Àjọ MAMSER

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

MAMSER jẹ́ gbólóhùn ìgé-kúrú fún (Mass Mobilization for Self Reliance, Social Justice, and Economic Recovery) Ó jẹ́ ìgbésẹ̀ òṣèlú láti dáni lẹ́kọ̀ọ́ ní orílẹ̀ èdẹ Nàìjíríà, tí Ààrẹ Babángídá buwọ́ lù gẹ́gẹ́ bí ìlànà kan pàtàkì tí ẹ̀ka ètò ìṣèlú lábẹ́ ììjọba tí Dr. Samuel Joseph Cookey jẹ́ adarí rẹ̀. Iṣẹ́ ẹ̀ka yìí láti ṣèjìròrò pẹ̀lú àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti láti jábọ̀ fún Armed Forces Ruling Council, lórí ọ̀nà tí ìjọba lè gbà láti mú ìgbà ọtun bá ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Wọ́n dá MAMSER kalẹ̀ ní ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹ́fà, ọdún 1987.

Kókó èròngbà MAMSER ni láti ṣúgbàá ètò iṣẹ́ ọ̀tun ìjọba. Ó rún jẹ́ ọ̀nà àrà láti ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Nàìjíríà lórí ètò ìṣèlú, láti kó wọn jọ kí wọ́n lè gbaradì àti kópa nínú ètò ìṣèlú àti ìtàkurọ̀sọ ìṣèlú tí ó ń bọ̀ lọ́nà lásìkò ìgbà náà, pàá pàá láti mú ìdàgbà-sókè bá àwọn ohun èlò tí abá ṣe lábẹ́lé fúnra wa ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Lára àwọn ìlànà MAMSA nìwọ̀n yí:

  1. Láti dà àwọn ọmọ ikẹ̀ Nàìjírìà lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè dẹ́kun fífohun ṣòfò àti ìba-ǹ-kan jẹ́ yálà tìjọba tàbí tàdáni.
  2. Lát dẹ́kun ìgbésí-ayé àdàmọdì àwọn ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà.
  3. Láti fẹsẹ̀ ìdẹ́kun ìwà ìbàjẹ́ tó dógbìn nílẹé-iṣẹ́ ìjọba bíi ìwà àjẹ́bánu, àìṣòtítọ́, màdàrú nínú ètò ìdìbò àti ètò ìkànìyàn, ìfòpin sí ìyapa nínú ẹ̀yà àti nínú ẹ̀sìn.

Àjọ MAMSER ni ó wà lábẹ́ ìṣàkóso àti àṣẹ Jerry Gana gẹ́gẹ́ bí alága nígbà tí Ken Saro Wiwa jẹ́ ọ̀kan lára aláṣẹ rẹ̀. Ẹ̀wẹ̀, lẹ́yìn oṣù dìẹ̀ tí Ken Saro Wiwa kúrò gẹ́gẹ́ bí aláṣe àjọ. Àjọ náà ti lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú mọ̀ọ́ká gbajúmọ̀, èyí tí Túndé Adénírran, tí ó padà di ọ̀gá àgbà fún àjọ NOA (National Orientation Agency), Mọlará Ògúndípẹ̀-Leslie, àti Jonathan Zwingina, tí ó jẹ́ Sẹ́nétọ̀ dún Federal Republic of Nigeria.

Ọ́n yí orúkọ MAMSER oadà sí NOA, ìyẹn (National Orientation Agency) tí àjọ náà sì tàn ká dé ìjọba ìbílẹ̀ 774 ní ilẹ̀ Nàjíríà, tí aláṣẹ àgbà pátápátá fún àjọ náà sì jẹ́ Dr. Garba Abari, ilé iṣẹ́ àjọ náà wà ní Old Secretariat, Area 1 Garki, Abuja.

Àwọn ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • BISIS IKE-AUDU, Special Report on Nigeria (2): Challenge of an action-packed tomorrow - Political transition, The Guardian (London), September 3, 1987
  • Stephen Wright; Nigeria: Struggle for Stability and Status, Westview Press, 1998
  • MICHAEL HENDERSON, "NIGERIAN LEADERS SEEK KINDER, GENTLER NATIONAL ETHIC", The Oregonian (Portland, Oregon), March 26, 1990
  • OKPATA JOSHUA, HEIR APPARENT; A STITCH IN TIME, May 22, 2011