Ékọ́ ìmọ̀ ìpoògùn
Ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìpoògùn jẹ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìléra (health science) tí ó rọ̀ mọ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìṣègùn (medical science), pẹ́lú ìmọ̀ nípa ìpo kẹ́míkà (chemistry) mọ́ra wọn. Ẹ̀kó yí dá lórí ìṣàwárí ìpèsè, ìṣàkóso,dídànù, lílò ati bí oògùn náà yóò ṣe bára mu. Fífi iṣẹ́ ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìpoògùn ṣiṣẹ́ gba í ènìyàn ó nímọ̀ tó lọ́ọ̀rìn nínú ìṣègùn, bí àwọn èròjà inú oògùn ṣe ń ṣiṣẹ́, ìpalára tí ó lè mú wá, ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àìsàn tí a fẹ́ lòó fún, lílọ bíbọ rẹ̀ nínú ẹẹ̀jẹ̀, àgọ́ ara àti ìjàmbá tí oògw náà lè fà bí kò bá tó tàbí pọ̀jù. Ẹ̀wẹ̀, ẹ̀kọ́ yí tún nílò kí ènìyàn mọ̀ nípa (pathology). Lára àwọn ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìpoògùn bíi clinical pharmacists, ma ń nílò kí ènìyàn ó mọ̀ nípa ìmọ̀ mìíràn bí àpẹẹrẹ́ 'ìgbéyẹ̀wọ̀ àwọn èsì àbájáde láti inú láàbù'. [1] Àwọn ohun tí ó jẹ ẹ̀kọ́ ìmọ̀ yí lógún ni:
- Títo àwọn egbògi ìbílé abínibí láti fi pèsè oògùn.
- Pínpín àwọn oògùn náà ká, àti pípèsè ìtọ́jú tó péye.
- Ṣíṣàgbéyẹ̀wò àwọn akọsílẹ̀ tí yóò lani lọ́yẹ̀ nípa oògùn náà.
- Sísọ nípa iṣẹ́ oògùn náà léréfèé.
Fúndí èyí, àwọn onímò nípa ìmọ̀ ìpoògùn i a lè ṣàpèjúwe wọn gẹ́gẹ́ bí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nípa oògùn, tí wọ́n sì tún jẹ́ ẹni akókọ́ tí ó ń ṣètọ́jú aláìsàn pẹ́lú pípèsè oògùn, ati bí a ṣe.lè.lòó tí yóò múni lára dá. Ibi tí a ti ń ta tàbí ra oògùn ni a mọ̀ sí ilé oògùn (pharmacy) tabí (chemist). Lọ́pọ̀ ìgbà ni a ma ń ṣalábàá-pàdé àwọn nkan mìíràn tó yatọ̀ sí oògùn pàdé.nílé oògùn bíi : ọṣẹ, ìpara, ìparun, àwọn ìṣeré ọmọdé, ìwé ìròyì.àti bbl.
Ìpínsísọ̀rí ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìpoògùn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọ̀nà mẹ́ta ọtọ̀ọ̀tọ̀ ni a lè pín ìmọ̀ nípa ìpoògùn sí, àwọn ni:
- Pharmaceutics
- Medicinal Chemistry àti Pharmacognosy
- Pharmacy Practice
Àlà tàbí ìyàtọ̀ tí ó wà láàrín àwọn ìpínṣísọ̀rí yí sí àwọn ẹ̀ka ìmọ̀ tó kù bíi biochemistry kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ púpọ̀. Kódà, ìwònubọ̀nú ma ń wáyé láàrín ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìpoògùn àti àwọn ẹ̀ka ìmọ̀ sáyẹ́nsì tó kù lòpọ̀ ìgbà láti lè gbé àwọn àṣàyàn oògùn kọ̀ọ̀kan jáde. Ẹ̀ka ìmọ̀ Pharmacology ni a ma ń kà sí ìpísísọ̀rí kẹrin ẹ̀mnínú ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìpoògùn. Lóòtọ́, ìmọ̀ pharmacology ṣe pàtàkì nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìpoògùn (pharmacy), amọ́ òun kọ́ ni ó gbé ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìpoògùn ró. Ìlànà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nípa pharmacy ati pharmacology yóò gbà kẹ́kọ̀ọ́ lórí àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí yóò sì yàtọ̀ síra wọn. Pharmacoinformatics náà tún jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú ẹ̀ka ìmọ̀ ìpoògùn tí ó níṣe pẹ̀lú ìṣàwárí ìlànà tí a lè fi gbé oògùn kalẹ̀, gbe jáde tí yóò sì ṣiṣẹ́ tí a fẹ́ àti bí a ṣe lè ṣe ìtọ́jú oògùn náà kí ó má ba bàjẹ́. Pharmacogenomics tún dá lé ìkẹ́kòọ́ nípa ìbáṣepọ̀ àwọn légbé-n-légbé inú omi, iṣan àti ẹ̀jẹ̀ ara àti ìṣesí àwọn légbé-n-légbé yí sí àwọn oògùn tí wọ́n pèsè lẹ́yìn tí wọ́n lòó tán nínú àgọ́ ara.[2]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Clinical Pharmacy Education, Practice and Research. November 2018. ISBN 9780128142769. https://books.google.com/books?id=9Jp7DwAAQBAJ&pg=PA1.
- ↑ Reference, Genetics Home. "What is pharmacogenomics?". Genetics Home Reference (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-11-20.