Àwọn àdúgbò ìlú Mọdákẹ́kẹ́

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Oruko ati itumo awon adugbo ilu Mọdákẹ́kẹ́, ni Ipinle Osun, Naijiria.

Àwọn àdúgbò ìlú Mọdákẹ́kẹ́ àti ìtumọ̀ wọn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nọ. Adugbo Itumo
1. Ajíbésinró Ilé olá ti won ti n so esin mó èèkàn. Esin ni babańlá wa máa ń gùn jáde. Ìdí ni yìí to je yo nínú wón pé: Omo Ajíbésinró, Omo òlésin léèkàn, Omo ògbajè gboko lówó olóko.
2. Ògúnsùà Ògún lo so won pò nínú egboilé yìí. Orúko oba to kókó je ni Modákéké ni Agboilé yìí ni Oba náà ti wá o ké si gbogbo àwon ènìyàn rè pe e wá, e jékí orùsà ògún ti a ń bo yìí so wá pò.
3. Alágbàgun Won máa n be àwon ara gboile yìí lówè fun iyàn gígún nínú oríkì agboile yìí lo ti jáde to so pé : Omo alágbàgún kò gbodò fìyán tore
4. Ilé pàràkòyí Orúko Oye olóórí onísòwò láyé àtijó ni Abé rè ni àbojútó òwò síse wà.
5. Arókómo A rówó gbé omo. Omo tó ba yanjú làágbé ti kò se òkùnrin nínú oríkì agboilé yìí lo ti jáde tó so jé: Omo ri jùkú a bá ìyá rè gbe, Omo dari ara a kòó sílè.

6. Àdúgbo: Ilé Oósà Ìtumò: Orúko Oyè ìlí, òun ni olóórí àwon afobaje

7. Àdúgbo: ilé Ògòkú Ìtumò: A ri èyin kágò eégún ijó níí jó. Òrìsà eégún ni won ń bo níbè

8. Àdúgbo: Agbo ilé káríkárà Ìtumò: Onísòwò ni gbogbo won. nínú oríkì won lo ti jáde tói so pé. Kárí kárà kámó sanwó, ká sin owó kó dìjà 9. Àdúgbo: Olóyà Ìtumò: orisa oya ni won ń lo níbe, ojúbo oya wà nibe, won sì gbàgbó pé o máa ń fun won lómo

10. Àdúgbo: Ajóńbàdí Ìtumò: Gbajumò aláfé ènìyàn ni bale agbo ilé yìí. Ti o ba n rin lo lójúde ìrin oge pèlú fáàri ni.

11. Àdúgbo: Olókúta Ìtumò: kìkì òkúta ni agbo ilé náà. Àwon ènìyàn rip e ko si ohun to lè hù níbè.

12. Àdúgbo: Ilé Elébiti Ìtumò: Orúko Eégún to maa ń jáde ni agboile yìí ni. Nínú oríki rè ló ti jáde tó so pé. Elébiti sàgbá ko níjà.

13. Àdúgbo: jágbéegùn Ìtumò: Onísègùn ni won. Kò si àrùn ti won gbé dé Ibè ti ko san

14. Àdúgbo: òòpó òsun Ìtumò: Ilé olósun òrìsà òsun máa ń fún won lómo.

15. Àdúgbo: Ilé Èkerin Ìtumò: Orúko òye Balógun. Òun lo je igbá kerin si Oba.

16. Àdúgbo: Ilé òsó Aró Ìtumò: Aró dídá ni isé won níbi. Ko si aso ti won ko le se òsó sí lára.

17. Àdúgbo: Agbo ilé Fágúnwá Ìtumò: Ifá gúnwá síbì. Onífá niwón ni agbo ilé yìí wón ni ojúbo Ifá níbè.

18. Àdúgbo: Olórò Ìtumò: Orò ni won ń bò. Àwon ara agbo ilé yìí máa ń dásà pe bi obìnrin bá fojú di orò, orò yóò gbe e.

19. Àdúgbo: Ilé ògóbùlà Ìtumò: Ogo bu olá fún won nínú ilé yìí. Ibi ti olóórí àwon onísàngó ń gbé. Ojúbo sàngó wà níbè

20. Àdúgbo: ilè Àsàmú Ìtumò: Orúko oyè ìlú ní, onílù ni wón níbè

21. Àdúgbo: Alágbòn Ìtumò: Agbón ni wón ń hun ta. pàtàkì isé owó won ni àgbòn híhùn.


22. Àdúgbo: játíná Ìtumò: Oti títà ni isé owó won. Eléyìí hàn nínú oríkì won tó sap é: Játi jákà bí àdèbà Oti sèkètè ni won máa ń se

23. Àdúgbo: Olómi Ape Ìtumò: Omi inú orù won máa ń mu. Won máa n re omì nínú ape.

24. Àdúgbo: Ilé Eléwúro Ìtumò: Ewúro gbigbo ni ise won, àwon ènìyàn kìí wá ewúro ti níbè

25. Àdúgbo: Adélérè Ìtumò: Orúko eni tó te agbo ilé yìí dó. Won gba pe oruko ajemoyè ni èrè nínú

26. Àdúgbo: Wúgbolú Ìtumò: òun lo kókó je oba ògúnsùà. O ni ìfé àwon ènìyàn re

27. Àdúgbo: Agbo ilé yangun Ìtumò: Àgbàdo títà ni ise won. Àwon ni kò jékí ebi pa èlú .

28. Àdúgbo: Àgbójà Ìtumò: Àlùbàtá ni won. Bàtá ni won máa ń lù fún Eégún won

29. Àdúgbo: Ilé epo Ìtumò: Onísowò epo ni won. Epo kìí won nílé yìí

30. Àdúgbo: Baálè Sàngó Ìtumò: Ibi ti olóórí àwon onísàgó ń gbé, Ojúbo sàngó wà níbè.

31. Àdúgbo: Iráyè Ìtumò: Ní àtijo òrìsà kan wà ni ibi tí à ń pè ni ìráyè yìí orúko òrìsà náà ni ìrá láti ipólé òwu ni wón ti gbé òrìsà yìí wá léyìn ogun húkù húkù, obaláayè ni orúko àwòro rè. Bí wón bat i n bo òrìsà yìí tí won da Obì tí Obì si yàn àwon Olùsìn rè yóòmáa pariwo ayò pé ìra ti yè, Ìráyè, ìráyè láti ibi yìí ni a ti mu orúko àdúgbò yìí

32. Àdúgbo: pónńtan Ìtumò: Ìrísí ìyá ken tí ó jé gbajúmò ni agbo ilé yìí ni won fi n pè é ìyá náà lówó lówó béè ni ó sì pupa wèè ó sì tún sígbonlè pípupa tí ìyà yìí pupo ni won fi n fi àwò rè júwe rè tí wón si fi so agbo ilé yìí

33. Àdúgbo: Okè èsó Ìtumò: Àwon ìran oníkòyí ni wón te agbo ilé yìí dó, jagunjagun sin i wón àwon ni won máa n jagun fun ìlú.

34. Àdúgbo: Esin Oye Ìtumò: Ilé Alésinlóyè ni won máa n pè é télè kí won fi n pe béè ni pé okùnrin ken wa níbè nígbà náà tí ó máa n gun esin ni àsìkò ilé odún tí wón bá wa sí ilé láti oko àsìkò yìí sì ni oyé máa n mu ni agbègbè wa; èyí ni won fi máa n pè é ni Alésin nígbà oyé.

35. Àdúgbo: Ilé Èkerin Ìtumò: Ní Ìdílé yìí oyè Èkerin ni wón máa ń je níbè èyí ni won fi máa n pè won ni ilé èkerin

36. Àdúgbo: Òkè ìpàlò Ìtumò: Orí òkè ni ìbí yìí ó sì kún fun kìkì òkuta èyí ni a fi n pè é ni òkè ìpàhò

27. Àdúgbo: Ajíbésinro Ìtumò: Aji bá esin lórí òòró ni wón sún kid i ajíbésinró. Ní àtijó àwon ìdílé yìí ni won máa n fie sin rin ìrìn àjò béè wón sì ni esin yìí to pò gan-an débi pe won máa n so won mólè ní iwájú ìta nit í eni tí ó ń lo tí o ń bò yóò máa ba won níbè.

28. Àdúgbo: Okè Òwu Ìtumò: Àwon ènìyàn tí ogun lé kúrò ni ìpólé òwu nígbà ogun húkùhúkù ni wón tèdó si ibí, orúko ìlú won ni won si fib o agbolé won

29. Àdúgbo: Ìtaàsìn Ìtumò: Níbí yìí ni ilè ìjósìn àkókó ni ilú Modákéké kókó wa àwon ìjo sítifáánù mimó ni wón kó ilé ìjósìn yìí bákan náà légbèé rè ni ilé ìjósìn àwon mùsùlùmí wà èyí ni won fi so Ibè ni ita ìsìn èyí tí ó wa di itaàsìn

30. Àdúgbo: Agbo ilé Oláyá Ìtumò: Ní agboole yìí òrìsà oya ni won n sìn níbí orúko òrìsà yìí ni a fi n pe agbo ilé yìí.

31. Àdúgbo: Olúgbòóyàn Ìtumò: Orúko odò kan ni olúgbo ògàn yìí orúko odò yìí ni a fi n pe agbo ilé yìí.

32. Àdúgbo: Òkè Olá Ìtumò: Orí òkè kan ń be ni àdúgbò yìí àwon ènìyàn ń dá àníyàn pé kí òkè náà ó jé òkè olá fún àwon

33. Àdúgbo: Ilé Arídìíèké Ìtumò: Ìnágije babaláwo kan ni ń jé báyìí ìdí ti wón fi n pè é béè ni pé babaláwo náà máa n tu eni ti àwon àjé bá dè mólè béè ni ó sì máa n gbogbo kùrukùn ti bá n be ní ìgbésí ayé omo èdá. Babalawo náà gbónà ìlú mo ká sì nib í àwon ènìyàn ba ti n lo si ilé rè won a ni àwon ènìyàn ba ti n lo si ilé rè won a ni àwon n lo si ilé arídìíèké èyí ni won fi n pe agbe ilé yìí di òní olónìí

34. Àdúgbo: Ilé onílé àrán Ìtumò: Ní ìdílé yìí aso àrán ni won máa n tà níbè ìdí nìyí tí wón fi ń pè é ni onílé àrán

35. Àdúgbo: Eréta Ìtumò: Ìdì ti wón fi ń pe agbo ilé yìí ni ilé eréta ni pé níògangan agbo ilè yìí ni àwon ará ijóhun ti máa n wa ota tí àwon alágbède máa n yó sínú ìgbá kí won ó tó so ó di Irin ti won fi n rokó ròdá.

36. Àdúgbo: Ilé Alubàtá Ìtumò: Ìsé ìlù lílù ni wón n se níbí ìlù bàtá ni won sì máa n lù àwon onílù ìdílè yìí ni wón máa n lu bàtà fun àwon tí won ń bo òrìsà sàngó àti àwon eléégún ibé owó won yìí ni won fi so agbo ilé won loruko.

37. Àdúgbo: Òkè Amólà Ìtumò: Orúko enìkàn tí ó jé gbajúmò ní ìlù Modákéké ni ó ń jé Amólà ní àgbègbè Ibi tí ó kó ilé sí òkè yí. Ibè po ni béè ni orí òkè yìí ni ó kó ilé sí tente èyì ni won fi n pe agbo ilé yìí ni òkè Amolà

38. Àdúgbo: Ilé Aláró Ìtumò: Látijo isé aró dídà ni àwon idílè yìí máa n se isé yìí ni àwon ènìyàn sì mo wón mó bí enìkàn bá ti fe lo si ilé won, won á ni àwon ń lo sí ilé aláró, orúko yìí ni wón tè mo agbo ilé yìí lára dòní olónìí.

39. Àdúgbo: Òkè Awo Ìtumò: Níbí ni igbódù àwon baba awo kí ilù ó to máa fè si nígbà tí ìlú wá kúrò ni inú igbó ni àwon babalawo wá fenu kò pé ibè ni àwon yòó ti máa se ìpàdé owo àwon yóò lo se igbódù mìíràn ni wón bá n se ìpàdé awo ni òkè awo. Èyí ni won fi ń pe ibè ní òkè awo di òní.

40. Àdúgbo: ilé atàgbèdò òjo Ìtumò: Ní agbo ilé yìí ni won ti máa n ta àgbàdo ju ní àsìkò òjò èyí rí béè torí pé àwon kíì sábà gbin oúnje mìíràn àfi àgbàdo ìdí nìyí ti won fi n pè won ni ilé àtàgbàdo òjò.

41. Àdúgbo: Olómi Ape Ìtumò: Odò ti ó ń sun láti ilè tí won wa gbé ape le lórí láti inú àpe yìí ni won ti máa n pon omi yìí idí nìyí ti wón fi so ni agbo ilé olomi ape.

42. Àdúgbo: Egbédòré Ìtumò: Àwon egbé ni wón parapò tí wón dá àdùgbò yìí sílè èyí ni wón fi so agbo ilé yìí ní orúko.

43. Àdúgbo: Ilé Akirè Ìtumò: Àwon ìdílé Obá ìkirè ni won te agboolé yìí dó ìdí nìyí ti won fi só lórúko mo orúko ìlú won 44. Àdúgbo: Ìta mérin Ìtumò: Orita ni àdúgbò yi jé títì mérin ni wón sì pàdé níbè èyí ló fà á tí wón fi n pè é ni ìtamérin.

45. Àdúgbo: Ilé gbénà Ìtumò: Ní agbe ilé yìí – isé gbegilére ni isé won àwon ìdílé Ajibógun ni won sì máa n gbénà ni wón ba kúkú so ìdílé náà ní ilé gbénàgbénà sùgbón akekúrú rènì àwon ènìyàn ń pè dòní

46. Àdúgbo: Kóìíwò Ìtumò: Ìtàn ìgbà ìwásè so fun wa pe tokotaya kan wà níbí agbo ilé yìí tí won n bí àbìkú omo bí won bat i bi omo yìí ni yóòkú ni won wá pinnu láti kó omo tí wón bi ni àsìkò kan jade kí won ó si se ináwó rè kí ayé gbó kórun mò. Nìgbà tí wón se báyìn ni omo bá dúró ni kò bá kú mó èyí ni ó fà á ti won fi so ibè ni kóìíwò èyí tí àpajá rè ń jé kó èyí wò ná bóyá a jé dúró.

47. Àdúgbo: Okè D.O Ìtumò: Ìtàn so pé Ibè ni (District officer) ń gbé orí òkè sì ni ibè ilé àwon tí ó ti di ipò D.O. yìí mu ti wón jé òyìnbó sì wà níbè pèlú. Léyìn ìgbà tí a gba òmìníra àwon òyìnbo ti ń gbé ibè kí Obásanjó ó tó sòfin kí àlejò m;aa lo ní (1978)

48. Àdúgbo: Bodè Ìtumò: A rí orúko agbo ilé yìí nipa sè pé ibè ni enu odi ìlú.

49. Àdúgbo: Ilé Akálà Ìtumò: Àwon ìdílè yìí jé ìdílé tí wón wa láti ede wá tèdó sí Modákéké. Ilá ni wón sì máa ń gbìn. Wón ni wón máa n sòrò pé ilá odun yìí o àkálà ni o ohun tí wón máa n wí yìí ni won fi so agbo ilé won ni ilé àkálà.

50. Àdúgbo: Alágbàáà Ìtumò: Télètélè rí, àwon eléégún ni àwon ti wón ń jé alágbàáà yìí ibè sì ni àwon olórí òjè won wa. lénu kan kìkìdá àwon eléégún ni wón dá àdúgbò yìí sílè.

51. Àdúgbo: Agbóríití Ìtumò: Ní ayé àtijó, ode niwón nínú agboolé yìí Akíkanjú ènìyàn sì ni wón nínú ode sisé nígbà náà, tí wón bá degbó lo títí tí wón bá pa erankéran àwon ni wón máa ń gbé orí rè fún. Ìdi rè nìyí tí wón fi ń pè wón ní agbóríitú.

52. Àdúgbo: Ilé Owá Ìtumò: Gégé bí wón ti so, wón ní láti Ilésà ni àwon tí ó da àdúgbò yìí sílè ti wá. Nítorí pá àwon ìjèsà ni a máa ń kì ni “Omo owá, obokun rémi”.

53. Àdúgbo: Irépòlérè Ìtumò: Gbogbo àwon tí wón kólé ládúgbò yìí ni wón femu kò láti so àdúgbò won ni Ìrépòlérè. A lè so pé pèlú ìsòkan tí wón ní ni orúko àdúgbò yìí se di

54. Àdúgbo: ile péròó Ìtumò: Ìtàn so fún wa pé, àwon tó wà ni àdúgbò yìí láyé àtijó jé ologbón gidigidi, tó fi jé pe tí òrò bá rújú tan níbò míràn àwon ni wón máa ń báwon dá eyó pèlú. Èyí ló mú kí àwon aládùúgbò won panupò so àdúgbò yìí dó títí di òní olónìí yìí.

55. Àdúgbo: Ilé Olómù Ìtumò: Àwon tí wón wá láti òmù àrán la gbó pé àwon ló té àdúgbò yìí dó títí di òní yìí.

56. Àdúgbo: Awótóbi Ìtumò: Ní ayé àtijó àwon babaláwo ni wón wa ní àdúgbò yìí. Ní ìgbà náà gbogbo wa mò pé ipa pàtàkì ni Ifá ń kó láwùjò àwon Yorùbá, èyí ló mú kí àwon ènìyàn máa so pé, àwon ń lo sílé baba awo títí wón fi so ó di ilé Awótóbi.

57. Àdúgbo: Amókèegùn Ìtumò: Ìdí tí wón fi ń pe àdúgbò yìí ni Amókèegùn nip é, kí èègùn tó débè yóò gun òkè bíi mélòó kan, lénu kan òkè ni a máa gùn débè ni wón se so àdúgbò ni Amókèegùn.

58. Àdúgbo: Onílàálì Ìtumò: Ìsé àwon àdúgbò yìí ni wón se so wón lórúko. Ní ayé àtijó làálì tí àwon Hausa máa ń lé sórí èékánná ni àwon fi ń sisé se ní ti won. Idí nìyí tí wón fi ń pè wón ní ilé Onílàálì.

59. Àdúgbo: Ogérojú Ìtumò: Ní ayé àtijó ìtàn kan so fún wa pé àwon tí wón wa nínú agbo ilé yìí gbáfínjú dáadáa, kò sí ibi tí wón lè dé nígbà náà tí wònkò ní mò pé inú àdúgbò yìí ni wónm ti jáde wá, ni àwon ènìyàn se pa emu pò láti so wón ni ilé Ogérojú.

60. Àdúgbo: Agbónanni Ìtumò: Wón ni ní ìgbà ken Igbó tí ouni máa wa lára rè ni ènìyàn máa wà dé àdúgbò yìí, àárò kùtù hàn ni omi yìí máa ń wà ní ara igbó yìí tó fi jé pé kò sí bí ènìyàn se lè jí lo sì àdúgbò yìí ki aso irú eni béè ma tutu wálé. Idí nìyí tí wón fi so àdúgbò yìí ni agbón-an-ni.

61. Àdúgbo: Atólógun Ìtumò: Ní ilé yìí, àwon jagunjagun má fit i ìbon se ni wón, tí ogun bale tán won ki í lo ìbon láti fi jà rárá bí kò se kùmò àti ada pèlú ida. Ko sì sí bí ogun náà se lè le tó ti wón lè pa wón lójú ogun, fóniladìe toko èèmó bò nit ì won. Ìdí nìyí tí wón fi ń pè wón ní ilé Atólógun.

62. Àdúgbo: Àgbója Ìtumò: Ìtàn so fún wa pé àwon tó wà ni ilé Àgbójà máa ń bínú púpò tó fi jé pet í enìkan bá yan ènìyàn je lójú won, wón lè so ìjà náà di ti won pátápátá, kò sì sí ibi tí wón ti lè gbá pé wón ń jà ní àdúgbò tó tì wón, tí won kò ní débè láti loo jà. Òpèbé aríjà sorò ló mú won di ìlé àgbójà. 63. Àdúgbo: Òsúnaró Ìtumò: Isé owó tí wón ń se ló mú ki wón máa pe àdúgbò won ni òsúnaró. Isé aró rife ni wón fi sísé òjó won, bí ó tilè jé pé isé aró ríre yìí kò wópò láàrin won mó

64. Àdúgbo: léwèéré Ìtumò: Nínú agbo ilé yìí láyé àtijó, wón ní àwon omo agbo ilé yìí máa ń wéré nígbà náà, èyí ló mú kí won máa pe agbo ilé won ní ilé léwèéré.

65. Àdúgbo: Ibágbé Ìtumò: Wón ni inú àwon tí ń gbé àdúgbò yìí té púpò, won kì í ba èèyàn jà rárá, wón sì máa n ba èèyàn dámòràn púpò tàbí gba ènìyàn nímòràn nípa ohunkóhùn tí ba se ènìyàn. Idí nìyí tí wón fi ń pé wón ní ilé ìbágbé.

66. Àdúgbo: Agbédè Ìtumò: Wón ní ní ayé àtijó bàbá kan wà tí ó máa n sòrò tí yó sì yo kòmóòkun òrò tó bá so pèlú, àwon aládùúgbò tí ò tí won máa ń wá kó ìlànà tí ènìyàn fi máa ń ba ènìyàn sòrò tírú eni béè yó sì gbó òrò náà ni àgbóyé. Idi nìyí tí wón fi so ilé máa ní ilé agbédè.

67. Àdúgbo: Òkodò Ìtumò: Wón ní ìdí ti wón fi ń pe àwon ní òkódò ni pé ilé àwon ti omi pé omi yìí gan-an ló sì yí àwon ka pèlú.

68. Àdúgbo: Ògo: Ìtumò: Ìtàn so fún wa pé, nítorí pé àwon tó wà ní agbo ilé yìí féràn láti máa yin olúwa logo ni wón se so wón di agbo ilé ògo.

69. Àdúgbo: Báálèsàngó Ìtumò: Sàngó ni wón so pé àwon tí wón wà nínú ilé yìí máa ń bo láyé àtijó, ibè gan-an ni a lè so pé ojúbo sàngó gan-an wà nígbà náà láti ìgbà tí à ń wí yìí ni wón ti ń pè wón ni agbo ilé baálè Sàngó.

70. Àdúgbo: Òkò Ìtumò: Wón ní àwon omo tó wà ni agbo ilé yìí burú ju èpè ìdílé lo láyé àtijó tó fi jé pé òkò ni gbogbo àwon omo yìí máa ń lè kiri àdúgbò nígbà náà, èyí ló mú won so orúko agbo ilé won ní agbo ilé òkò.

71. Àdúgbo: Ańdù Ìtumò: Orúkò enìkàn tí ó kókó dé àdúgbò nì wón fi so àdúgbò náà ni orúko rè. Wón ní òun gan-an ni wón fi je alága àdúgbò náà.

72. Àdúgbo: Ògìdìgànún Ìtumò: Wón ní eni tí ó bá sè ni àwon ilé yìí máa ń gbé ni gídí gánún lo bá baálè láàfin rè láyé àtijó, won kì í jé kí esè irú enì béè kanlè títí tí won ó fi gbé e dé ibi tí wón bá gbé e lo. Ìdí nìyí tí wón fi ń pe ilé yìí ní agbo ilé ògìdìgànún

73. Àdúgbo: Adébóyè Ìtumò: Adúgbò yìí náà dàbí ti okè tí mo kókó menu bà télè, orúko eni tí ó kókó dé àdúgbò yìí ni wón fi so àdúgbò yìí lórúkò tí wón sì ń jé orúko náà di òní olómìí yìí.

74. Àdúgbo: Bérí Ìtumò: Ìtàn so fún wa pé, wón le nílé béré yìí láyé àtìjó, Ìbèrù yìí ni wón gbìn sókàn àwon ènìyàn láti má jè é kí àwon omodé máa ta félefèle lo sí àdúgbò won láti se ohunkóhun. Ìdí nìyí tí wón fi ń pè wón nílé bérí.

75. Àdúgbo: Òòtà Ìtumò: Ní ayé àtijó, wón ní kò sí irú ojà tí ènìyàn lè gbé dé agbolé yìí tí kò ní rí tà. Ìdí nìyí tí wón fi ń pè é ni ilé òòtà.

76. Àdúgbo: Móńdé Ìtumò: Wón ní ní ayé àtijó, wón ní ilé kan soso tó wà ni àdúgbò yìí pa amò ni wón fi kó ilé náà, fún ìdí èyí tí ènìyàn bá ti ńlo ibè won a ní ilé monde, ilé móńdé. Ìdí nìyí tí wón fi só dilé móńdé.

77. Àdúgbo: Ońsàká Ìtumò: Gégé bí a se mò pé sàká gan-an jé Ìtore àánú fún àwon aláìní ènìyàn, èyí lò mú kí àwon ara ile ońsàká sora won ni orúko yìí nítorí pé wón ní bàbá kan wa ní agbolé yìí ni ayé àtijó to máa ń se ìtore àánú fún àwon ènìyàn lopolopo. Bí àwon alámùlégbè won se so won ní agbolé ońsàká nìyen.