Àwọn èdè Austronésíà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lọ sí: atọ́ka, àwárí
Àwọn èdè Austronesian
Ìpínká
ìyaoríilẹ̀:
Maritime Southeast Asia, Oceania, Madagascar, Taiwan
Ìyàsọ́tọ̀: one of the world's major language families; although links with other families have been proposed, none of these has received mainstream acceptance
Àwọn ìpín-abẹ́:
Formosan (several primary branches)
Malayo-Polynesian (perhaps a sub-branch of Formosan)
ISO 639-2 and 639-5: map
[[File:
Malayo-Polynesian-en.svg

Oceanic languages.svg
|350px]]

Ebí àwon èdè kan nìyí tí èdè tí ó wà nínú rè tó ogófà. Àwon tí ó ń so àwon èdè yìí tó àádórin lé ní igba mílíònù (270 million). Wón ń so wón láti Madagascar dé Eastern Island: Wón tún ń so wón láti Taiwan dé hawal títí dé New Zealand. Wón tún máa ń pe Austronesian yìí ní Malayo-Polynesian. Ó jé òkan nínú àwon ebí èdè tí ó tóbi jù. Ohun tí kò jé kí àwon onímò mò dájú sáká iye èdè tí ó wà nínú ebí yìí ni pé òpò ìgbà ni won kì í lè dá èdè mò yàtò sí èka-èdè. Yàtò sí èyí, àwon èdè yìí ti ń wo inú ara. Ìyen ni pé enì kan lè máa so èdè A àti B papò nítorí òwò tí ó ń jé kí àwon ènìyàn pàdé ara won. Ìpín méta pàtàkì ni a máa ń sábì pín ebí yìí sí. Àwon ìpín méta náàs ni Western Austronesian, Eastern Austronesian àti Central Austronesian. Àwon egbé èdè tí ó wà nínú Western Austronesian tó èédégbèta. Wón ń bo wón ní Madagascar, Malaysia, àwon Erékùsù Indonesia, Phillipines, Taiwan àti apá kan Vietnam àti Cambodia àti igun ìwò-oòrùn New Guinea. Ara won máà ni àwon èdè méjì Micronesia (tí wón ń fé chamorro àti Palauan). Àwon tí ó wà nínú egbé Eastern Austronesian náà tó èédégbèta èdè. Wón tún máa ń pe egbé Eastern Austronesian ní oceanic. Wón ń so wón ní New Guinea, gbogbo àwon erékùsù bí egbèrún méwàá ní Melanesia, Micronesia àti Polynesia sùgbón àwon tí ó ń so wón kò ju mílíònù méjì àbò lo (2.5million). Àwon èdè tí ó wà nínú egbé Central Austronesian jé àádójo (150). Àwon tí ó ń so wón jé mílíònù mérin àbò ní ààrin gbùngbùn àwon erékùsù Indonesia.


Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]