Étò Ìkànìyàn
Ìrísí
Étò Ìkànìyàn ni ìgbésẹ̀ kan tí a fi ń ṣe àkọsílẹ̀ iye ènìyàn tí wọ́n ń gbé ní ìletò, Ìlú Ìpínlẹ̀ tabí orílẹ̀-èdè kan nípa kíka àwọn ènìyàn ní orí-ò-jorí ní ojúlé sí ojúlé. Gẹ́gẹ́ bí àjọ àgbáyé ṣe làá kalẹ̀, étò ìkànìyàn gbọ́dọ̀ ma wáyé ní orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan láàrín ọdún Mẹ́wàá síra wọn.[1][2]
Ohun tí étò ìkànìyàn gbọ́dọ̀ kó sínú
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Étò ìkànìyàn gbọ́dọ̀ ṣàfihàn àkọsílẹ̀ iye ọkùnrin, obìnrin, ọmọdé àti àgbà pẹ̀lú iye ọjọ́ orí wọn lásìkò ìkànìyàn. Bákan náà, ó gbọ̀dọ̀ ṣe àkọsílẹ̀ iye ilé, ati iye ìdílé tí ó wà nínú ìlìlú tàbí ìletò tí ó wà láàrín Ìpínlẹ̀ àti orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan. [3]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ United Nations (2008). Principles and Recommendations for Population and Housing Censuses. Statistical Papers: Series M No. 67/Rev.2. p8. ISBN 978-92-1-161505-0.
- ↑ "CES 2010 Census Recommendations" (PDF). Unece.org. Retrieved 2013-11-19.
- ↑ "History and Development of the Census in England and Wales". theforgottenfamily.wordpress.org. 2017-01-19. Retrieved 2017-01-20.