Àtọ̀sí ajá
Àtọ̀sí ajá | |
---|---|
Awọn alefọ àwọ̀ lori ọwọ́, ti wiwọle si inu ara kokoro àrùn Ṣistosoma nfa. | |
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta | |
ICD/CIM-10 | B65. B65. |
ICD/CIM-9 | 120 120 |
MedlinePlus | 001321 |
Àtọ̀sí ajá (ti a tun mọ si bilhasia, ibà igbín, ati Ibà katayama)[1][2] jẹ àrùn ti awọn aràn ti o nfa ijamba fun ara ti irúṢistosoma. O le yọ ọpa ti o ngbe ìtọ̀ tabi awọn ifunlẹnu. Awọn ààmì idamọ aisan le ni ninu inu ti o dun ni, igbẹ-ọrin, igbẹ ti o ni ẹ̀jẹ̀ ninu, tabi ẹ̀jẹ̀ ninu ìtọ̀. Fun awọn ti wọn ti ni ikọlu fun igba pipẹ, ẹdọ le bajẹ, kidirin le d’aṣẹ silẹ, ailebimọ, tabi jẹjẹrẹ apo-ìtọ̀ le waye. Ninu awọn ọmọde o le fa ifasẹyin fun idagbasoke ati iṣoro ẹkọ kikọ.[3]
Okunfa
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àrùn yìí maa ntan nipa nini ifarakan omi ti o ni awọn kokoro ti o nfa àrùn ninu. Awọn kokoro ti o nfa àrùn ni a maa jọwọ lati ìgbín omi ti o ti ni ikọlu. Àrùn yìí wọpọ laarin awọn ọmọde ni awọn orilẹ-ede ti o ṣẹṣẹ ndagbasoke nitori ti o ṣee ṣe lati ṣere ninu omi ti o ti ni àrùn. Awọn ẹgbẹ miiran ti o wa ninu ewu ti o ga ni awọn agbẹ, awọn apẹja, ati awọn ti o nlo omi ti o ti ni àrùn fun iṣẹ oòjọ́ wọn.[3] Ohun wa ninu ẹgbẹ awọn ikọlu aràn.[4] Ayẹwo nwaye nipa riri awọn ẹyin kokoro àrùn naa ninu itọ eniyan tabi ninu igbẹ. A tun le jẹrisii nipa rírí antibodies lodi si àrùn naa ninu ẹ̀jẹ̀.[3]
Didena ati Abojuto
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Awọn ọna lati dena àrùn naa ni ninu mimu gberu nini aaye si omi ti o mọ́ ati di din iye awọn ìgbín ku. Ni awọn agbegbe ti àrùn naa ti wọpọ a le ṣe itọju gbogbo ẹgbẹ papọ lẹẹkan naa ati l’ọdọọdun fun àrùn naa pẹlu ogun praziquantel. A nṣe eyi lati din iye awọn eniyan ti o ni ikọlu ku ati pe nipa bẹẹ ki a din titan kiri àrùn naa ku. Praziquantel tun jẹ itọju ti Ajọ Ilera Lagbaye (World Health Organization) gba n’imọran fun awọn ti a mọ wipe wọn ti ni ikọlu.[3]
Imọ nipa titan kiri àrùn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àtọ̀sí ajá nyọ o to miliọnu eniyan mẹwa le ni igba (210)lẹnu ni gbogbo agbaye,[5] ati iye eniyan bíi ẹgbẹrun mejila (12,000)[6] si ẹgbẹrunlọgọrunmeji (200,000) ni o nku nipasẹ rẹ l’ọdun.[7] Àrùn yìí wọpọ julọ ni Afrika, ati pẹlu ni Aṣia ati Gusu Amẹrika.[3] Bíi miliọnu ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀rin (700) eniyan, ni awọn orilẹ-ede ti o le ni aadọrin (70), ni o ngbe ni awọn agbegbe ti àrùn naa ti wọpọ.[7][8] Àtọ̀sí ajá jẹ igbakeji si àrùn ibànikan, gẹgẹ bíi àrùn ti kokoro nfa ti o ni ipá ti o ga julọ.[9] Lati igba lailai tí tí di ibẹrẹ ọdun ti ọgọrun ti ogun (20th century), ààmì idamọ àtọ̀sí ajá ti ẹjẹ ninu ìtọ̀ ni a ri bíi ẹya nnkan oṣu ti ọkunrin ni Egipiti ti a si rii bíi nnkan ti a nlati lakọja fun ọdọmọkunrin.[10][11] a kaa si àrùn awọn ile-olóoru ti a ko kàsí.[12]
Awọn itọkasi
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Schistosomiasis (bilharzia)". NHS Choices. Dec 17, 2011. Archived from the original on 15 March 2014. Retrieved 15 March 2014.
- ↑ "Schistosomiasis". Patient.co.uk. 12/02/2013. Archived from the original on 23 May 2015. Retrieved 11 June 2014. Check date values in:
|date=
(help) - ↑ 3.0 3.1 3.2 3.3 3.4 "Schistosomiasis Fact sheet N°115". World Health Organization. February 2014. Retrieved 15 March 2014.
- ↑ "Chapter 3 Infectious Diseases Related To Travel". cdc.gov. August 1, 2013. Retrieved 30 November 2014.
- ↑ Fenwick, A (Mar 2012). "The global burden of neglected tropical diseases.". Public health 126 (3): 233–6. doi:10.1016/j.puhe.2011.11.015. PMID 22325616.
- ↑ Lozano, R; Naghavi, M; Foreman, K; Lim, S; Shibuya, K; Aboyans, V; Abraham, J; Adair, T et al. (Dec 15, 2012). "Global and regional mortality from 235 causes of death for 20 age groups in 1990 and 2010: a systematic analysis for the Global Burden of Disease Study 2010". Lancet 380 (9859): 2095–128. doi:10.1016/S0140-6736(12)61728-0. PMID 23245604.
- ↑ 7.0 7.1 Thétiot-Laurent, SA; Boissier, J; Robert, A; Meunier, B (Jun 27, 2013). "Schistosomiasis Chemotherapy". Angewandte Chemie (International ed. in English) 52 (31): 7936–56. doi:10.1002/anie.201208390. PMID 23813602.
- ↑ "Schistosomiasis A major public health problem". World Health Organization. Retrieved 15 March 2014.
- ↑ The Carter Center. "Schistosomiasis Control Program". Retrieved 2008-07-17.
- ↑ Kloos, Helmut; Rosalie David (2002). "The Paleoepidemiology of Schistosomiasis in Ancient Egypt" (PDF). Human Ecology Review 9 (1): 14–25. http://www.humanecologyreview.org/pastissues/her91/91kloosdavid.pdf.
- ↑ Rutherford, Patricia (2000). "The Diagnosis of Schistosomiasis in Modern and Ancient Tissues by Means of Immunocytochemistry". Chungara, Revista de Antropología Chilena 32 (1). ISSN 0717-7356. http://www.scielo.cl/scielo.php?pid=S0717-73562000000100021&script=sci_arttext.
- ↑ "Neglected Tropical Diseases". cdc.gov. June 6, 2011. Retrieved 28 November 2014.