Àsáró

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àsáró

Àsáró jẹ́ orúkọ àpapọ̀ fún irúfẹ́ oúnjẹ tí a sè pẹ̀lú àwọn èròjà oríṣiríṣi sè papọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà. Oríṣiríṣi àsáró lò wà nílẹ̀ Yorùbá, àsáró iṣu, àsáró[1]ànàmọ́, àsáró kókò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[2]Èyíkéyìí nínú àsáró tí wọ́n bá sè ni wọ́n máa ń kó ohun èròjà onírúurú papọ̀ láti fi pèsè oúnjẹ aládìídùn yìí. Àsáró jẹ́ oúnjẹ tí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ilẹ̀ Adúláwọ̀ pàá pàá jùlọ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà máa ń jẹ sùn lálẹ́ tàbí ní ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ ọ̀sán tàbí bí ìpanu lásán ṣáájú oúnjẹ gidi.[3]

Àwọn èròjà Àsáró[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Pípèsè àsáró yàtọ̀ síra wọn ní ìlú sí ìlú àti agbègbè sí agbègbè. Lára àwọn èròjà rẹ̀ ni: iṣu, ànàmọ́, kókò, ẹja, epo tàbí òróró, ata èyíkéyìí, edé, iyọ̀, ẹ̀fọ́ èyíkéyìí, ẹ̀dọ̀ màlúù, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[4]

Àwọn Ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "How To Make Asaro (Yam Porridge) - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. 2017-09-15. Retrieved 2019-12-12. 
  2. Onyeakagbu, Adaobi (2019-07-15). "Asaro How to prepare the Yoruba thick and spicy yam porridge". Pulse.ng. Retrieved 2019-12-12. 
  3. Osinkolu, Lola (2015-07-13). "Yam pottage/Yam Porridge (Asaro recipe)". Chef Lola's Kitchen. Retrieved 2019-12-12. 
  4. "Nigerian Yam Porridge". All Nigerian Recipes. 2019-03-24. Retrieved 2019-12-12.