Àwọn ènìyàn Mucubal
Àwọn ènìyàn Mucubal (tí a tún mọ̀ sí Mucubai, Mucabale tàbí Mugubale) jẹ́ ara àwọn ènìyàn Herero ní apá gúúsù Angola.[1] Bí àwọn Masai tí wọ́n bá tan, isẹ́ dídá Màlúù àti Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni wọ́n ń ṣe.[1] Ilẹ̀ wọn wà ní Asálẹ̀ Namib, òkè Serra da Chela sì ni ó wà ní Àríwá wọn tí Odò Cunene sì wà ní gúúsù wọn.[1][2]
Àwọn ènìyàn Mucubal kìí wọṣọ púpọ̀, wọ́n sì ma ń mú àdá tàbí òkò dání lọ ibi tí wọ́n bá ń lọ. Àwọn ènìyàn mọ àwọn Mucubal fún ẹ̀mí tí wọ́n ní, wọ́n le sá eré tí ó tó 50 miles (80 km) ní ọjọ́ kan.[2]
Ní àwọn ọdún 1930s, àwọn Portuguese sọ pé wọ́n pọ̀ tó ẹgbẹ̀rún márùn-ún, wọ́n sì gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilẹ̀ Portugal. Láàrin ọdún 1939 sí 1943, àwọn ọmọ ológun Portuguese bẹ̀rẹ̀ sì ń dójú ìjà kọ àwọn pẹ̀lú afisùn pé wọ́n jẹ́ ọlọ́tẹ̀ àti olè màálù, ìjà náà pa tó ará Mucubal ọgọ́rùn-ún.
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 1.2 "Woman from the Mucubal (Mucubai, Mucabale, Mugubale) tribe". Photo Contest 2011. National Geographic. 2011. Archived from the original on 3 April 2014. Retrieved 21 July 2012.
- ↑ 2.0 2.1 "Mucubais considerados como verdadeiros 'donos' de África" (in Portuguese). Zwela Angola. SOL. 29 October 2010. http://www.zwelangola.com/ler.php?id=3783. Retrieved 21 July 2012.