Ìṣẹ̀-Èkìtì
Ìṣẹ̀-Èkìtì | |
---|---|
Country | Nigeria |
State | Ekiti State |
Iṣẹ́ yìí dá lórí àyẹ̀wò fonọ́lọ́jì ẹ̀ka-èdè Ìṣẹ̀-Èkìtì, èyí tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka-èdè tí à ń sọ ní ìpínlẹ̀ Èkìtì. Láti ṣe àgbékalẹ̀ iṣẹ́ yìí, tíọ́rì onídàrọ́ ni a lò. Ìpín mẹ́rin ni a pín iṣẹ́ yìí sí. Ní orí kìn-ín-ní ni a ti sọ ìtàn orírun Ìṣẹ̀-Èkìtì. A sọ èrèdí iṣẹ́ yìí, ọgbọ́n ìwádìí tí a lò àti àyẹ̀wò iṣẹ́ tí ó wà nílẹ̀. Bákan náà, a sọ tíọ́rì tí a lò fún iṣẹ́ yìí.
Ní orí kejì ni a ti ṣe àlàyé lórí àwọn ìró inú ẹ̀ka-èdè ìṣẹ̀-èdè Ìṣẹ̀-Èkìtì. Bíi ìró kónsónáǹtì, ìró fáwẹ́lì, ìró ohùn, iṣẹ́ ohùn, sílébù àti oríṣiríṣi. sílébù tí a lè rí nínú ẹ̀ka-èdè Ìṣẹ̀-Èkìtì. Ní orí kẹ́ta àpilẹ̀ko yìí ni a ti ṣàyẹ̀wo nípa ìgbésẹ̣̀ fonọ́lọ́jì tí ó wà nínú ẹ̀ka-èdè Ìṣẹ̀-Èkìtì. A wo ìpàrójẹ, àrànmọ́ àti àǹkóò fáwẹ́lì.
Ní orí kẹ́rin iṣẹ́ yìí ni a ti gbìyànjú láti wo àwọn ìyàtọ̀ àti ìjọra tí ó wà láàrin fonọ́lọ́ji ẹ̀ka-èdè Ìsè-Èkìtì àti ti olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá. Àgbálọgbábọ̀ iṣẹ́ yìí dá lé àwọn tuntun tí ó jáde nínú ìwádìí ti a ṣe a si tọ́ka sí àwọn ibi tí a lérò pé iṣẹ́ kù sí.
- M.G. Fátóyè, (2003), Àyèwò Fónolojì Ẹ̀ka Èdè Ìsè Èkìtì.’, Àpilẹ̀kọ fún Oyè Ẹ́meè, DALL, OAU, Ifẹ̀, Nigeria.
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |