadaa Melbaa ní Mormor, Oromia. Ọjọ́ tí ó gbẹ̀yìn Gadaa Melbaa - àkókò ebi àti àìrí oúnjẹ jẹ - jẹ́ dídá sílẹ̀ ní ọjọ́ àìkú nínú ọ̀sẹ̀ tí ó gbẹ̀yìn oṣù kẹsàn-án tàbí ọjọ́ àìkú nínú ọ̀sẹ̀ kìíní oṣù kẹwàá gẹ́gẹ́ bí ó ti wà nínú kọ́jọ́dá Gadaa.

Ìṣẹ̀lẹ̀ Ìjàmbá

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọjọ́ kejì, oṣù kẹwàá, ọdún 2016, àwọn ènìyàn tí wọ́n tó ẹ́ẹ̀dẹ́gbẹ̀ta sí ọ̀ọ̀dúnrún níye ní wọ́n tè pa níbi ọdún ìbílẹ̀ ti Irreecha tí ó jẹ́ àjọ̀dún ìdúpẹ́, èyí tí ó jẹ́ àjọ̀dún tí ó tóbi tí ó sì mọ́ jù fún àwọn ènìyàn Oromo. [8] Ní ọjọ́ kan ṣoṣo péré, àwọn ènìyàn bíi méjìlá kú tí ọ̀pọ̀ nínú wọn sì fi ara pa yánnayànna ní àkókò yìí. Àwọn ènìyàn fi ẹ̀sùn kan àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò fún ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. [9]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "How to Travel to Ethiopia's Irreecha Festival As a Tourist". Archived from the original on 2021-01-21. https://web.archive.org/web/20210121051128/https://www.ethiopiaonlinevisa.com/irreecha-festival/. 
  2. "How to Travel to Ethiopia's Irreecha Festival As a Tourist". Archived from the original on 2021-01-21. https://web.archive.org/web/20210121051128/https://www.ethiopiaonlinevisa.com/irreecha-festival/. 
  3. "How to Travel to Ethiopia's Irreecha Festival As a Tourist". Archived from the original on 2021-01-21. https://web.archive.org/web/20210121051128/https://www.ethiopiaonlinevisa.com/irreecha-festival/. 
  4. "In pictures: Ethiopia's Oromos celebrate thanksgiving". https://www.bbc.com/news/world-africa-49945694. 
  5. "In Pictures: Ethiopia's Oromos celebrate Irreecha festival". Aljazeera. 6 Oct 2019. https://www.aljazeera.com/indepth/inpictures/pictures-ethiopia-oromos-celebrate-irreecha-festival-191006060457944.html. 
  6. "Ethiopia's largest ethnic group celebrate Thanksgiving festival". https://www.trtworld.com/africa/ethiopia-s-largest-ethnic-group-celebrate-thanksgiving-festival-40248. 
  7. "Irreecha: The Oromo National Thanksgiving Day". Waaqeffannaa.org. Archived from the original on 13 April 2016. Retrieved 15 January 2017.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  8. "Ethiopia mourns 55 killed during protest at Oromia festival". BBC News. 3 October 2016. https://www.bbc.com/news/world-africa-37539975. 
  9. Dozens killed in stampede at Ethiopian religious festival, October 2, 2016