Ìbà pọ́njú-pọ́ntọ̀

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ìbà pọ́njú-pọ́ntọ̀
Ìbà pọ́njú-pọ́ntọ̀A TEM micrograph of the yellow fever virus (234,000X magnification)
Ìbà pọ́njú-pọ́ntọ̀A TEM micrograph of the yellow fever virus (234,000X magnification)
A TEM micrograph of the yellow fever virus (234,000X magnification)
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta
ICD/CIM-10A95. A95.
ICD/CIM-9060 060
DiseasesDB14203
MedlinePlus001365

Ìbà pọ́njú-pọ́ntọ̀, tí a mọ̀ láti ìṣẹ̀wá sí yẹ́lò jaki tàbí àjálù pupa,[1] jẹ líle Àkóràn àrùn.[2] Ní ọ̀pọ̀ ìṣẹlẹ̀, lára aamì ni ibà, òtútù, àìle jẹun, èébì, iṣan dídùn pàápáà ní ẹhìn, àti orí fífọ́.[2] Àwọn aamì sábà maa ń jẹyọ láàrín ọjọ́ márùn ùn.[2] Àwọn ènìyàn kan láàrín ọjọ́ kan tí ara wọṅ ti ń dá, ìbà náà padà wá, inú dídùn maa ń wáyé, àti ẹ̀dọ̀ bíbàjẹ́ bẹ̀rẹ̀ èyí to ń fa àwọ̀ ara pípọ́n.[2] Bí èyí bá wáyé, ewu ṣíṣẹ̀jẹ̀ àti àwọn ìṣoro kídìnrín maa ń pọ̀si.[2]

Òkunfà àti ìwádìí aisàn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àkóràn arùn pọ́njú-pọ́ntọ̀ ni okùnfà arùn náà èyí tí gígéjẹ abo ẹfọn ń tànká.[2] Ènìyàn nìkan ni o ńkó àrùn yíì, àwọn pírámétì míìràn, àti ọ̀pọ̀ ẹ̀ya ẹ̀fọn míìràn.[2] Ní àwọn ìlú, àwọn ẹ̀fọ́n ẹ̀yà Aedesaegypti ni ó sábà maa ń tàn káàkiri.[2] Àkóràn yíì ni Kokoro RNA ti gẹ́nùsì Flavivirus.[3] Àrùn náà le ṣòro láti sọ yatọ̀ sí àwọn aisàn míìràn, pà́apáà nígbà ìpinlẹ̀ àkọkọ́ bẹ́rẹ̀.[2] Láti jẹ́rì ipò afurasí, àyẹwò ìdánwò ẹ̀jẹ̀ pẹ̀lú polymerase chain reaction ní a nílò.[4]

Ìdẹ́kun àti Ìtọjú àti Ìsọtẹ́lẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìdábòbò àti ìmọ̀ọ́ṣe àjẹsára lódì sí àrùn pọ́njú-pọ́ntọ̀ wà, àwọn orílẹ̀-èdè kan sì nílò àwọn àjẹsára fún àwọn arinrìn-ajò.[2] Àwọn ìgbìyànjú míìràn láti dẹ́kun àkóràn ni láti dín pípọ̀si àwọn ẹ̀fọn aṣòkunfà kù.[2] Ní àwọn àgbegbè tí ibà pọ́njú-pọ́ntọ̀ wọ́pọ̀si ti àjẹsára ó sì wọ́pọ̀, ìwádìí kíákíá tí àwọn ìṣẹlẹ̀ àti abẹ́rẹ́ àjẹsára tí ọ̀pọ̀ lára àwọn ará ìlú ni ó ṣe pàtàkì láti dẹ́kun àjàkálẹ̀ arùn.[2] Nígbà tí ó bá tiní àkóràn, ìṣàkóso jẹ́ ti aláámì láìsi ìwọ̀n tí ó jáfáfá Kankan lòdì sí àkóràn náà.[2] Lára àwọn tí ó ní àrùn líle, ikú maa ń wáyé lára àwọn ìdajì ènìyàn tí kògba ìtọjú.[2]

Ìmọ̀ nípa àrùn àti ìtàn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àrùn pọ́njú-pọ́ntọ̀ ń ṣòkunfà àkoràn 200,000 àti ikú 30,000 lọ́dọọdún,[2] pẹ̀lú bíi ìdá 90% ìṣẹlẹ̀ ní Áfíríkà.[4] Bíi bílíọ́nù ènìyàn ni o ń gbé ní agbègbè àgbayé níbi tí àrùn náà ti wọ́pọ̀.[2] Ó wọ́pọ̀ ní ibi oorùn àwọn agbègbè Gúúsù Amẹ́ríkà àti Áfíríkà, ṣùgbọ́n kìíṣe ní Áṣíà.[5][2] Láti ọdún àwọn 1980, àwọn nọ́ńbà ìṣẹlẹ̀ àrùn pọ́njú-pọ́ntọ̀ ń pọ̀si.[6][2] Èyí ń wáyé nítorí àwọn ènìyàn díẹ̀ tí wọ́n ń fún ní àjẹsára, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí o ń gbé ní ìlú, àwọn ènìyàn tí o ńlọ káakiŕi, àti ìyípadà afẹ́fẹ́.[2] Àrùn yíì bẹ̀rẹ̀ ní Áfíríkà, níbi tí o ti tàn dé Gúúsù Amẹ́ríkà nípasẹ̀ òwò ẹrú ní 17 century.[1] Láti 17 century , ọ̀pọ̀ gbòógì àjàkálẹ̀ ti àrùn náà wáyé ní àwọn Amẹ́ríkà, Áfíríkà, àti Yúrópù.[1] Ní àwọn 18 àti 19 century, ìbà pọ́njú-pọ́ntọ̀ ni wọ́n rí bíi èyí tí ó léwu jùlọ àrùn àkóràn.[1] Kòkòrò ìbà pọ́njú-pọ́ntọ̀ ni kòkòrò ènìyàn àkọkọ́ tí a kọ́kọ́ ṣàwarí.[3]

Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 Oldstone, Michael (2009). Viruses, Plagues, and History: Past, Present and Future. Oxford University Press. pp. 102–4. ISBN 9780199758494. http://books.google.com/books?id=2XbHXUVY65gC&pg=PA103. 
  2. 2.00 2.01 2.02 2.03 2.04 2.05 2.06 2.07 2.08 2.09 2.10 2.11 2.12 2.13 2.14 2.15 2.16 2.17 2.18 "Yellow fever Fact sheet N°100". World Health Organization. May 2013. Retrieved 23 February 2014. 
  3. 3.0 3.1 Lindenbach, B. D., et al. (2007). "Flaviviridae: The Viruses and Their Replication". In Knipe, D. M. and P. M. Howley. (eds.). Fields Virology (5th ed.). Philadelphia, PA: Lippincott Williams &Wilkins. p. 1101. ISBN 0-7817606-0-7. 
  4. 4.0 4.1 Tolle MA (April 2009). "Mosquito-borne diseases". CurrProblPediatrAdolesc Health Care 39 (4): 97–140. doi:10.1016/j.cppeds.2009.01.001. PMID 19327647. 
  5. "CDC Yellow Fever". Retrieved 2012-12-12. 
  6. Barrett AD, Higgs S (2007). "Yellow fever: a disease that has yet to be conquered". Annu. Rev. Entomol. 52: 209–29. doi:10.1146/annurev.ento.52.110405.091454. PMID 16913829.