Ìkún omi ní Benue ní ọdún 2017
Ìrísí
Ìkún omi Benue ti ọdún 2017 ṣẹlẹ̀ ní oṣù kẹsàn-án ọdún 2017 ní Ìpínlẹ̀ Bẹ́núé, orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[1] Ó mú kí àwọn ènìyàn tí ó tó ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ̀rún sọ ilé wọn nù,[2][3] ó sì tún ba ilé tí ó tó ẹgbẹ̀rún méjì jẹ́.[4]
Okùnfà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Òjò tí ó rọ̀ léra fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀sẹ̀ mú kí àwọn odò ṣàn kọjá etí wọn, èyí fa ìkún omi. Ìjọba Ìbílẹ̀ kan lélógún nínú mẹ́talélógún ni ìkún omi náà dàmú.[5] Ìkún omi ní agbègbè náà ma ń ṣẹlẹ̀ nítorí òjò líle àti odò Benue tí ó sàn kọjá ibẹ̀.
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "More than 100,000 displaced by flooding in central Nigeria" (in en). USA TODAY. https://eu.usatoday.com/story/news/world/2017/09/01/flooding-central-nigeria/624150001/.
- ↑ "Nigeria – Thousands Displaced by Floods in Benue State – FloodList". floodlist.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Copernicus. 5 September 2017. Retrieved 2017-09-10.
- ↑ Al Jazeera (1 September 2017). "Nigeria floods displace more than 100,000 people". www.aljazeera.com. Retrieved 2017-09-10.
- ↑ "Flood Hits Makurdi, Ravages Over 2,000 Homes • Channels Television". Channels Television. 2017-08-27. Retrieved 2017-09-10.
- ↑ "West and Central Africa: 2017 flood impact". Reliefweb 18 Oct 2017.