Ìdábẹ́ fún ọmọbìrin ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ìdábẹ́ fún ọmọbìrin ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà jẹ́ àṣà tí wọ́n ti fòfin dè. Ààrẹ tẹ́lẹ̀ Goodluck Ebele Jonathan buwọ́ lu òfin tí ó fòpin sí àṣà yí ní oṣù karún ọdún 2015.[1] Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni àṣà dídábẹ́ fún ọmọbìnrin tí wọ́pọ̀ jù ní gbogbo àgbáyé. Síbẹ̀síbẹ̀, ó ti ń dínkù. Ọ̀kànlélógójì nínú ọgọ́rún obìrin ní wọ́n ti dábẹ́ fún. Àṣà yìí wọ́pọ̀ ní gúúsù , ìwọ̀ oòrùn gúúsù, gúúsù ìlà oòrùn Nàìjíríà. Mẹ́tàdínlọ́gọ́rin nínú ọgọ́rún obìrin ní wọ́n ti dábẹ́ fún ní gúúsù, márùndínláàádọ́rin nínú ọgọ́rún obìrin ní wọ́n ti dábẹ́ fún ní ìwọ̀ oòrùn gúúsù tí wọ́n sì ti dábẹ́ fún méjìdínláàádọ́rin obìrín ní gúúsù ìlà oòrùn Nàìjíríà.[2] Àṣà yìí kò wọ́pọ̀ ní àríwá Nàìjíríà, àti pé àwọn Fúlàní kìí dábẹ́ fún ọmọ wọn. [3][2] Ìdí pàtàkì tí wọ́n fi ń dábẹ́ fún ọmọbìrin ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni láti díku ìkúdùn ìbálòpọ̀ àti láti dẹ́kun ìwà àgbèrè ṣ́íṣe.[2]

Oríṣi mẹ́rin ni ìdábẹ́ fún ọmọbìrin tí ó wà ní orílè èdè Nàìjíríà. Àwọn ni oríṣi àkọ́kọ́ (clictoridectomy), oríṣi kèji (sunna), oríṣi kẹta (infibulation) àti àwọn ọ̀nà míràn tí wọ́n maa ṇ́ gbà dábẹ́ bíi gúngún, fífá, títọ àti gígé idọ èyí tí ó sì máa ń fa ìpálára.[2][4]

Ìtànkálẹ̀ rẹ̀ káàkàkiri[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àyẹ̀wò[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àyẹ̀wò lóri ìbágbépọ̀ àti ìlera ti ọdún 2003 fihàn pé méjìlá nínú ọgọ́rún ọdọ́mọbìrin tí ọjọ́ orí wọn wà láàrín 15-19 ni wọ́n ti dábẹ́ fún tí bíi mẹ́tàdínlógojì nínú ọgọ́rún ni wọ́n gé idọ rẹ̀. Látàrí ìṣirò yìí, dídábẹ́ fún ọmọbìrin ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láàrín obìrin tí ó ti bàlágà kúsí mẹ́tàlá nínú ọgọ́rún ní àríwá ìlà òòrùn, mẹ́sán lé díẹ̀ ní ọgọ́rún ní àárín àríwá, kòpé ìdákan tán nínú ọgọ́rún ní àríwá ìwọ̀ oòrùn , bíi mọ́kànlélógójì nínú ọgọ́rún ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn, bíi márùnlélọ́gbọ̀n ní gúúsù, bíi mẹ́rìnléláàdọ́ta olé díẹ̀ ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn. Àyẹ̀wò yìí fihàn pé bíi méjìdínlọ́gbọ̀n olé diẹ̀ nínú ọgọ́rún àwọn obìrin tí ó ń gbé ní ìgboro ní wọ́n ti dábẹ́ fún tí ó sì jẹ́ wípé mẹ́rìnlá nínú ọgọ́rún àwọn obìrin tí ó ń gbé níabúlé ni wọ́n ti dábé fún. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó ń dábẹ́ fún obìrin ní orílè èdè Nàìjíríà jẹ́ obìrin tí kò ní ìmọ̀ púpọ̀ tàbí ìmọ̀ rárá nípà abẹ́ dídá.[5]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Nigeria Prohibits Female Circumcision In New Act • Channels Television". Channels Television. 2015-05-25. Retrieved 2018-02-20. 
  2. 2.0 2.1 2.2 2.3 Okeke, TC; Anyaehie, USB; Ezenyeaku, CCK. "An Overview of Female Genital Mutilation in Nigeria". Annals of Medical and Health Sciences Research 2 (1). doi:10.4103/2141-9248.96942. PMID 23209995. https://www.ncbi.nlm.nih.gov/pmc/articles/PMC3507121/. Retrieved 2018-02-20. 
  3. "Journals". Academic Journals. Retrieved 2018-02-21. 
  4. Okeke, Anyaehie & Ezenyeaku 2012, 70–73.
  5. Olubukola, Faturoti; Olumide, Abiodun; John, Sotunsa; Franklin, Ani; John, Imaralu; TaiwoOgechukwu; Omodele, Jagun (2015-01-01). "Practices of Traditional Circumcisers in Ogun State Nigeria (PDF Download Available)". IOSR Journal of Dental and Medical Sciences 14 (1 v6): 42–45. ISSN 2279-0861. https://www.researchgate.net/publication/271387229_Practices_of_Traditional_Circumcisers_in_Ogun_State_Nigeria. Retrieved 2018-02-20.