Jump to content

Àlìmájìrín

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àlìmájìrí

Àlìmájìrí jẹ́ ìlànà ikẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn ará ilẹ̀ Hausa ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ń lò láti kọ́ àwọn Ìkọ kedere Ìkọ kedere ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn Islam. Wọ́n ṣe àfàyọ orúkọ ìlànà ikẹ́kọ̀ọ́ yí láti ara ọ̀rọ̀ Lárúbáwá "al-muhajirun" tí ó túmọ̀ sí "A rìn rìn-àjò" [1]

Almajirai ní ilé ìwé kan ni Birnin Kebbi, Kebbi State, Nàìjíríà

Bi ó ṣe bẹ̀rẹ̀ laye àtijọ́

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìlànà ìkẹ́kọ̀ọ́ yí ìlú Kanem Borno, níbi tí pupọ̀ nínú àwọn adarí wọn jẹ́ onímọ̀ nípa Alùkùránì tí ó jẹ́ ìwé mímọ́ ẹ̀sìn Islam. Lẹ́yìn ọgọ́rin mẹ́rin ọdún ó dìn mẹ́wá (700), tí wọ́n dá ìlú Sokoto sílẹ̀ ni wọ́n pọọ́n ní dandan láti máa lo ìlànà ìkẹ́kọ́ ẹ̀sìn Islam. Àwọn Ọba ilẹ̀ Sokoto àti Borno ni wọ́n wa ń ṣàkóso ẹ̀kọ́ Al-májìrí. Lásìkò yí, àwọn ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ ma ń wa lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn ni, tí àwọn ilé-ẹ̀kọ́ wọn gbogbo si wà ní ìtòsí ìletò wọn gbogbo. Àwọn olùbẹ̀wò aṣojú Ọba si ma wà ń ṣèbẹ̀wò, tí wọ́n si ń jábọ̀ fun Ọba. Àwọn ilé-ẹ̀kọ́ wọ̀nyí ni ó jẹ́ wípé owó àpò ìlú, òbí, ọrẹ àtinúwá (sadaqqah) , owó orí (Zakat) ni wọ́n fi ń tọ́jú ilé-ẹ̀kọ́ náà. [2]

Àlìmájìrí ayé òde óní

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọdún 1904, àyípadà dé bá ètò ẹ̀kọ́ Almájìrí nígbà tí àwọn Gẹ̀ẹ́sì fi agbára wọ ilẹ̀ Hausa tí wọ́nnsì fipá gbàjọba lọ́wọ́ àwọn Emir. Fífipá gbàjọba yí mú kí àwọn Gẹ́ẹ̀sì ó pa ọ̀pọ̀ nínú àwọn Emir, tí púpọ̀ wọ́n si pàdánù ìjọba ilẹ̀ wọn sí ọwọ́ àwọn Gẹ̀ẹ́sì, fúndí èyí ètò ẹ̀kọ́ àlìmájìrí kò ri ìtọ́jú to péye mọ́. Lẹ́yìn èyí, wọ́n dá Bókò sílẹ̀, tí ó túmọ̀ sí "ìmọ̀ ẹ̀kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì". ÌjọbaGẹ̀ẹ́sì tuntun fòpin sí ìnáwó sí ètò ẹ̀kọ́ Almájìrí láti àpò ìjọba tí kò sì sí ìrànwọ́ kankan mọ́ fún ètò ẹ̀kọ́ àlìmájìrín mọ́. Èyí ni ó mú kí àwọn olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí ní gba bárà láti fi jẹun.

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]