Ìṣẹ̀-Èkìtì

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lọ sí: atọ́ka, àwárí
Ìṣẹ̀-Èkìtì
Ìṣẹ̀-Èkìtì is located in Nigeria
Ìṣẹ̀-Èkìtì
Location in Nigeria
Àwọn ajọfọ̀nàkò: 7°27′36″N 5°25′12″E / 7.46°N 5.42°E / 7.46; 5.42
Country Flag of Nigeria.svg Nigeria
State Ekiti State

Ise-Ekiti

Isé yìí dá lórí àyèwò fonólójì èka-èdè Ìsè-Èkìtì, èyí tí ó jé òkan lára àwon èka-èdè tí à ń so ní ìpínlè Èkìtì. Láti se àgbékalè isé yìí, tíórì onídàró ni a lò. Ìpín mérin ni a pín isé yìí sí. Ní orí kìn-ín-ní ni a ti so ìtàn orírun Ìsè-Èkìtì. A so èrèdí isé yìí, ogbón ìwádìí tí a lò àti àyèwò isé tí ó wà nílè. Bákan náà, a so tíórì tí a lò fún isé yìí.

Ní orí kejì ni a ti se àlàyé lórí àwon ìró inú èka-èdè ìsè-èdè Ìsè-Èkìtì. Bíi ìró kónsónántì, ìró fáwélì, ìró ohùn, isé ohùn, sílébù àti orísirísi. sílébù tí a lè rí nínú èka-èdè Ìsè-Èkìtì. Ní orí kéta àpilèko yìí ni a ti sàyèwo nípa ìgbésè fonólójì tí ó wà nínú èka-èdè Ìsè-Èkìtì. A wo ìpàróje, àrànmó àti ànkóò fáwélì.

Ní orí kérin isé yìí ni a ti gbìyànjú láti wo àwon ìyàtò àti ìjora tí ó wà láàrin fonólóji èka-èdè Ìsè-Èkìtì àti ti olórí èka-èdè Yorùbá. Àgbálogbábò isé yìí dá lé àwon tuntun tí ó jáde nínú ìwádìí ti a se a si tóka sí àwon ibi tí a lérò pé isé kù sí.

  • M.G. Fátóyè, (2003), Àyèwò Fónolojì Èka Èdè Ìsè Èkìtì.’, Àpilèko fún Oyè Émeè, DALL, OAU, Ifè, Nigeria.